Ohun tí ó bá wu ènìyàn ni ó lè fi ìgbé-ayé rẹ̀ ṣe o! ṣùgbọ́n, ẹni a wí fún, ọba jẹ́ ó gbọ́!
Ìròyìn tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára X, sọ pé ẹnikan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Gbóyèga Isiaka, tí wọ́n sọ pé ó nṣojú “Àríwá Yewa àti Imeko-Afon“, Ìpínlẹ̀ Ògùn tí ó jẹ́ ara Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), wọ́n ní ó nṣe ojú wọn ní ilé-ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣ’òfin ní ìlú Nàìjíríà, ni ó sọ ọ̀rọ̀ kan síta o.
Àkọ́kọ́ ná, ìpínlẹ̀ Ògùn jẹ́ ìkan nínú àwọn ìpínlẹ̀ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y), èyí tí ó sì ti jáde kúrò lára Nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù bélú ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún, bẹ́ẹ̀ náà ni a ti ṣe Ìpolongo Ìṣèjọba-Ara-Ẹni wa láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún tí a wà nínú rẹ̀ yí: nítorí náà,
kò yé wa o, kíni ìtumọ̀ pé ẹnikan nṣojú Yewa, orílẹ̀-èdè D.R.Y, ní ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin Nàìjíríà, tí ó yàtọ̀ pátápátá sí D.R.Y! Kí ló njẹ́ bẹ́ẹ̀!? Ààà, ìwọ Gbóyèga Isiaka yẹn, o tí dá ọ̀ràn o! O ti ṣe àkọlù sí Ìṣèjọba-Ara-Ẹni Orílẹ̀-Èdè D.R.Y.
Kí wá ni ọ̀daràn Gbóyèga Isiaka náà sọ o? Ìròyìn náà sọ pé ó nsọ̀rọ̀ nípa ètò ẹ̀yáwó fún àwọn akẹ́kọ ilé-ẹ̀kọ́ gígá gbogbonìṣe ní ìlú nàìjíríà.
Ẹ jọ̀wọ́, ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ẹ máṣe yá owó kankan tàbí gba ohunkóhun lọ́wọ́ Nàìjíríà o!
Àkọ́kọ́, ẹ kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà. Èkéjì, tí ẹ bá gba owó tí Nàìjíríà nfún àwọn ọmọ Nàìjíríà, ẹ ti sọ pé ẹ kìí ṣe ọmọ D.R.Y nìyẹn o! Àrọ́mọ-d’ọmọ yín, láyé, kò sì lè ní ẹ̀tọ́ sí ohunkóhun tó wà fún ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá.