• Oríkò Ilé-Iṣẹ́ Ìjọba, Agodi, Ìpínlè Ìbàdàn (Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ látijọ), D.R.Y

Àǹfààní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Tí Yorùbá

Díẹ̀ Lára Àwọn Àǹfààní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Tí Yorùbá

1. Ìwé Òfin D.R.Y

Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ní ànfààní àti ẹ̀tọ́ láti fún’ra wa kọ Ìwé Òfin Orílẹ̀-Èdè wa. 

Gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ṣe ṣe àlàyé fún wa, òfin tí ó dára jùlọ fún Orílẹ̀-Èdè wa ni èyí tí ó jẹ́ pé àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) gan-an-gan ló kọọ́: láti inú ìrírí wa, gẹ́gẹ́bí àṣà àti ìṣe wa, ohun tí ó bá ìṣẹ̀dá wa mu, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Nípasẹ̀ ètò yí, òfin Orílẹ̀-Èdè D.R.Y yóò jẹ́ èyí tí ó ti ọwọ́ ara wa jáde, gẹ́gẹ́bí ojúlówó Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P).

Àkókò ṣì ńbọ̀ tí àwọn aṣojú wa máa jóko láti gbé àwọn àbá wa gbogbo yẹ̀wò, láti mọ̀ èyí tí apapọ̀ ọmọ Yorubá fọwọ́ sí gẹ́gẹ́bí òfin.

2. ILÉ-Ẹ̀KỌ́ Ọ̀FẸ́

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Adániwáyé tó sọ ohun gbogbo di ọ̀tun fún wa Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), tí a bá wo orílẹ̀ èdè agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí a ti kúrò, a ó ríi bí ètò ẹ̀kọ́ wọn ṣe mẹ́hẹ, púpọ̀ ọmọ tó yẹ kó wà ní ilé-ẹ̀kọ́ ló ń rìn káàkiri ìgboro nígbà tí àwọn òbí wọn kò rí owó ilé-ìwé san, àwọn ìjọba tó jẹ́ àǹfààní ilé-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ṣe ni wọ́n gun àkàbà tán tí wọ́n gbé e kúrò kí ọmọ ẹlòmíràn má bàa ní oore ọ̀fẹ́ síi.

Àwọn tò sì tún wà nílé ẹ̀kọ́ ọ̀hún ńkọ́, ṣèbí ẹ̀kọ́ àdàmọ̀dì náà ni wọ́n ń kọ́ wọn, ẹ̀kọ́ tí kò wúlò lẹ́nu iṣẹ́ nígbà tí wọ́n bá kàwé tán, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ń san owó gegere.

A ò róhun fáyọ̀ bí ò s’ọpẹ́ àwa ọmọ Yorùbá? Olódùmarè ti mú ìgbà ọtún dé fún wa. Gẹ́gẹ́ bí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa wípé, ní Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ọ̀fẹ́ ni ilé ìwé láti alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé ipele ìgboyè kíní ní Fáṣítì,ẹ̀kọ́ tó yè kooro ni àwọn ọmọ wa yóò gbà, pẹ̀lú àwọn olùkọ́ tó yanrantí, kò sí ẹ̀fọ́rí owó ilé ìwé fún àwọn òbí mọ́,ohun gbogbo ti dì’rọ̀rùn.

3. GBÍGBÉ ÀṢÀ YORÙBÁ LÁRUGẸ

Ìgbà ọ̀tun ti wọlé dé o gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y),gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé, ní kété tí àwọn ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó ń f’ipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa bá ti kúrò pẹ̀lú ìtìjú àti ìpayínkeke,ní ohun gbogbo yóò gba àyípadà ọ̀tun, bẹ̀rẹ̀ láti  ìwa wa, ìjẹ́un wa, ìwọ’ṣọ wa, àti ìgbésí ayé wa lápapọ̀.

Gẹ́gẹ́ bí màmá wá Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, tí Olódùmarè lò fún òmìnira àwa ìran Yorùbá ṣe máa ń sọ fún wa wípé, àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́ yóò dá wa padà sí bí àwa ìran Yorùbá ṣe jẹ́ gan-an láì sí àmúlùmálà rárá. Màmá sọ fún wa nípa ètò ìwòsàn wípé, a ó máa ló ìlànà àwọn babańlá wa láti ṣe ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn,ìmúra àti ìw’ọṣọ wa yóò jẹ́ ti ìlànà ìbílẹ̀ Yorùbá. 

Èdè Yorùbá ni a ó máa sọ ní ilé- ẹ̀kọ́, ní ilé – iṣẹ́ àti níbi gbogbo káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, àwọn oúnjẹ wa tí ó ti di ohun ìgbàgbé a ó padà sí bí a tií ṣeé tẹ́lẹ̀, a óò padà sí ìwà ọmọlúwàbí wa bakanna, nítorí pé orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kò ní fi àyè gbà ìwà tí kò tọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ìṣẹ́ àti ìyà yóò di àfìsẹ́yìn tí eégún ńf’iṣọ.

4. ÈTÒ FÚN ÀKÀNDÁ

Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) jẹ́ èyí tí ó kún fún ànfààní tó yanrantí fún oríṣiríṣi àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P). Bí ètò ti wà fún ọmọ-ilé-ìwé, bẹ́ẹ̀ ló wà fún ọmọ-oyún-inú; ètò fún arúgbó náà kò gbẹ́hìn; bákannáà ni ètò fún gbogbo àkàndá tí wọ́n jẹ́ ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá.

L’akọ́kọ́ ná, gbogbo ohun tí ó wà fún ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá t’ó jẹ́ akẹ́kọ, tàbí oníṣòwò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, òun náà ló wà fún àkàndá tí ó jẹ́ ojúlówó ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá.

L’ẹhìn pé ó njẹ gbogbo ànfààní àti ẹ̀tọ́ I.Y.P, àkàndá I.Y.P tún wá ní ètò tí yíò jẹ́ kó rọrùn fún-un láti má sí ìdojúkọ tí ọwọ́ ò ká, látàrí bí ó ṣe jẹ́ àkàndá. Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, àkàndá tí ó fẹ́ lọ sí ilé-ìwé máa ní ohun tí kò fi ní nira láti kàwé, ìbáà ṣe ìpèníjà ojú ni ó ní.

Àkàndá tí ó jẹ́ pé ìpèníjà ìrìn-ẹsẹ̀ ni ó ní, á rí ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ D.R.Y nípa bí ojú pópó kò ṣe ní l’ewu fun láti rìn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìdùnnú àkọ́kọ́ ni pé, ó jẹ́ I.Y.P – ànfààní rẹpẹtẹ ló bá dé: wípé ó tún wá jẹ́ àkàndá túmọ̀ sí pé oríṣiríṣi amáyé-àkàndá-dẹrùn ní ó tún máa ní, tí kò fi ní máa ṣe ìnira tàbí ìpalára fún-un láti gbé ìgbé-ayé rẹ̀.

5. ÌWÁDI ÌJÌNLẸ̀ NÍ D.R.Y

Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun ni a nílò ìwádi-ìjìnlẹ̀ lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyà-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ṣe sọ, pé a máa ṣe ìwádi àti àgbéjáde Ìtàn wá; bẹ́ẹ̀ ni a máa ṣe ìwádi àwọn ohun ìwòsàn abáláyé wa.

