Kò ní dáa fún àwọn ọ̀bàyéjẹ́, olóṣèlú àti gbogbo àwọn amúnisìn ìjọba nàìjíríà tí wọ́n nfi ipá jẹgàba lórí ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y). Ìjẹgàba yí ni ó ṣe okùnfà kí ìyà ṣì máa jẹ ọmọ Yorùbá títí di ìsiìyí!

Láìpẹ́ yí ni a rí fọ́nrán kan tí ó fi hàn bí àwọn ènìyàn, tìtorí EBI, tí wọ́n tò láti inú ọgbà ilé-iṣẹ́ amóhùnmáwòrán LTV-8 ní ìpínlẹ̀ Èkó ní’bí tí ẹni tí ó sọ̀rọ̀ nínú fọ́nrán náà sọ pé àwọn ènìyàn ọ̀ún lọ gba ohun jíjẹ níbẹ̀ ni, wọ́n sì tò sí orí ìlà láti inú ìlé-iṣẹ́ náà, títí tí ìlà náà fi dé obírípo Agidingbi (Roundabout)! Háà, ohun tí ẹ sọ ọmọ Yorùbá dà nìyí, Nàìjíríà ajẹgàba!

Omi bọ́ lójú ẹni, ní rírí tí a rí àwọn ẹni-bí-ẹni, nínú ìdúró wọn, àwọn èèyàn bí èèyàn, lọ́kùnrin lóbìnrin ṣùgbọ́n tí ebi ti sọ di atọrọjẹ! Kò sí ojútì mọ́, wọ́n ní ebi kìí wọ’nú kí ọ̀ràn míràn ó tún wọ’bẹ̀; òun ló ṣe okùnfà àwọn tí ìdúró wọn ṣe-é mú yangàn ṣùgbọ́n tí wọ́n ti wá di ẹni tí ntò lójú títì, látàrí ká ṣáà rí ọwọ́ múlọ s’ẹnu!

Èdùmàrè, máṣe jẹ́ kí ètè Nàìjíríà lórí ọmọ Yorùbá kí ó ṣẹ; a dúpẹ́ pé o ti gbà wá; jẹ́ kí ìrírí-ojúkorojú ìgbàlà yí kí ó hàn ní gbàgede láìpẹ́ láìjìnà.

Ṣùgbọn gbogbo ẹ̀yin tí ẹ sọ pé ti Nàìjíríà ni ẹ fẹ́ máa ṣe, láì ní ẹ̀tọ́ ẹ̀ lórí ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba, kò ní dáa fún yín o! Láìpẹ́ àti láìjìnà, ìtìjú ni Nàìjíríà á fi sá kúrò lórí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá. D.R.Y kì nṣe ilẹ̀ Nàìjíríà, ẹ̀sín àgbáyé ni ẹ máa ṣe!

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal