A ò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ o, tàbí ibí gan-an tí ó ti ṣẹ’lẹ̀; ohun tí a ṣáà rí lórí ayélujára X, sọ pé “South West” èyí tí kìí ṣe orúkọ wa, ṣùgbọ́n tí àwọn tó ndá’ràn máa nsọ, dípò kí wọ́n pe Orúkọ wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ni ó ti ṣẹ’lẹ̀.
Ìyẹn bẹ́ẹ̀. Nínú fọ́nrán náà ni a ti rí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin tí wọ́n nbọ̀ láti ibi kan, tí gbogbo wọ́n sì gbé àpò s’orí, èyí tí ìròyìn náà sọ pé àpò ìrẹsì ni.
Ìwòye wa ni pé àwọn kan ni wọ́n pin fún wọn – gẹ́gẹ́bí ìròyìn náà pàápàá ṣe sọ pé ebi l’ó fa èyí!
Àánú ṣe’ni l’ati rí àwọn obìnrin, àwọn Ìyá, ní Ìran Ọmọ Aládé, tí wọ́n kún gbogbo ojú títì, l’ọtún l’osì tí ojú kò rí ibi tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èrò náà ti nbọ̀, bí aláìríjẹ tí ó wá kúkú gbà pé kò sí ìtìjú mọ́, kí òun ṣáà ti ri nkan fún àwọn ọmọ òun jẹ.
Gbogbo ìwọ̀nyí dá lé orí fífi ipá dúró s’orí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba tí Nàìjíríà nṣe. Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ti fi wá l’ọkàn ba’lẹ̀, pẹ̀lú àánú àti Oore-Ọ̀fẹ́ Olódùmarè, pé àwa ni a máa r’ẹyìn wọn.
Ẹ jẹ́ kí á máa gbárùkù ti ijọba-Adelé wa; a ti fẹ́rẹ̀-ẹ́ dé’bi tí a nlọ – èyí tí ó jẹ́ inú oríkò-ilé-iṣẹ́ Ìjọba wa gbogbo, káàkiri ilẹ̀ Yorùbá; ìgbáyé-gbá’dùn á wá bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu fún gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P). Ó ku díẹ̀, ọmọ Aládé máa bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbé-ayé ìrọ̀rùn, ọlá àti ọrọ̀ tí Olódùmarè kọ mọ́ wa l’ara.
Njẹ́ a ti ngbáradì láti ṣe ojúṣe wa ní Orílẹ̀-Èdè Yorùbá wa yí? Ṣé a ti lọ sí ilé-iṣẹ́ ayélujára www.democraticrepublicoftheyoruba.com láti fi orúkọ wa sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá? Iṣẹ́ tí a fẹ́ ṣe nkọ́? Ṣé a ti nṣe àkójọpọ̀ ìlànà bí a ṣe fẹ́ ṣe-é? Ẹ jẹ́ kí a rántí pé owó kò lè jẹ́ ìdínà fún ohun rere tí á bá fẹ́ ṣe o! Nítorí orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y máa ràn wá l’ọwọ́, tí sísan’wó padà kò sì ní mú ìnira dání!