Màmá wa sọ bákannáà pé gbogbo ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn fún òwò kan tàbí òmíràn tí ó jẹ́ pé àwọn kan jẹ gàbá lé lórí ní ilẹ̀ Yorùbá, kí á lọ wádi nípa rẹ̀, láti máà ṣé, nítorí ẹnikan-kan kò ní gàba lé ọmọ Yorùbá nínú òwò kankan.

A tún ti mọ̀, tẹ́lẹ̀, pé, ìwádi tó pọ̀ ni ó máa wáyé nípa iṣẹ́-ẹ̀rọ ní oríṣiríṣi.Kíni ìwọ̀nyí nsọ fún wa?

Wọ́n nsọ fún wa pé iṣẹ́ wà gidi fún wa, gẹ́gẹ́bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) láti gbé oríṣiríṣi ìmọ̀ jáde, fún iṣẹ́ tí ìwádi wọ̀nyí máa já sí, tí èyí á wá jẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún oríṣiríṣi àbáyọrí-sí-rere ní iṣẹ́ ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè wa.

A ò gbọ́dọ̀ ṣe ọ̀lẹ o. Ó túmọ̀ sí pé iṣẹ́-ọpọlọ, ìwádi-ìrònú-jinlẹ̀ àti ṣíṣe àwárí oríṣiríṣi Ìmọ̀, Ọgbọ́n àti Òye, máa kó ipa tó lágbára gidi ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).

6. ÌṢÀKÓSO ÀLÙMỌ́NÌ ILẸ̀

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí òye kò yé, ni wọ́n ti béèrè pé “kí la máa jẹ,” “kí la máà mu,” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ní Orílẹ̀-Èdè wa.

Ọ̀rọ̀ yí kò rújú rárá; Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti máa nsọọ́, láti ìgbà dé ìgbà, pé nísiìyí tí a ti polongo ìṣèjọba-ara-ẹni wa, tí a dẹ̀ ti ṣe ìbúra wọlé fún Ìjọba Orílẹ̀-Èdè wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ohun tí ó túmọ̀ sí ni pé a ti ní ÀṢẸ báyi láti máa wa kùsà wà, ní ilẹ̀ Yorùbá, lábẹ́ àkóso ìjọba wa, ìjọba D.R.Y, fún ànfààní ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá.

Ìwọ ni Góòlù, lithium, bitumen, epo rọ̀bì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, gbogbo rẹ̀ ti wà ní ìkáwọ́ ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá báyi, láìsí ẹni tí ó nbá wa pín nkan tí Olódùmarè fún wa. A ò tíì sọ erè oko, ẹja inú omi, àwọn ìgbó wa, ibi ìgbafẹ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Gẹ́gẹ́bí màmá wa ti ń sọ fún wa, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ni Olódùmarè túbọ̀ nfihan’ni oríṣiríṣi àlùmọ́nì tí ó wà nínú ilẹ̀ wa.

Láyé, ẹnikẹ́ni kò ní wá máa kó nkan wa mọ́: àwa ni a ni ohun tí Èdùmàrè fún wa; kò ń ṣe fún ẹlòmíran Àti má yé dẹrùn- ilé ìwòsàn, ilé-ẹ̀kọ́, títì tó dára, pẹ̀lú omi tó mọ́ gaara, kò ní ni wá lára; níbo ni a ti máa rí owó ṣe ohun wọ̀nyí? Owó wà nínú ilẹ̀ wa! ÀLÙMỌ́NÌ ló njẹ́ bẹ́ẹ̀! Ìdí nìyẹn tí Màmá tí máa nsọ pé ìṣèjọba-ara-ẹni, èyí tí ó fún wa ní àṣẹ láti ṣe àkóso gbogbo ohun tí Ọlọ́run jogún fún wa, ìyẹn gan-an ni a npè ní ÒMÌNIRA.

Ọmọ ìbílẹ̀-Yorùbá ti bọ́ sí Òmìnira báyi: Ohun kan tó kù ni kí á lé àwọn wèrè tó wà lórí ilẹ̀ wa; ìṣàkóso àlùmọ́nì ilẹ̀ wa túmọ̀ sí pé a ò lọ kọ́kọ́ gba àṣẹ níbikíbi kí á tó fọwọ́ kan ohun tó jẹ́ tiwa; láarín ara wa, ní abẹ́ àkóso ìjọba D.R.Y, ni a ti máa sọ pé ohun rere báyi la fẹ́ ṣe; àlùmọ́nì ilẹ̀ wa á dẹ̀ sọ pé a ríi sọ, torí òun wà níbẹ̀ fún wa: àgàgà, a tún wá ní Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè ti gbé lé Màmá wa lọ́wọ́, tí ó máa fi ọ̀nà hàn wá, bí a ṣe máa ṣé, tí gbogbo rẹ̀ á yẹ Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P).

Kò sí ìfòyà fún wa o! Agbára àlùmọ́nì ilẹ̀ jẹ́ ìkan gbòógì nínú nkan tí orílẹ̀-èdè fi nṣe orí-ire, Olódùmarè dẹ̀ ti ṣe ọmọ Yorùbá ní olórí-ire. Gbogbo àlùmọ́nì wọ̀nyí ni wọ́n ti wà ní inú ilẹ̀ wa láti àtètèkọ́ṣe; ohun tí ó wá jẹ́ ayọ̀ wa báyi ni pé a ti wá ní ÀṢẸ lórí ohun tó jẹ́ tiwa.

Kìí ṣe èyí nìkan; Èdùmàrè tún wá jogún ọpọlọ fún àwa ọmọ Yorùbá láti ṣe ìwádi, ṣe iṣẹ́, àti gbé iṣẹ́ lóríṣiríṣi jáde nípasẹ̀ àwọn àlùmọ́nì wọ̀nyí, fún ògo, ìdùnnú àti ayọ̀ ọmọ Yorùbá – kí á lè máa yin Ọlọ́run, títí ayé, gẹ́gẹ́bí Màmá wa ṣe máa nsọ.

7. ÀǸFÀÀNÍ ÈTÒ ILÉ GBÍGBÉ

Láìpẹ́, láìjìnnà, orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) yóò di àpéwò káàkiri àgbáyé látàrí àwọn ohun àrà-meèrírí tí yóò máa ṣẹlẹ̀ lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan ní orílẹ̀ èdè wa nípasẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye tí Olódùmarè fún màmá wá, iya ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, lára àwọn ohun tí màmá wa ti máa ń bá wa sọ náà ni wípé, gbogbo àwa tó jẹ́ ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, IYP) ni yóò ní ilé lórí nítorí pé, ìjọba orílẹ̀ èdè DRY yóò fún ẹni kọ̀ọ̀kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ọdún mọ́kànlélógún ní ilẹ̀, wọ́n yóò sì tún ṣe àtìlẹyìn fún wọn láti kọ́ ilé náà.

