Báwo ni ìbá ṣe dùn tó, ẹ̀yin Ọmọ Igbó-Ọrà, tí ó bá jẹ́ pé ní àkókò tí ó ti yẹ kí a lọ pàdé ìjọba-Adelé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ní ìlú Ìbàdàn, ní ọjọ́ kẹ́tàláá sí ìkẹ́rindín lógún oṣù igbe ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún yí, ni gbogbo wa ti ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ó bà ni, kòì tíì bàjẹ́; ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé a ti bọ́ síta níjọ náà ni, kí ìjọba Adelé wa ti wọ’nú oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba, ayẹyẹ àwọn Ìbejì ti ọdún yí ní Igbó-Ọrà ìbá jẹ́ ohun mánigbàgbé.
Ìròyìn tí a gbọ́ sọ pé oṣù-ọ̀wàrà yí ni ọdún àwọn Ìbejì ní ìlú Igbó-Ọrà, Democratic Republic of the Yoruba, tí Igbó-Ọrà sì jẹ ibi tí a gbọ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn rí wọn gẹ́gẹ́bí ibi tí Ìbejì pọ̀jù sí ní Àgbáyé.
A ní ìrètí àti ìdùnnú pé láìpẹ́ yí ni Olódùmarè máa ṣí’dí ajẹgàba Nàìjíríà àti àwọn ẹmẹwà rẹ gbogbo kúrò ní ilẹ̀ Yorùbá; nígbànáà ni ayẹyẹ àwọn Ìbejì ní Igbó-Ọrà kò ní jẹ́ tí ebi tàbí ìnira, nítorí ìjọba Adelé Orílẹ̀-Èdè Yorùbá yíò ti wà nínú oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo.
Ìwọ tí o pera rẹ ní gómìnà, o ò kì nṣe gómìnà D.R.Y o, ilẹ̀ D.R.Y sì ni Igbó-Ọra àti gbogbo Ìpínlẹ̀ Ìbàdàn wà (èyí tí ó njẹ́ Ìpínlẹ̀ Ọyọ́ nígbàti Democratic Republic of the Yoruba kòì tíì dá dúró kúrò nínú Nàìjíríà). Nítorí náà kúrò ní ilé-iṣẹ́ ìjọba tí o jẹgàba sí: láìpẹ́ láìjìnà, o máa ṣẹ̀sín jáde náà ni.
Gbogbo ọmọ Igbó-Ọrà, ẹ gbárùkù ti Orílẹ̀-Èdè wa, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ẹ mọ̀, dájú, pé a ti kúrò nínú Nàìjíríà ní ogúnjọ́ oṣù bélú ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún, a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba wa ní ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún.