IBRAHIM TRAORE SỌ Ọ̀RỌ̀ ỌMỌ-ỌKỌ FÚN ÀWỌN ÌJÒYÈ BURKINA
Ààrẹ Ibrahim Traore ti ìlú Burkina Faso, ni a rí nínú fọ́nrán kan ní’bi tí ó ti ń bá àwọn olórí nínú ìjọba rẹ̀ sọ̀rọ̀; ó ní jagun-jagun ni òun o, òun kìí ṣe olóṣèlú; nítorí náà òun ò mọ bí wọ́n ṣe ń pẹ́ ẹnu sọ̀rọ̀; nítorí náà òótọ́ tààràtà ni òun ó sọ. […]