Bẹ́ẹ̀ sì ni ètò yóò wà fún àwọn àgbègbè tí ó bá yẹ fún ilé gbígbé, ilé iṣẹ́ tàbí fún iṣẹ́ ọ̀gbìn. Ẹnikẹ́ni kò ní leè kọ́ ilé láìgba àṣẹ lọ́dọ̀ ìjọba DRY bẹ́ẹ̀ni, ìjọba ní láti lọ ṣe àbẹ̀wọ̀ sí irú àgbègbè bẹ́ẹ̀ kí wọn leè ríi dájú pé kò ní sí ìjàǹbá kankan fún àwọn olùgbé ilé náà nígbà tí wọ́n bá kọ́ọ tán, tàbí fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń kọ́ ilé ọ̀hún,nítorí pé àwọn akọ́sẹ́mọṣẹ́ tó kún ojú òṣùwọ̀n ni yóò máa kọ́ àwọn ilé wa ní orílẹ̀ èdè DRY. 

Fún ìdí èyí, gbogbo àwa ọmọ IYP ti DRY ìgbé ayé ìrọ̀rùn ti dé fún wa, ìjọba tí yóò fi àwọn ará ìlú ṣe àkọ́kọ́ ní ìjọba Democratic Republic of the Yorùbá, DRY, nítorí pé lẹ́yìn Ọlọ́run, Yorùbá ni!

8. OWÓ ORÍLẸ̀-ÈDÈ WA

Ọrọ̀-Ajé orílẹ̀-èdè dúró lórí àwọn ìpìlẹ̀ àti àwọn òpó kan. Lára àwọn òpó wọ̀nyí ni ìdíyelé owó-ìná orílẹ̀-èdè.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìlọsíwájú, lónìí ni ó jẹ́ pe, ọ̀kan gbòógì lára ìṣòro wọn ni àìníye-lórí òwó-ìná wọn. Èyí ni ó máa ń fa ọ̀wọ́n-gógó, nìtorí pé, owó gọbọi ní’ye kò ra ń kan tó pọ̀ lọ títí.

Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá wá fi àṣírí kan hàn wá nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá wa sọ, nígbàtí wọ́n sọ̀rọ̀ dé’bi owó-ìná (currency) Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y). Wọ́n ní góòlù ni a máa fi ṣe ìdíwọ̀n owó-ìná D.R.Y

Góòlù jẹ́ ohun kan ní àgbáyé tí ìdíyelé rẹ̀ kìí sábà jás’okè-jásí’sàlẹ̀ bí ọkọ̀ tí ìjánu rẹ̀ ti bàjẹ́; iye tí ìwọ̀n góòlù kan bá jẹ́ lóni, kò níí fi tóbẹ́ẹ̀-jùbẹ́ẹ̀-lọ yàtọ̀ sí iye tí ó máa jẹ́ ní ọ̀la.

Orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá ti gbé ìdíwọ̀n owó-ìná wọn lé àpáta tàbí ìpìlẹ̀ iye tí ó jẹ́ ní góòlù, sábà máa nń aní ètò ọ̀rọ̀-ajé tí kìí sí ọ̀wọ́n gógó tó kọjá ìfaradà, nítorí ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí góòlù nìkan náà ló lè ṣẹlẹ̀ sí’rú owó-ìná orílẹ̀-èdè náà.

Èyí yàtọ̀ sí ìrírí àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ pé owó-ìná orílẹ̀-èdè míràn ni owó-ìná orílẹ̀-èdè tiwọn gb’ara lé: tí aburú bá ti bá àwọn t’ọ̀ún, ó ti bá àwọn náà nìyẹn.

Èyí túmọ̀ sí pé, ní orílẹ̀-èdè wa, ìfọkàn-balẹ̀ wa pé, níwọ̀n ìgbàtí àwa gan-an kò bá ya ọ̀lẹ, ohun tí ó bá máa ṣẹlẹ̀ sí ìdíwọ̀n góòlù ní àgbáyé, tí èyí kò sì jẹ́ aburú láti àtẹ̀yìn wá, òun náà ni a le ní ìrètí rẹ̀ lórí ìdíyelé owó-ìná wa.

Màmá tún fi yé wa pé nígbà tí a bá bẹ̀rẹ̀ sí yí èyí tí ó wà lọ́wọ́ báyi, sí owó tiwa, kí á máṣe jẹ́ kí ó yà wá lẹ́nu pé, nínú òǹkà , ení, èjì, ẹ̀ta, òǹkà rẹ̀ kò ní tó ti tẹ́lẹ̀; ìdí èyí ni pé ìdíyelé owó wa ju ti èyí tí a gbé lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀.

Wọ́n tilẹ̀ ṣe àpèjúwe kan fún’wa nígbà náà l’ọhún: wọ́n ní tí ohun tí a ní lọ́wọ́ báyi bá jẹ́ mílíọ̀nù kan, kí ó máṣe yà wá lẹ́nu pé pàṣípààrọ̀ rẹ̀ lè fún wa ní ẹgbẹ̀rún l’ọnà igba owó D.R.Y, tí ó túmọ̀ sí ìdámárun mílíọ̀nù èyí tí ó jẹ́ pé, ní òǹkà owó D.R.Y kan yóò ra ohun tí márùn-ún owó tí a gbé dání tẹ́lẹ̀ máa rà. Ó níye lórí ju ti tẹ́lẹ̀ ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀.

Ṣùgbọ́n, tí ó bá jẹ́ pé òǹkà mílíọ̀nù-mílíọ̀nù ní ó wu ẹni yẹn kí ó máa kà, bí mílíọ̀nù ọ̀ún kò tilẹ̀ leè ra’jà púpọ̀, ẹni náà lè lọ kó mílíọ̀nù rẹ̀ sí’bi tí àwọn tó ń ná owó yẹn nílu wọn ń ko sí, kí ó wá bẹ̀rẹ̀ síi ṣe iṣẹ́ tí áá fi lè kó owó D.R.Y tó níye lórí jọ, ní ilẹ̀ D.R.Y.

Gbogbo èyí túmọ̀ sí pé kò sí ìfòyà ní D.R.Y, lórí ìdíyelé tàbí ìwọ̀n owó-ìná orílẹ̀-èdè wa; àá mú ònkà kan lọ́wọ́ báyi, yóò sì jẹ́ owó gidi.

9. EWÉ ÀTI EGBÒ

Láti ìgbà ìwásẹ̀ ni Olódùmarè ti fún àwọn babańlá  wa ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye, láti lè bá ewé sọ̀rọ̀, àti oríṣiríṣi ohun tí ó wà ní àyíká wa; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ní ìmọ̀ àwọn ohun tí èwé, egbò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ le ṣe, pàápàá ní àgọ́-ara.

Èyí ló ṣe okùnfà oríṣiríṣi ìwòsàn tí àwọn babanlá wa ní fún àwọn àìsàn tàbí àrùn tí ó bá yọjú; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń fi àwọn ń kan wọ̀nyí kọ́ àwọn ọmọ láti ìran-dé-ìran.

Ara ń kan tí àwọn òyìnbó rí nìwọ̀nyí tí wọ́n fi sọ pé ètò ẹ̀kọ́ wa wà lókè ju ti àwọn lọ, àti pé ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ láti ayébáyé ni; ṣùgbọ́n nínú ìwà ìkà wọn, wọ́n pinu láti gbàá lọ́wọ́ wa, wọ́n wá gbé tiwọn fún wa.

Gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nípele nípele, ni Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá sì ń fi yé wa ní ìgbà-dé-ìgbà, tí wọ́n sì sọ fún wa pé ètò ìwòsàn ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) máa dá gbogbo ìmọ̀, agbára àti ẹkọ́ nípa èwé àti egbò tí a ti ní láti ìpinlẹ̀ṣẹ̀ padà fún  wa.

