Ètò ìlera àti ìwòsàn to péye, ti yio jẹ akọkọ irú rẹ ní àgbáyé – jẹ ìkan l’ara àgbékalẹ̀ ètò fun gbogbo ọmọ bíbí orílè-èdè Yorùbá ti a mọ si Blueprint.
Gẹ́gẹ́ bi mama wá, Ọmọ-Aládé Modupeola Onitiri-Abiola ṣe sọ wípé ko tun ni si òun ti ò njẹ “kosisẹ” tabi “òṣì” tabi tálákà láwùjọ ọmọlúwàbí mọ, nítorí náa, iforukosilẹ rẹ ṣe pàtàkì fun wa láti le fòpin si òṣì ati isẹ káàkiri orílè-èdè Yoruba.
Ilẹ̀ Yorùbá kùn fún wàrà àti oyin pẹlu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọlọpọlọ pípè àmọ́ tí ìlú mújẹ-mújẹ Nàìjíríà kọ jẹ kí ara ìlú mọ. Boju-boju ni wọn fi bo yín loju, Òun ti o nbẹ nilẹ Yorùbá nìkan-nìkan o to fun gbogbo ilẹ̀ Afíríkà.
Lati rí dájú pe ìdàgbàsókè ati Itesiwaju de ba ìlú wá ati ọrọ ajé wá, ìjọba nrọ ẹyin ara ìlú ti ẹ jẹ ọmọ bíbí orílè-èdè Yorùbá, ki ẹ so’wọpọ pẹlu wa nípa fífi àwọn orúkọ yin pẹlu àlàyé àwọn oríṣiríṣi ìṣẹ ti ẹ yan láàyò, kí ó ba le rọrùn fún wa láti pèsè isẹ fún gbogbo wa.
Èmi ko ní iriri ko si nbẹ rárà!
Èmi ko gbọ èdè òyìnbó ko si nbẹ rárà!
Erongba wa ni lati jẹ orílè-èdè ti o ni idagbasoke julọ ni agbaye. À ko le ṣàṣeyọrí eyi laisi imọ, ọgbọn, ati oye yín; nitori náa, ẹ ba wá fi orúkọ yin ránṣẹ́. Ẹ jẹ ka so’wọpọ lati pèsè ọjọ ọla ti o dara fun awọn ọmọ wa ati awọn ìran ti nbọ lẹyin-wa-ọla!
Àkíyèsí Pàtàkì
1. Fọwọsi fọọmu yi gẹgẹbi a ṣe gbé kalẹ; Awọn aaye tí à sàmìnsí (*) jẹ dandan fún wa!
2. Rí dájú pé òtítọ́ ni gbogbo òun ti o fi ránṣẹ́ ki o ma ba pàdánù àǹfààní náa.
3. O gbọdọ jẹ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá! Ẹnikẹ́ni ti o ba fi orúkọ rẹ silẹ – ti ki ńṣe ọmọ ìbílẹ̀ orilẹ-ede Yorùbá, ní à o yọ kúrò.
Yes, You can apply. The Democratic Republic of the Yoruba is for the Indigenous People of Yoruba irrespective of where you are, you entitled to all the benefits.