Olódùmarè má fi ìyà ṣe tiwa nítorí, ìyà kìí ṣe omi ọbẹ̀.
Fọ́nrán kan ni a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tò láti gba iṣu ẹyọ kan ṣoṣo.
Aò mọ ìlú tí ìṣẹ̀lẹ̀ yí ti ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n àmọ́ pé ilẹ̀ Yorùbá ni, nítorí èdè Yorùbá ni wọ́n ń sọ.
Ìkòríta tí ìjọba aríremáse nàìjíríà bá àwa ọmọ Yorùbá dé nìyí. Wọ́n fẹ́ kí àwọn ènìyàn rí igá nílẹ̀ báyìí, kí wọ́n pèé ní owó.
Àwọn ni ó da Fúlàní síta láti máa pa àwọn ènìyàn nínú oko, kí wọ́n má baà lè lọ sí oko mọ́, kí wọ́n sì sọ wọ́n di atọrọjẹ ní ọjọ́ ọ̀la àti láti leè máa dárí wọn bó ti wù wọ́n nítorí ẹni tó bá ń fúnni ní oúnjẹ ni ọ̀gá ẹni, ohun tó bá sì ti sọ ní wọ́n máa tẹ̀lé.
Ìjọba afipá jẹgàba nàìjíríà sọ àwa ọmọ Aládé di oníbáárà lórí ilẹ̀ babańlá wa, ní ìlú tí Olódùmarè kẹ́ pẹ̀lú ohun àlùmọ́ọ́nì lorísìírísìí tí kò sí irú rẹ̀ ní àgbáyé.
Ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó gbà wá lọ́wọ́ apanilẹ́kún jayé nàìjíríà nípasẹ̀ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla Tó fi iṣẹ́ náà rán sí ìran Yorùbá.
Ọ̀dájú àti ìkà ni àwọn olóṣèlú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí ó ń fi agídí jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, kò sì sí ohun rere kan tó lè ti inú ìlú náà jáde mọ́.