Èyí túmọ̀ sí pé ètò ìwòsàn wa ní D.R.Y máa rinlẹ̀ gidi, àjínde ara á máa jẹ́ fún wa nípasẹ̀ èwé àti egbò tí Olódùmarè  fi dá wa lọ́lá. Òpin ti dé sí àìrójú àìrayè tí àìsàn ń fà fún’ni.

Gẹ́gẹ́bí Màmá ṣe sọ fún wa, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ní àgbáyé yí ló jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwa Yorùbá ni wọ́n ti máa ní ìwòsàn sí ń kan tí wọn kò rí ojútu rẹ̀ láti ìgbà pípẹ́ wá! A dúpẹ́ lọ́dọ̀ Elédùmarè tí ó fi Ìránṣẹ́ Rẹ̀ ṣe atọ́nà fún wa.

10. ÌWÁDI ÌJÌNLẸ̀ NÍ D.R.Y

Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun ni a nílò ìwádi-ìjìnlẹ̀ lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyà-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ṣe sọ, pé a máa ṣe ìwádi àti àgbéjáde Ìtàn wá; bẹ́ẹ̀ ni a máa ṣe ìwádi àwọn ohun ìwòsàn abáláyé wa.

Màmá wa sọ bákannáà pé gbogbo ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn fún òwò kan tàbí òmíràn tí ó jẹ́ pé àwọn kan jẹ gàbá lé lórí ní ilẹ̀ Yorùbá, kí á lọ wádi nípa rẹ̀, láti máà ṣé, nítorí ẹnikan-kan kò ní gàba lé ọmọ Yorùbá nínú òwò kankan.

A tún ti mọ̀, tẹ́lẹ̀, pé, ìwádi tó pọ̀ ni ó máa wáyé nípa iṣẹ́-ẹ̀rọ ní oríṣiríṣi.Kíni ìwọ̀nyí nsọ fún wa?

Wọ́n nsọ fún wa pé iṣẹ́ wà gidi fún wa, gẹ́gẹ́bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) láti gbé oríṣiríṣi ìmọ̀ jáde, fún iṣẹ́ tí ìwádi wọ̀nyí máa já sí, tí èyí á wá jẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún oríṣiríṣi àbáyọrí-sí-rere ní iṣẹ́ ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè wa.

A ò gbọ́dọ̀ ṣe ọ̀lẹ o. Ó túmọ̀ sí pé iṣẹ́-ọpọlọ, ìwádi-ìrònú-jinlẹ̀ àti ṣíṣe àwárí oríṣiríṣi Ìmọ̀, Ọgbọ́n àti Òye, máa kó ipa tó lágbára gidi ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).

11. Ètò Ààbò Tó Péye

Ọ̀rọ̀ ètò ààbò jẹ́ ohun pàtàkì tí a kò sì gbúdọ̀ fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú, nítorí wípé, kò sì ohunkóhun tí ènìyàn leè ṣe  nínú ìbẹ̀rù àti àìbalẹ̀ ọkàn. Ìjọba tó bá fẹ́ ìdàgbàsókè fún orílẹ̀ èdè rẹ̀, yóò rí ọ̀rọ̀ ààbò gẹ́gẹ́ bíi ohun àkọ́kọ́ nínú ètò ìsèjọba  rẹ̀ tí ó sì gba àbójútó gidigidi.

Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kò sí lára Nàìjíríà mọ́ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a sì ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún, tí wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí Olódùmarè pè wọ́n sí èyí tí ètò ààbò tó dájú sì jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé lé màmá wá lọ́wọ́, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, èyí tí yóò mú ọkàn gbogbo wa bálẹ̀ lórí ilẹ̀ babańlá wa.

Àwọn àgbẹ̀ wa yóò leè máa lọ sí oko wọ́n pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀, tí kò ní sí ìbẹ̀rù àwọn ajínigbé, àwọn arìnrìn-àjò yóò leè lọ síbi tó bá wù wọ́n ní àkókò tí wọ́n fẹ́,láìsí ìfòyà àwọn alọnilọ́wọ́gbà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ìbẹ̀rù lórí àwọn dúkìá wa gbogbo.

Bákan náà, àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò tí yóò  máa wo ìgbòkègbodò àwọn ènìyàn yóò wà tọ̀sán-tòru, àti wípé, káàkiri orilẹ́ èdè wa ni yóò ní ohun èlò ìyàwòrán, dé bi pé, abẹ́rẹ́ tó kéré jù kò leè jábọ́ tí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò kò ní mọ̀ ní orí ilẹ̀ wa.

Iṣẹ́ ọwọ́ Olódùmarè ni eléyìí jẹ́, nítorí náà àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run wa títí láé.

12. ORÍKÌ ILẸ̀ YORÙBÁ

Oríkì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àṣà ilẹ̀ Yorùbá. Àwọn Yorùbá fẹ́ràn oríkì púpọ̀ nítorí pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tó máa ń mú inú ènìyàn dùn tàbí mú orí ẹni wú.

Kò sí ohun tí àwọn Yorùbá kò ní oríkì fún,bí oríkì se wà fún ènìyàn(ìyẹn ni oríkì ìdílé) bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà fún ẹranko, bẹ́ẹ̀ sì ni oúnjẹ náà ní oríkì tirẹ̀.

Yorùbá fẹ́ràn láti máa ki ènìyàn pàápàá ní àkókò ayẹyẹ, a sì tún máa ń fi pe àwọn míràn gẹ́gẹ́ bíi orúkọ oríkì, bí àpẹẹrẹ: ÀjàníÀlàóÀlàbíÀkànjí, ìyẹn ni fún orúkọ oríkì ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn obìnrin náà ní orúkọ oríkì bí àpẹẹrẹ: Àjọkẹ́Àjíkẹ́Àríkẹ́, Àbẹ̀bí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

Ṣùgbọ́n àwa ọmọ Yorùbá mélòó ni a tilẹ̀ mọ oríkì ìdílé tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ti jáde mọ́ lónìí, bẹ́ẹ̀ sì ni a ò sọ àwọn ọmọ wa ní orúkọ oríkì mọ̀.

Nítorí náà a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí ó ra ìran Yorùbá padà lọ́wọ́ ìparun nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ ìyá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla, nítorí pé màmá wa ti sọ fún wa wípé àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́ yóò dá wa padà sí ìpinlẹ̀ṣẹ̀ wa ni. Ayọ̀ ni ti wa!

13. ÀǸFÀÀNÍ FÚN ỌMỌ ÌBÍLẸ̀  YORÙBÁ

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó gbé ìránṣẹ́ rẹ̀ ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla dìde fún àwa ìran Yorùbá ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yìí láti gbà wá lọ́wọ́ ìṣẹ́ àti ìyà.

Àwa ọmọ aládé ti jìyà púpọ̀ fún àìmọye ọdún, ṣé ti ebi ni ká sọ ni, àbí ti ọmọ tó kàwé tí kò rí iṣẹ́ tó wá di alárìnkiri láàárín ìlú, ètò ààbò tó mẹ́hẹ ńkọ́?

Bí wọ́n ṣe ń jíwa lọ́mọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń jíwa láya tí wọ́n á sì tún máa béèrè òbítíbitì owó fún ìtúsílẹ̀ wọn. 

