Aṣemáṣe gbáà ni orìlẹ̀-èdè China àti àwọn ilé-iṣẹ́ aládani rẹ̀, bíi CCECC (China Civil Engineering Construction Company), àti àwọn míràn bẹ́ẹ̀ láti àwọn orílẹ̀-èdè ní Asia, nṣe báyi o, ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).
Ìròyìn tí a rí fídíò rẹ̀ l’orí YouTube, fi hàn gbangba pé nṣe ni àwọn ilé-iṣẹ́ aládani láti agbègbè Asia wọ̀nyí, pẹ̀lú àtìlẹ́yìn àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè wọn, nra ilẹ̀ lọ ràì, ní ìpínlẹ̀ Èkó, tí ó sì tún jẹ́ pé pẹ̀lú ìbuwọ́lù tàbí ìf’ọwọ́sí ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ni.
Ohunk’ohun t’ó wù k’ó jẹ́, ohunk’ohun t’ó wù k’ó ṣe, ìnkank’inkan ìyíó-wù kí wọ́n ti ṣe, òótọ́ tí ó wà nínú ibẹ̀ ni ìwọ̀nyí:
Èkíní, ohunk’ohun, ìbáṣepọ̀-k’ibáṣepọ̀, àdéhùn-k’adéhùn tí ìbáà-wù kí nàìjíríà tàbi ìpínlẹ̀ kankan ní ilẹ̀ Yorùbá, nígbàtí a ṣì wà nínú Nàìjíríà (èyí tí ó túmọ̀ sí pé, kí ó tó di ogúnjọ́-oṣù-bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún); ohunk’ohun tí wọn ìbáà ti ní papọ̀ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè míràn, tàbí ilé-iṣẹ́ kankan, gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ṣe sọ fún wa, máa jẹ́ ohun àpérò, èyí tí àwọn ọmọ Yorùbá máa wò fín-ní-fín-ní, láti mọ ṣé ó kàn wá, báwo l’ó ṣe kàn wá, àti èló l’ó kàn wá ní’bẹ̀?
Èkejì; l’ẹyìn ìkéde Òmìnira Yorùbá ní ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjì-lé-l’ógun, títí di àkókò tí a ṣe Ìpolongo Ìṣèjọba-Ara-Ẹni Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ní ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, ohunk’ohun tí ẹnik’ẹni, orílẹ̀-èdè-k’orílẹ̀-èdè, tàbí ilé-iṣẹ́ k’ilé-iṣẹ́ bá ní’ṣe pẹ̀lú nàìjíríà, tàbí ìpínlẹ̀ kankan ní D.R.Y tàbí ẹnik’ẹni ní ilẹ̀ D.R.Y, tí wọ́n sì ṣe-é lábẹ́ pé ilẹ̀ Yorùbá ṣì wà nínú Nàìjíríà (tí èyí kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá); òfúùtù-fẹ́ẹ̀-tẹ̀ ni o! Ìmúlẹ̀-m’ofo ní o! Kò kan orílẹ̀-èdè Yorùbá rárá!
Ẹ̀kẹ́ta, gbogbo àdéhùn àti ohunk’ohun tí ẹník’ẹni tàbí orílẹ̀-èdè tàbí ilé-iṣẹ́ k’ilé-iṣẹ́, tí wọ́n bá ní pẹ̀lú Nàìjírà tàbí ẹnikẹ́ni, ìjọba tàbí ilé-iṣẹ́ tí wọ́n nlo orúkọ ajẹgàba nàìjíríà, ní orí ilẹ̀ D.R.Y, l’ẹyìn tí a ti ṣe Ìpolongo Ìṣèjọba-Ara-Ẹni wa, gbogbo ohun bẹ́ẹ̀ jẹ́ Ọ̀RÀN DÍDÁ l’abẹ́ òfin D.R.Y.
Ẹ̀kẹ́rin, kí gbogbo àgbáyé ó mọ̀ pe, ilẹ̀ Yorùbá, ti ọmọ-Yorùbá ni.
Nítorí nkan wọ̀nyí, ìwọ ni China, ìwọ ni Orílẹ̀-Èdè-k’orílẹ̀-èdè, tàbí ILÉ-IṢẸ́ tí ó nṣe ohunk’ohun ní ilẹ̀ Yorùbá, tàbí tí àdéhùn kankan wà tí ẹ dárúkọ ibik’ibi ní ilẹ̀ Yorùbá sí, kí ẹ yáà mọ̀ pé kò kan orílẹ̀-èdè D.R.Y, ẹ̀yin ni ẹ máa f’orí fa!