ÀǸFÀÀNÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TÍ YORÙBÁ: AYÉ ÌDẸ̀RÙN FÚN I.Y.P
Ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (D.R.Y), a kí ara wa kú oríre fún ayé ìdẹ̀rùn tí Olódùmarè lo màmá wa, Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) fún, nípasẹ̀ mùdùnmúdùn àlàkalè ètò tí Olódùmarè fi rán màmá wa MOA sí àwa ọmọ aládé. Láti ọmọ ọwọ́ títí di arúgbó, ìgbé ayé ìrọ̀rùn […]
KÒ SÍ NKAN TÓ NJẸ́ “WARRIOR” MỌ́
Ìyá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè, Ìyá-Ààfin), ẹni tí Olódùmarè rán sí àwa ọmọ Yorùbá láti ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún wa, ti gbé ohùn síta fún gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) pé, Kò sí nkankan tó njẹ́ “warrior” mọ́ ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y); […]
ÀǸFÀÀNÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TÍ YORÙBÁ: ÌMỌ́TÓTÓ D.R.Y
Ìmọ̀tótó borí àrùn, bí ọyẹ́ ṣe nborí oru. Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ìmòtótó jẹ́ nkan gbòógì tí a kò lè fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ní orílẹ̀ èdè wa, láti dènà àìsàn àti àrùn ní àyíká àti agbègbè wa. Láìsí ìmọ́tótó agbègbè àti àyíká wa, nílé, lóko, […]
Ẹ PADÀ SÍ ILÉ YÍN!
ỌMỌ ÌBÍLẸ̀ YORÙBÁ (Indigenous Youba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ẹ jẹ́ kí á ṣe ìfiyèsí pàtàkì yí: àwọn kan wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṢUN, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), tí wọ́n pe orúkọ ara wọn ní SEGILỌLA RESOURCES OPERATING LIMITED (SROL), wọ́n nwa àlùmọ́nì wa, wọ́n nwa GÓÒLÙ wa, ní […]
ÀǸFÀÀNÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TÍ YORÙBÁ: ÌGBÁYÉGBÁDÙN ÀWỌN ÈWE
Gbogbo èwe I.Y.P ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ni a kí kú oríre nítorí láti inú oyún ni wọn yóò ti máa jẹ ìgbádùn àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé fún màmá wa, Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin). Èyí yóò jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nínú ayé èwe I.Y.P. Ètò ti wà […]
SẸ̀GÍLỌLÁ NWA GÓÒLÙ D.R.Y!
TORONTO VENTURE EXCHANGE ni wọ́n wà o! Orúkọ wọn ni THOR EXPLORATIONS LIMITED, iṣẹ́ wọn ni láti máa wa GÓÒLÙ, káàkiri ìwọ̀-oòrùn Áfríkà! Ìkan nínú àwọn ilé-iṣẹ́ wọn ni, SEGILỌLA RESOURCES OPERATING LIMITED (SROL). Gẹ́gẹ́bí orúkọ wọn ṣe so, àwọn ohun-àmúṣọrọ̀ (Resources) ni wọ́n nwá kiri. Àwọn SEGILỌLA RESOURCES OPERATING LIMITED yí, wọ́n sọ pé […]
I.Y.P Ẹ PARIWO SÍ AYÉ GBỌ́, NÀÌJÍRÍÀ KÌÍ ṢE ORÍLẸ̀ ÈDÈ
Tí irọ́ bá lọ f’ógún ọdún, ọjọ́ kan ṣoṣo ni òtítọ́ yóò bàa. Ṣé ọjọ́ ti pẹ́ tí àwọn amúnisìn ti kó ìran Yorùbá sínú ìdààmú nípa síso irun iwájú pọ̀ mọ́ ti ìpàkọ́ tí wọ́n kó orílẹ̀ èdè Yorùbá papọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè míràn láti máa pè wọ́n ní Nàìjíríà. Ṣùgbọ́n nígbà tí […]
ÀǸFÀÀNÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TÍ YORÙBÁ: Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ ÌGBÁDÙN FÚN I.Y.P
Olódùmarè fi ọrọ̀ rẹpẹtẹ dá ilẹ̀ Yorùbá lọ́lá, Ó fún wa ní ilẹ̀ ọlọ́ràá tó nṣe àtìlẹyìn fún oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn láti so dáradára àti lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ní ìgbà òjò, ẹ̀rùn, ooru, òtútù ati bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀, nítorínáà, a ó ní ànító oúnjẹ àti àjẹṣẹ́kù. Ní àfikún, Olódùmarè fún wa ní àwọn ènìyàn tó pọ̀, tó sì ní […]
GBOGBO I.Y.P TI D.R.Y Ọ̀KAN NI WÁ
Ìkan nínú ọ̀rọ̀ tó ṣe gbòógì tó pè fún àkíyèsí, tí màmá wa Olóyè Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá sọ jẹ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì “Lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè Yorùbá ni Àkọ́kọ́“. Màmá wá MOA tẹnu mọ fún àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (lndigenous Yorùbá People, l.Y.P) tí Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y), wípé “ÒKAN” ni wá bí òṣùṣù […]
Ẹ̀KỌ́ ÈDÈ YORÙBÁ
Màmá wa Olóyè Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá ti jẹ́ kí á mọ̀ pàtàkì Èdè abínibí wa, èyí tí nṣe èdè YORÙBÁ àti wípé, èdè ni ìdánimọ̀ ẹni, Orílẹ̀ èdè tó bá sì ti sọ èdè rẹ̀ nù, Orílẹ̀ èdè bẹ́ẹ̀ ti sọ ìdánimọ̀ rẹ̀ nù. Gẹ́gẹ́bí àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè fi rán màmá wa MOA sí ìran […]