Ṣùgbọ́n Olódùmarè ti gbà wá, gbogbo rẹ̀ sì ti di àfìsẹ́yìn tí eégún ń fi’ṣọ,nítorí pé màmá wa ti sọ orísìírísìí àwọn ìgbádùn tí yóò wà fún wa ní orílẹ̀ èdè wa tuntun yí nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè ti gbé lé wọn lọ́wọ́, nítorí pé iṣẹ́ yóò pọ̀ yanturu, oúnjẹ yóò wà lọ́pọ̀lọpọ̀, bẹ́ẹ̀ni gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ni yóò nílé lórí. Gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá Indigenous Yorùbá People IYP, a kú oríire!

14. ÀṢÀ YORÙBÁ

Gẹ́gẹ́bí a ṣe mọ̀; Ìyá Ìran Yorùbá, ẹni tí Olódùmarè ti rán sí wa gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà, ti máa nsọ fún wa, pé, a máa padà sí Orísun wa ni – àṣẹ Ẹlẹ́da wa ni èyí.

Kíni orísun wa? Ibi tí a ti ṣàn wá; ìṣèjọba-ara-ẹni wa, gẹ́gẹ́bí Yorùbá, láìsí lábẹ́ ẹnikẹ́ni!

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ti fi yé wa pé nṣe ni a máa padà sínú àṣà abínibí wa nínú ohun gbogbo – títí kan bí a ṣé nwá onjẹ nínú ilé-iṣẹ-ọ́lónjẹ gbogbo.

Àṣà wa nìkan ni ó bá ìṣẹ̀dá wa mu; ìdí nìyẹn tí a níláti padà sí àṣà wa! Láìṣe bẹ́ẹ̀, kí Ọlọ́run máṣe jẹ́ kí ẹ̀dá wa kí ó takò wá o! A ò ní gba àbọ̀dè fún ara wa.

Àṣà wa ni ohun ìbílẹ̀ wa; ohun tí ó bá ẹ̀jẹ̀ tí Olódùmarè fi dá Yorùbá, tí ó ba mu – ohun tí ó jẹ́ pé láti ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá ní a ti nṣe é, tí ó dẹ̀ ngbè wá; ohun tí ó fún wa ni ẹ̀mí “ilé-ni-mo-wa” kì nṣe ohun tí ó jẹ́ àjèjì sí ẹ̀mí ọmọ Yorùbá, ẹ̀mí Ìran Yorùbá.

Gẹ́gẹ́bí ewé àti egbò, fún àpẹrẹ – àwọn ohun tí Olódùmarè ti fi sí Àyíká wa, pé kí wọ́n le jẹ́ ààbò àti ìwòsàn fún ara wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa nní ọgbọ́n kún ọgbọ́n ni, síbẹ̀, èyí tí Ọlọ́run ti fún wa, tí ó jẹ́ Àbáláyé, a máa padà sínú rẹ̀, kí ilẹ̀ àbáláyé wa yí, kí ó le gbè wá.

Màmá ti máa nsọ fún wa pé ó ní bí àwọn Bàbá wa ṣe ní ìgbé ayé rere níjọ́ láíláí, kí amúnisìn ó tó gòkè odò; a máa ṣe àwárí àwọn ohun tó mú kí wọ́n ní irúfẹ́ ìgbé-ayé-rere bẹ́ẹ̀.

A ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú lílo èdè wa; láti inú lílo èdè yí ni oríṣiríṣi nkan míì tí ó jẹ́ ti àbáláyé ti máa búyọ.

Ṣebí ó ní àwọn ọgbọ́n tí àwọn Baba wa ní, tí wọ́n fi nṣe àgbéjáde oríṣiríṣi iṣẹ́, bíi gbígbé nkan àgbẹ̀dẹ jáde; oríṣiríṣi Ìmọ̀ nípa ilẹ̀ tí a fi ndá’ko, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nkan, tí ó jẹ́ ti Ìbílẹ́, ló máa búyọ; bí àwọn ìyá wa ní ayé àtijọ́ tí máa nṣe àwọn iṣẹ́-ọwọ́ kan, èyí tí ó jẹ́ pé, títí di òní, a ò tíì rí ìran míràn tí ó ríi ṣe tó Ìran Yorùbá.

Ẹ jẹ́ kí a rántí bí àwọn òyìnbó amúnisìn, ṣe gbà pé ẹ̀kọ́, àṣà àti ìjọ́mọ-lúàbí wa ga ju tiwọn lọ, ṣùgbọ́n tí wọ́n wá gbe tiwọn yẹn lé wa lọ́wọ́! Ṣùgbọ́n tí ìyá ìran Yorùbá sọ pé èyí tí a sọnù yẹn, a máa padà sínú rẹ̀.

Yorùbá ni wá; àṣà Yorùbá nìkan ló le pé wa.

15. Iṣẹ́ Ṣíṣe

Yorùbá bọ̀, wọ́n ní, àgbàlagbà tó bá fàárọ̀ ṣeré, yóò fi ọjọ́ alẹ́ gbàárù, àti pé ìgúnpá nì’ye kan ẹni, àwọn náà ni wọ́n tún máa ń p’òwe wípé ìdí iṣẹ́ ẹni la tií mọ’ni lọ́lẹ.

Ìdí tí àwọn òwe wọ̀nyí fi wáyé ni wípé, ìran Yorùbá fẹ́ràn láti máa tẹpá mọ́’ṣẹ́ púpọ̀, Yorùbá kò fẹ́ràn ìmẹ́lẹ́ àti ọ̀lẹ.

Ní ayé àtijọ́, kété tí a bá ti bí ọmọ tuntun sílé ayé ni àwọn òbí rẹ̀ yóò ti lọ wo àkọsẹ̀jayé ọmọ náà lọ́dọ̀ ifá, ìdí ni láti mọ iṣẹ́ tí Ẹlẹ́dàá yàn mọ́ọ láti ọ̀run wá.

Yorùbá gbàgbọ́ pé tí ọmọ bá ṣe iṣẹ́ míràn yàtọ̀ sí èyí, irú ọmọ bẹ́ẹ̀ kò leè ṣe rere nídìí iṣẹ́ náà, ìdí nìyí tí Yorùbá fi máa ń wúre wípé, Ọlọ́run má jẹ̀ẹ́ kí a ṣiṣẹ́ oníṣẹ́.

Emi la ò ní yọ̀sí àwa ọmọ Yorùbá? Tí a bá wo àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé lé màmá wa lọ́wọ́ ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ìyá ìran Yorùbá tí Olódùmarè lò fún ìtúsílẹ̀ ìran Yorùbá ní àkókò yí, a óò ríi wípé láti dá wa padà sí irú ẹni tí ìran Yorùbá jẹ́ ni.

Ṣé a ò gbàgbé wípé màmá  ti sọ fún wa pé, iṣẹ́ yóò pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ àti pé, gbogbo wa ni a máa ṣiṣẹ́ nítorí pé kò ní sí owó ọ̀fẹ́ rárá, àti pé ọ̀sẹ̀ méjì-méjì ni àwọn òṣìṣẹ́ yóò máa gba owó ọ̀yà wọn.

