Nínú ìròyìn kan tí a kà lórí ẹ̀rọ ayélujára nípa ọmọbìnrin olóògbé Brigadier Samuel Adémúlégún, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣọlápé Adémúlégún tó jáde fún if’ọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nípa ìdìtẹ̀ gbà ‘jọba tó wá’yé ní ọjọ́ karùndínlógún osu Sẹ́rẹ́ ẹgbàá ọdún ó-dín-mẹ́rinlélọ́gbọ̀n, ní ìgbà tí arábìnrin Ṣọlápé yìí wà ní ọmọ ọdún mẹ́fà.
Ìpànìyàn tó ṣẹlẹ̀ lójú arábìnrin yìí ni ọmọ ọdún mẹ́fà tí wọ́n pa ìyá àti bàbá rẹ̀ ní ojú rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ ọkùnrin ọmọ ọdún mẹ́rin, kò kúrò ní ọpọlọ arábìnrin yìí títí di òní.
Ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ìjàǹbá púpọ̀ nínú ayé arábìnrin yìí, tó fí níláti kọ ìwé jáde lórí bí àwọn ológun ìlú agbésùnmọ̀mí apanimáyọ’dà nàìjíríà, fi pa àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì ní oju òun àti àbúrò rẹ̀.
Àwa ìran Yorùbá dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè fún àánú tí a rí gbà pẹ̀lú iṣẹ́ ribiribi tí, màmá wa, ìyáàfin Modúpẹ́ọlá Onitìrí-Abiọ́lá ṣe láti gbà wa kúrò lọ́wọ́ ìpakúpa tí àwọn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà ń pa àwọn ọmọ ológo ilẹ̀ Yorùbá, kí a lè bẹ̀rẹ̀ si rí ògo wa lò títí ayé.
Àwa Indigenous Yorùbá People, (I.Y.P.), ẹ jẹ́ kí gbogbo wa gbárúkù tí Olórí Adelé àti gbogbo àwọn adelé Ìpínlẹ̀ méjèèje láti lè tètè bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ìgbádùn ohun mère-mère tí Olódùmarè yọ̀nda fún àwọn bàbá ńlá wa lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá, (D.R.Y.).