Awọn bàbá wa sọ wípé, Ọmọdé gbọ́n, Àgbà gbọ́n, laafi dá’lẹ̀ Ifẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sọ wípé, Ọwọ́ ọmọdé kò tó Pẹpẹ; ṣùgbọ́n, àgbàlagbà tí ọwọ́ rẹ̀ tó pẹpẹ nkọ́? ti ó bá gbé kèrègbè l’ati orí pẹpẹ, à ti mú nkan t’ó wà nínú kèrègbè náà nkọ́?
Ọwọ́ àgbàlagbà ti tóbi jù l’ati wọ’nú kèrègbè! Nítorí èyí, tí àgbàlagbà bá ti gbé kèrègbè ka’lẹ̀ l’ati orí pẹpẹ, nítorí wípé, òun gẹ́gẹ́bí àgbàlagbà ni ọwọ́ rẹ̀ gùn dé ibi pẹpẹ; ṣùgbọn, l’ẹhìn tí ó bá ti gbé kèrègbè náà ka’lẹ̀ nkọ́?
ó ti di dandan kí ọmọdé tí ọwọ́ rẹ̀ kéré, l’ati tẹ ọwọ́ náà bọ inú kèrègbè, kí ó sì bá àgbàlagbà mú nkan t’ó wà nínú kèrègbè.
Eyí tú’mọ̀ sí wípé, ọmọdé ní ohun pàtàkì l’ati ṣe, kí ìlú ó tó rí bó ṣe yẹ k’ó rí; ohun tí ọmọdé dẹ̀ ní’lò l’ati ṣe, òun gan-an ni kókó; nítorí wípé, bí àgbàlagbà bá ti gbé kèrègbè ka’lẹ̀ tán, ìnkan tí a fẹ́ kòì tíì ní ṣeé ṣe síbẹ̀ náà, àfi tí ọmọdé bá ti ọwọ́ bọ inú kèrègbè l’ati mú ohun tí a fẹ́ já’de.
Nínú ìrìn-àjò l’ati ìgbà tí a ti jẹ́ ajìjàngbara, títí di àkókò yí tí a fi di Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, orílẹ̀-èdè aṣè’jọba-ara-ẹni; ohun tí ojú ti là kọjá, kò ṣeé f’ẹnu sọ; àwọn àgbà tí a fi rán nìkan l’ó lè ṣé. Ọmọdé kankan, láí, kò lè ṣé.
Tani àgbà?
Ẹni t’ó mọ ọ̀nà; ẹnití Ọlọ́run rán; ẹnití Ọlọ́run yàn; ẹnití Ọlọ́run ti mú rin ìrìn-àjò èyí tí ó fi lè ṣe irú iṣẹ́ yí.
Ṣùgbọn àgbàlagbà yí sọ wípé, kèrègbè tí òun, pẹ̀lú àtìlẹ́yìn Olódùmarè, gbé ka’lẹ̀ yí, ó ní ọwọ́ ọ̀dọ́ l’ó lè wọ’nú kèrègbè yí; tìtorí wípé, ọwọ́ ọ̀dọ́ ni ó lè tọ ọ̀nà tí ó wọ inú kèrègbè yí.
A kò gbọ́dọ̀ dàbí àwọn onílé-kejì, tí ó jẹ́ wípé, kìkìdá ẹni t’ó ti ntẹ̀pá ni wọ́n máa gbé sí ipò à ti ṣe ohun mèremère fún ará ìlú. Àmọ́ ṣá, ohun mèremère mélo l’ó kù ní ọwọ́ ẹni tí ó ti nre bi àná?
Ohun mèremère mélo l’o kù tí ọmọ ọdún márun-lé-l’ọgọ́rin, tí a bí nígbàtí òyìnbó ṣì njẹ gàba lé wa l’orí; tí òun fúnrarẹ̀ kò rí’lé ayé wá tààrà; yàtọ̀ sí ohun ti òyìnbó fi bò wá l’ojú l’ati rò wípé a nj’ayé nìgbà yẹn; ohun mèremère mélo ni irúfẹ́ wọ́n ní l’ati ṣe àrà-ọ̀tọ̀ iṣẹ́ tí yíò gbé ọmọ ogún ọdún èní lé’kè kí ó lè ní ọjọ́ ọ̀la?
Àwọn onílé-kejì, èyíinì, ibi tí a ti mbọ̀, ni wọ́n máa nṣe bí ẹni wípé bí wọ́n ba ṣe nd’àgbà si ni wọ́n túbọ̀ mọ̀ nípa bí a ṣe nṣe ìlú.
Ká Ìròyìn: Mẹ́wàá Nṣẹlẹ̀ Nílẹ̀ Yorùba!
Wọ́n gbàgbé, tàbí wọn kò mọ̀, wípé, ón tó àkókò kan tí àgbà kò yẹ k’ó sá’ré bí ọmọdé – àkókò tí ó jẹ́ wípé àgbà ti wọ’lé ọgbọ́n; kí ó fi ọgbọ́n ayé tọ́’ka ọ̀dọ́ sí ọ̀nà tí Ọgbọ́n máa ngbà, kí o wá jẹ́ kí ọ̀dọ́ ó ṣe ohun tí ó jẹ́ wípé ọ̀dọ́ nìkan l’ó lè ṣeé ní àṣelà – èyíinì, kí ọ̀dọ́, pẹ̀lú ọpọlọ ìwòyí, òye ìwòyí, àti ọgbọ́n tí ó rí j’ogún l’ati ọ̀dọ̀ àgbà, kí ọ̀dọ́ náà kí ó fi t’ọwọ́ bọ inú akèrègbè wa yí, l’ati mú ohun tí àwọn àgbà pàápàá nfẹ́, ṣùgbọ́n tí ọwọ́ àgbà ti tóbi jù l’ati mú já’de l’ati inú kèrègbè wa yí.