A tún fẹ́ fi àkókò yí sọ fún wa wípé,nínú ètò ìgbaniṣíṣẹ́ ti Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, kò ní sí ojúsàájú tàbí gbígba rìbá, ẹ̀ka tí oníkálukú bá sì ti kún ojú òṣùwọ̀n ni yóò ti máa ṣiṣẹ́, àti wípé, ẹnìkan kò ní fi ojú tẹ́ńbẹ́lú iṣẹ́ ẹnìkejì, tàbí kí a máa sọ pé, iṣẹ́ ti ẹnìkan ni ó dára jù lọ nítorí pé, bákannáà ni gbogbo wa lábẹ́ òfin Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, àparò kan kò sì ní gaju ìkan lọ.

16. Ojú Ọ̀nà Tó Já Geere

Láìsí àní-àní, orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) ti dá dúró gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀ èdè, òun sì ni orílẹ̀ èdè tuntun jùlọ ní àgbáyé.

Olórí adelé wa àti àwọn adelé tó kù  sì ti ń ṣe ètò lórí ẹ̀ka lorísìírísìí ní orílẹ̀ èdè D.R.Y. Lára rẹ̀ náà ni ọ̀nà tó já geere, gbogbo àwọn ojú pópó àti kọ̀rọ̀ jákèjádò ilẹ̀ Yorùbá ní yóò ní ọ̀nà tó dára,bakanna ni àwọn ọ̀nà tó wọ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan káàkiri orí ilẹ̀ D.R.Y. kò ní gbẹ́yìn.

Ìjọba D.R.Y yóò ríi dájú pé, àwọn agba’ṣẹ́ṣe tó kún ojú òṣùwọ̀n tó sì jẹ́ ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.YP.) ní yóò máa ṣe àwọn ọ̀nà wa, nítorí pé ọmọ ẹni ò ní sè’dí bẹ̀bẹ̀rẹ̀ ká f’ìlẹ̀kẹ̀ sí ìdí ọmọ ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ìyá ìran Yorùbá ṣe máa ń sọ fún wa wípé lẹ́yìn Ọlọ́run, ọmọ Yorùbá ni àkọ́kọ́, fún ìdí èyí, àwọn ọmọ I.Y.P náà ni yóò máa ṣe àwọn iṣẹ́ lorísìírísìí láti tún orílẹ̀ èdè wa ṣe.

17. Ìpèsè Omi-Ẹ̀rọ

Omi-Ẹ̀rọ ṣe pàtàkì fún ìmọ́tótó, onjẹ àti láti dènà àrùn ní ilé àti àwùjọ.

Gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ṣe máa nsọ, L’ẹyìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá ni Àkọ́kọ́. Bẹ́ẹ̀ ni a mọ̀ pé àwa ni Ògo Adúláwọ̀. Ànfààní ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ni ó jẹ 

Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) lógún; ìrọ̀rùn dẹ̀ ni D.R.Y pinnu fún Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P). Kíni ìrọ̀rùn tí kò bá sí omi tó mọ́ gaara ní àrọ́wọ́tó?

Orilẹ̀-Èdè D.R.Y ní ìpèsè omi tó mọ́ gaara, tí ó wà ní àrọ́wọ́tó, nígbàkúgba àti níbi gbogbo ní ilẹ̀ D.R.Y, nínú ètò fún àwa ọmọ Aládé.

Ní kété tí a bá ti r’ẹyìn àwọn ọ̀tá, tí ìjọba orílẹ̀-èdè wa wọ’nú oríkò-ilé-iṣẹ́-ìjọba láti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀, ìpèsè omi ẹ̀rọ, fún àláfíà àti ìrọ̀rùn ọmọ Yorùbá, jẹ́ ìkan gbòógì nínú iṣẹ́ àmúṣe.

Eléyi yíò sì tún mú ìrọ̀rùn dé bá iṣẹ́ ṣíṣe gbogbo ní orílẹ̀-èdè wa, torí kò sí ilé-iṣẹ́, ìbáà ṣe ti ìjọba tàbí ti aládani, tí kò nílò omi-ẹ̀rọ tó mọ́ gaara, tó sì wà ní àrọ́wọ́tó.

Ẹ jẹ́ kí á fi àdúrà ran bàbá wa, Olórí-Adelé, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, àti gbogbo adelé, lọ́wọ́, kí Olódùmarè máa fún wọn ní Okun, Agbára, Ọgbọ́n àti Ìmọ̀ fún iṣẹ́ ribiribi tí Ó gbé lé wọn lọ́wọ́, kí àwa náà fi ọwọ́ so’wọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn láti tẹ̀lé Òfin Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y).

18. Iná Mọ̀nà-Mọ́ná

Lọ́kan-ò-jọ̀kan ni àwọn àǹfààní tí yóò wà ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) nítorí pé màmá wa Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tí Olódùmarè lò láti gba ìran Yorùbá lóko ẹrú fẹ́ràn ìran wọn tọkàntọkàn tí wọ́n kò sì fẹ́ kí ìyà jẹ ọmọ Yorùbá kankan, àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè sì gbé lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ fún wa wípé kò sí irú rẹ̀ ní àgbáyé, lára àwọn ohun am’áyédẹrùn tí a óò jẹ ìgbádùn rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y náà ni iná mọ̀nà-mọ́ná.

Láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún tí a ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ náà ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí gbogbo rẹ̀ sì ń lọ létò-letò nítorí pé pàtàkì ni iná mọ̀nà-mọ́ná láwùjọ, gbogbo àwọn onílé iṣẹ́ ńlá-ńlá àti olóko òwò kéékèèké yóò máa rí iná lò lóòrè-kóòrè láti ṣe iṣẹ́ wọn, bẹ́ẹ̀ sì ní gbogbo ìlú àti ìgbèríko káàkiri ilẹ̀ Yorùbá ni iná mọ̀nà-mọ́ná yóò wà tí kò ní sí ààyè fún àwọn amòkùns’èkà láti fi ojú pamọ́ sí.

Nítorí náà gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ìgbé ayé ìrọ̀rùn ti dé fún wa, ẹ jẹ́ kí a máa jó ká sì máa yọ̀.

19. ÌTỌ́JÚ OYÚN INÚ

Ìran Yorùbá fẹ́ràn ọmọ lọ́pọ̀lọ́pọ̀; láti inú oyún ni a ti ń nífẹ̀ẹ́ ọmọ wa: a tilẹ̀ máa ń pè wọ́n ní “atinúkẹ́,” yálà wọ́n jẹ́ orúkọ náà nígbá tí wọ́n dé’lé ayé tán tàbí wọn ò jẹ. 

Ìran Yorùbá wá ní Olùgbàlà tí Olódùmarè rán sí wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, tí Ó sì gbé Àlakalẹ̀ ètò ìsèjọba am’áyédẹrùn fún wọ́n láti lò fún àwa ìran Yorùbá. 

Láti inú oyún ni ìtọ́jú ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀, torí ìjọba Orílẹ̀-Èdè Yorùbá kò ní fi aláboyún sílẹ̀ fún ìgbé-ayé rádaràda èyí tí ó leè fa àkóbá fún oyún inú rẹ̀. 

Ìtọ́jú oyún-inú ti bẹ̀rẹ̀ kí a tó lóyún rẹ̀ pàápàá, nípasẹ̀ ìgbé ayé rere tó wà fún ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá tí kò ya ọ̀lẹ, tí kò sì gbàbọ̀de.

