Ìròyín tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára X, ìkànnì @SaharaReporters, sọ pé àwọn agbésùnmọ̀mí ti gbé Agbaninímọ̀ràn dókítà fún àwọn obìnrin àti aláboyún ní ilé-ìwòsàn kan ní ìlú tó fẹ̀gbẹ́ tì wá, Nàìjíríà.

Orúkọ dókítà náà ni Oníṣègùn Abídèmí Ọyárọ̀máde, tí ó nṣiṣẹ́ ní ‘Federal Medical Centre’ ní ìlú Gusau, ìpínlẹ̀ Zamfara ni ìlú àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà l’ọhún.

Ìdí tí ìròyìn yí fi kàn wá ni pé orúkọ Yorùbá ní dókítà yí njẹ́. Ìjẹgàba tí Nàìjíríà jẹgàba sórí ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) jẹ́ kí ó túbọ̀ ká wa lára, torí pé ìwà ìkà gbáà ni, ẹ jẹgàba sórí ilẹ̀ wa, ọmọ Yorùbá tó nṣiṣẹ́ ní ìlú yín Nàìjíríà kò tún ní àbò tí ó péye. Ẹ kúrò lórí ilẹ̀ wa. Kì nṣe ilẹ̀ Nàìjíríà.

Ní ti àwọn ojúlówó ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá tí wọ́n ngbé ní Nàìjíríà, ilẹ̀ òkèèrè ni Nàìjíríà jẹ́ sí wa o, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aláwọ̀dúdú ni àwọn náà; ṣùgbọ́n oníkálukú ló mọ àlà tirẹ̀, láì fi ti ìjẹgàba Nàìjíríà si rárárárá.

A gba ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) tí ó bá wà ní Nàìjíríà tàbí ibikíbi ní àgbáyé, ní’mọ̀ràn kí wọ́n máa bọ̀ nílé. Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ti di orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún.

Ẹ máṣe dúró sí ibi tí wọ́n ti lè lé yín tàbí ṣe jàmbá fún yín nígbàkúgbà.