Kèrègbè yí ni ohun gbogbo tí Olódùmarè ti kó lé wa l’ọwọ́, nípasẹ̀ àgbà tí ó bá wa gbé kèrègbè yí ka’lẹ̀ l’ati orí pẹpẹ tí ọwọ́ ọmọdé kò tó!
À b’ẹ ò ri bí? Láìsí ẹni tí ó ní ẹ̀mí àgbà, ẹni tí ó le bá wa gbé kèrègbè yí sí’lẹ̀ l’atorí pẹpẹ, tí ó sì ti bá wa gbe sí’lẹ̀, tí yíò sì máa fi ọgbọ́n àti òye àti ìmọ̀ tí Olódùmarè fun, tí yíò máa fi tọ́ wa s’ọnà títí láí, níbo l’à bá wà l’oní?
Ṣùgbọ́n, nísiìyí tí ó ti bá wa gbé kèrègbè ka’lẹ̀ l’ati orí pẹpẹ, tí ó sì ntẹ̀síwájú síi l’ati tọ́ wa s’ọnà, ó sọ wípé kí àwọn ọ̀dọ́ wá tẹ ọwọ́ wọn bọ inú kèrègbè, báyí, kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí mú gbogbo ohun mèremère já’de – èyíinì, ọ̀dọ́ tí ó ntẹ̀lé ọgbọ́n tí ẹni tí ó bá wa gbé kèrègbè yí ka’lẹ̀, ọgbọ́n tí ó fi ntọ̀ọ́, tí ó sì ní kí a máa tọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀; kìí ṣe ọ̀dọ́ ọ̀dàlẹ̀; kìí ṣe ọ̀dọ́ tí ó máa ju kèrègbè sọnù, tí ó máa sọ wípé t’ara òun l’òun máa ṣe, tàbí wípé ọmọ Yorùbá ṣáà náà ni òun; rárá o!
ká Ìròyìn: Àwọn Orúkọ Ní’lẹ̀ Yorùbá Tí Ó Ngbé Àwọn Akọni L’arugẹ Tàbí Àṣà Yorùbá
Ọ̀dọ́ tí ó ntẹ̀lé ọgbọ́n àgbà tí ó bá wa gbé kèrègbè ka’lẹ̀. Ṣe bí a tún lè sọ wípé kèrègbè yí pàápàá ni ohun gbogbo tí ó jẹ́ òmìnira fún wa; bẹ́ẹ̀ náà ni kèrègbè yí tún jẹ́ gbogbo àgbéka’lẹ̀ àlàka’lẹ̀ (èyíinì, Blueprint) Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.
Ọwọ́ àgbà ti tóbi jù l’ati wọ’nú kèrègbè yí!
Àwọn ìlú tí a ti mbọ̀, ibẹ̀ ni àwọn àgbàl’agbà t’ó jẹ́ wípé wọn kò tilẹ̀ rí’ran dáradára l’ati rí ẹnu ihò kèrègbè náà ti máa sọ wípé, dandanndandan, títí di ọjọ́ ikú, àwọn ni àwọn máamáa t’ọwọ́ bọ’nú kèrègbè – kèrègbè tí ọwọ́ wọn ti’lẹ̀ ti tóbi jù l’ati wọ’nú ẹ̀; wọ́n á ni àf’àwọn nìkan náà ni; ìdí ni èyí tí ó fi jẹ́ wípé kàkà kí àwọn àgbà òfò yí kí ó kó ‘ra wọn mọ́ wa l’ati ṣe iṣẹ́ òmìnira yí, nṣe ni wọ́n ṣì wà nínú oríṣiríṣi ipò tí wọ́n nfi wọ́n sí, nínú ìlú tí a ti mbọ̀.
ìlú òfò pẹ̀lú àwọn bàbá òfò tí wọ́n pe’ra wọn ní bàbá Yorùbá, ṣùgbọ́n tí wọ́n ndalẹ̀ Yorùbá l’ọtún l’osì; bí wọ́n dẹ̀ ti ṣe nṣe l’ati ìbẹ̀rẹ̀ ayé wọn nìyẹn – àwọn aríjẹ ní’dí màdàrú; aríjẹ ní’dí títa ìran wọn, àwọn aláìníti’jú akíndanidání tí wọn ò mọ̀ wípé Fúlàní kọ́ ni ìran wọn – ìgbà wá ti tó báyi, kí a mọ̀ wípé, ní ọ̀rọ̀ ìlú ṣíṣe, kìí ṣe gbogbo ọlọ́jọ́-orí ni àgbà.
Ní ilẹ̀ Yorùbá yí, àgbà tí ó bá wú’lò fún ìran Yorùbá ni àgbà! Àgbà tí kò ta Ìran rẹ́, òun náà ni Àgbà.
Ẹ jọ̀wọ́, kíni ẹni tí ó ti nsúnmọ́ àádọ́run ọdún fẹ́ lọ ṣe nínú ipò ìjọba tí yíò gbé ilé-ẹ̀kọ́ gíga s’okè. À fi k’á ṣáà ti’lẹ̀ ti lọ sí’bẹ̀ t’orí owó yi náà ni.
Ẹ kú ọ̀fọ̀ o, ẹ̀yin àgbà òfò.