Nípa èyí, nínú àgọ́-ara tí ó ní àláfíà ni ìlóyún-ọmọ ti máa wáyé !

Ìjọ́ tí ìyá-ọmọ bá sì ti fẹ́’ra kù ni Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ti ní Ètò àbojútó aláboyún àti ọmọ-oyún-inú, nípasẹ̀ ìmọ̀ràn, ìbojútóni,oríṣiríṣi àyẹ̀wò tí ìyá àti oyún-inú máa nílò !

Kí a tún wá rántí pé ọ̀dá owó kò ní dènà àyẹ̀wò wọ̀nyí, t’orí ètò ìwòsàn ọ̀fẹ́ wà fún aláboyún àti oyún-inú tí wọ́n jẹ́ ojúlówó Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P).

20. ỌJÀ ÌGBÀLÓDÉ

Nígbà gbogbo ní àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó rán ìyá aláàánú sí wa, màmá wa Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti gbà wá kúrò nínú ìyà àti òṣì. Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń fi dá’wa lójú wípé, ọmọ Yorùbá kankan kò tún j’ìyà mọ́, nítorí pé àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè gbé lé màmá lọ́wọ́, kún fún ìgbá’yé gbá’dùn lorísìírísìí,lára wọn náà ni ọjà ìgbàlódé.

Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), gbogbo àwọn ọjà wa ni a óò sọ di ti ìgbàlódé, iná mọ̀nàmọ́ná tí kò ní sẹ́’jú, omi ẹ̀rọ tí kò ní lọ,ààbò tó péyé fún àwọn olùra’jà àti olùta’jà, bẹ́ẹ̀ ni àyíká tó mọ́ tó sì dùn- ún wò.

Ìjọba D.R.Y yóò ríi dájú pé, gbogbo àwọn ohun tí ẹnu ń jẹ ní wọ́n ń pèsè ní àyíká tó mọ́ láti dènà àìsàn tó leè sẹ́yọ nípasẹ̀ ìdọ̀tí, nítorí pé, ìjọba tó fẹ́ràn ará ìlú tó sì fi tiwọn ṣe àkọ́kọ́ ni ìjọba D.R.Y 

Nítorí náà, a kí gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) pé a kú oríire, bẹ́ẹ̀ ni a kí màmá wa Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ẹ seun lọ́pọ̀lọpọ̀,ìran Yorùbá mọ̀ọ́ lóore.

21. ÌTỌ́JÚ ÀWỌN ỌMỌ OLÓGO

Màmá wa, Olùgbàlà Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, sọ pé gbogbo ọmọ Yorùbá tí aburú ti dé bá ìgbésí ayé wọn látàrí ìwàk’iwà, ni yíò rí kádàrá wọn gbà padà gẹ́gẹ́bí ọmọ ológo tí Olódùmarè fẹ́ kí wọ́n jẹ́.

Ìyá wa sọ pé inkan tó bá máa gbà ni a máa fun, kí ògo wọn lè búyọ.

L’ọnà kíní, ìtọ́jú tí ó péye máa wà fún wọn, láti mú ọkàn àti ìrònú wọn kúrò nínú ìgbé-ayé òṣì, kí wọ́n le mọ̀ pé ayé míràn tún wà, yàtọ̀ sí ayé rádaràda tí wọ́n ti ngbé tẹ́lẹ̀, kí iyè wọn lè ṣí láti ní ìfẹ́ sí àwọn ìgbé-ayé rere!

Ọ̀nà kéjì, ìtọ́jú-ìwòsàn máa wà fún wọn, láti lè mú gbogbo àgọ́-ara wọn padà bọ́ s’ipò, kúrò nínú oríṣiríṣi àìṣedéédé tí ìgbé-ayé búburú ti tẹ́lẹ̀ ti kó sí wọn l’ara.

Ẹ̀kẹ́ta, ìrànlọ́wọ́ nípa ohun-ti-ẹ̀mí, gẹ́gẹ́bí ìgbẹ́kẹ̀lé oníkálùkù wọn máa wà, títí tí wọ́n á fi di ènìyàn gidi padà, tí ògo wọn á búyọ

22. ÌBÁṢEPỌ̀ PẸ̀LÚ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ

Ìránṣẹ́ Olódùmarè, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti fi yé wa ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà, pé a ò níí ti oko-ẹrú kan bọ́ sí òmíràn! Wọ́n sọ èyí nítorí pé, Olódùmarè ti fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àṣìrí ní àgbáyé han wọ́n, èyí tí ó wá wúlò nínú iṣẹ́ ìgbàlà tí Ẹlẹ́da rán wọ́n, fún ìṣerere Ìran Yorùbá.

Òtítọ́ pàtàkì ni pé, orílẹ̀-èdè tí ó bá dá Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) mọ̀, ni àwa náà máa dá-mọ̀ gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè.Orílẹ̀-èdè tí ó bá pọ́n wa lé, ni àwa náà máa pọ́n-lé.

Orílẹ̀-èdè tí ó bá bu ọ̀wọ̀ fún wa ni àwa náà máà bu ọ̀wọ̀ fún.Bẹ́ẹ̀ ni, gẹ́gẹ́bí MOA ti sọ, D.R.Y kò ní ṣe ẹrú fún orílẹ̀-èdè kankan ní àgbáyé!

Ojú tí orílẹ̀-èdè k’orílẹ̀-èdè bá fi wò wá, ni àwa náà máa fi wò ó!Bẹ́ẹ̀ náà ni a ò ní bá orílẹ̀-èdè kankan pàdípọ̀ máa b’ẹnu àtẹ́ lu orílẹ̀-èdè míràn!

A ò ní bá wọn gbè s’ẹyìn orílẹ̀-èdè kan ṣe lòdì sí òmíran, àbí kó ọ̀wọ́-àbòsí pẹ̀lú orílẹ̀-èdè kan tako orílẹ̀-èdè míràn.Paríparì gbogbo rẹ̀, ohun tí ó jẹ́ atọ́kùn ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú orílẹ̀-èdè tí ìbáà-wù kó jẹ́, ni pé, L’ẹyìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá Ni Àkọ́kọ́!

A ò ní ta ohunk’ohun ní rọ̀bì fún orílẹ̀-èdè míràn. Ohun tí a bá ma tà jáde, jẹ́ ohun tí a ti sọ di oníye-lórí, bẹ́ẹ̀ ni a ò ní fi orílẹ̀-èdè wa sílẹ̀ máa wá ohun-ìmúlò fún àwọn ilé-iṣẹ́ wa ní’bi tí kò tọ́.

Irúfẹ́ ìgbésẹ̀-akin wọ̀nyí, kò ní fi àyè gba orílẹ̀-èdè kankan láti fi ìwọ̀sí lọ D.R.Y abí Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), bẹ́ẹ̀ ni a ò ní kó ara wa sí àfọwọ́-fà burúkú kankan!

23. OÚNJẸ TÓ DÁRA

Ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ìgbádùn tí yóò wà fún wa kò lóǹkà, àìríjẹ ti di ohun ìgbàgbé ní ilẹ̀ Yorùbá, oúnjẹ tó dára ní a óò máa jẹ́, nítorí pé ìjọba D.R.Y kò ní fàyè gba ayédèrú oúnjẹ GMO tàbí lílo èròjà tó leè ṣe àkóbá fún àgọ́ ara nínú iṣẹ́ ọ̀gbìn.

Gbogbo àwọn ẹnu ibodè wa ni wọ́n yóò ti máa ṣe àyẹ̀wò fínnífínní lórí ohunkóhun tí wọ́n bá ń kó wọlé sí orílẹ̀ èdè wa èyí ni láti ríi dájú pé wọn ò kò oúnjẹ tó leè ṣe ìpalára wá fún wa.

24. Ojúse Ìjọba Fún Àwọn Ara Ìlú

Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), gbogbo ojúṣe tó yẹ kí àwọn ìjọba ṣe ni wọ́n yóò máa ṣe, tí wọ́n kò sì ní yọ ọ̀kan sílẹ̀ nítorí pé, ìjọba wa yóò nífẹ̀ẹ́ àwọn ará ìlú bẹ́ẹ̀ni wọn kò ní jẹ́ kí ìyà jẹ ẹnikẹ́ni tàbí tẹ ẹ̀tọ́ wọ́n lójú mọ́lẹ̀.

Ojúse ìjọba ni láti dáàbò bo ara ìlú, láti pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu, iṣẹ́, iná mọ̀nàmọ́ná, ètò ìwòsàn, ètò ẹ̀kọ́ tó yanranntí, omi, àti àwọn ohun am’áyédẹrùn lorísìírísìí.

Gbogbo ìwọ̀nyí ni a óò fi ojú wa rí ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, ètò sì ti ń lọ lọ́kàn-ò-jọ̀kan, ọmọ Yorùbá kankan kò tún j’ìyà mọ́, gẹ́gẹ́ bí màmá wa, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa wípé, gbogbo àwọn ọ̀dọ́ wa ni yóò rí ògo wọn lò, nítorí náà ayọ̀ ni ti wa.

25. Orílẹ̀-Èdè Wà Kò Ní Jẹ Gbèsè

Màmá Ìran Yorúbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti máa nfi yé wa pé ìkan nínú àwọn ọ̀nà tí àwọn amúnisìn fi máa nmú àwọn orílẹ̀-èdè ní ẹrú, ni nípa gbèsè jíjẹ. Àwọn ni wọ́n á fa orílẹ̀-èdè náà pé kó wá yáwo; àwọn ni wọ́n a sọ fun bí ó ṣe máa ná owó náà, àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ! Títí tí gbèsè á máa gun orí gbèsè!

Màmá wá fi yé wa pé, láyé, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) kò ní yá owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. Ohun tí a bá nílò, àwa ni a máa ṣé fún’ra wa; ohun tí a bá sì ṣe ni a máa lò.

Ànfààní t’ó wà nínú pé a ò ní jẹ gbèsè, ni pé, kò sí ẹnikẹ́ni tàbí àjọkájọ tí á le fi ipá tì wá sí ohun tí a kò fẹ́ ṣe! Àbùrọ̀ jẹ gbèsè ni àbùrọ̀ di ẹni tí kò lè kọ nkan tí ó yẹ kí ó kọ̀: èyí á wá di oko-ẹrú míràn; bẹ́ẹ̀ a ò tún ní lọ sí oko-ẹrú míràn láyé!

Àìjẹ-gbèsè á fún wa ní ìbàlẹ̀-ọkàn: kò ní sí pé tí a ò bá wá lè san gbèsè, oní-gbèsè á wá máa béèrè ohun t’ó máa pa wá l’ara!

Ìrọ̀rùn fún ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), pẹ̀lú ìbàlẹ̀-ọkàn fún D.R.Y, bákan-náà, òun ni aìjẹ-gbèsè máa jẹ́ fún wa. Ìtẹ́lọ́rùn ni a máa fi ṣe ìgbé-ayé wa gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè.

26. ÌTỌ́JÚ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́

Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá(Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ni yóò jẹ àǹfààní ìsèjọba tó kún ojú òṣùwọ̀n tó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ará ìlú.

Ìtọ́jú tó péyé yóò wà fún àwọn òṣìṣẹ́, ìjọba kò sì ní fi ẹ̀tọ́ wọn dùn wọn. Gẹ́gẹ́ bí màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa wípé, ọ̀sẹ̀ méjì-méjì ni àwọn òṣìṣẹ́ yóò máa gba owó ọ̀yà wọn.

Fún ìdí èyí, awa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) fi àkókò yí dúpẹ́ lọ́wọ́ màmá wa MOA fún gbogbo akitiyan wọ́n lórí ìran Yorùbá láti lè jẹ́ kí a bọ́ nínú ìnira, kò ní súu yín, kò ní rẹ̀ yín láṣẹ Èdùmàrè.

27. ÌDÀGBÀSÓKÈ ÌGBÈRÍKO

Ìdàgbàsókè gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ni ó jẹ ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) lógún, lábẹ́ ìṣàkóso Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá, nípasẹ̀ Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá.

Gẹ́gẹ́bí Màmá wa ti sọ, gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ni ó máa ní ìdàgbàsókè àti ìgbá’yé gbádùn. Èyí tó jẹ́ pé ibi yóò wù kí a wà, ojúlówó ohun amáyédẹrùn àti ìgbé-ayé àláfíà ni ó máa wà ní àrọ́wọ́to.

Láti mú èyí wá sí ìmúṣẹ, ipele mẹ́rin ni yóò wà nínú ètò ìdàgbàsókè káàkiri ilẹ̀ Yorùbá – ipele “Ìlú-Nlá” (Urban); “Ìlú Kékèké” (Sub-Urban); “Ìgbèríko” (Rural) àti “Ẹsẹ̀kùkú” (Sub-Rural). Bẹ́ẹ̀ ni ipele kọ̀ọ̀kan sì ní ojúṣe tirẹ̀ ní orílẹ̀-èdè  D.R.Y. Èyí túmọ̀ sí pé ipele tí àgbègbè kan bá wà ni ó máa ṣe àpèjúwe irú ohun amáyédẹrùn tí yóò wà níbẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn bí omi, títì t’ó dára, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, tí ó máa wà ní’bi gbogbo.

Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, agbègbè t’ó jẹ́ pé àwọn ní wọ́n npèsè oúnjẹ fún orílẹ̀-èdè wa, ó ní àwọn ohun ìdàgbàsókè tí ó gbọ́dọ̀ wà ní’bẹ̀; agbègbè tí ó jẹ́ pé ibẹ̀ ni àwọn ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ gbogbonìṣe pọ̀ sí, ó ní bí a ṣe máa ṣe ètò ìdàgbàsókè ibẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Nípasẹ̀ èyí, Ìgbèríko ní iṣẹ́ tirẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè tí ìlú-nlá kò lè ṣe: irú ìdàgbàsókè tí ó máa mú iṣẹ́ ìgbèríko dùn-ún ṣe, nínú ìrọ̀rùn, ni ó máa wà ní’bẹ̀, yàtọ̀ sí àwọn ohun amáyédẹrùn tí ó jẹ́ kòseémá nìí gbogbo D.R.Y.

Ohun tí a ń sọ ni pé Ìgbèríko ní D.R.Y kìí ṣe oko lásán tí ènìyàn máa p’ẹ̀gàn, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ ibi àmúyangàn tí ipò rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè kò ní ṣeé fi ọwọ́ rọ́ s’ẹ́yìn.