Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni wọ́n pe’ra wọn ní àgbà ṣùgbọ́n ọpọlọ kọ́bọ̀ kò sí lórí wọn.
Ní orí ẹ̀rọ Ayélujára ni a ti rí fọ́nrán kan níbi tí àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní Yorùbá, tí wọ́n tún sọ pé àgbà ni àwọn, tí wọ́n nsọ̀rọ̀ aríremáse nàìjírà bíi pé Orílẹ̀-Èdè Yorùbá wà níbẹ̀! Ọṣọba wà níbẹ̀ pẹ̀lú Bísí Àkàndé. Ó mà ṣe ò. Báwo ni ènìyàn á ṣe pe arà rẹ̀ ní àgbà tó ní ìfẹ́ Yorùbá lọ́kàn ṣùgbọ́n tí kò fi ọpọlọ si láti mọ kí ló nṣẹlẹ̀ nípa Yorùbá.
Ṣé àwọn wọ̀nyí á sọ pé àwọn ò mọ̀ pé láìpẹ́ yí, àwọn olórí orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó pé jọ sí ìpàdé ìkọkàn-dín-lọ́gọ́rin àjọ àgbáyé ní ìlú New York gbúro àwọn ọmọ Yorùbá tí wọ́n nṣe àjọ̀yọ̀ orílẹ̀-èdè tuntun jùlọ ní Àgbáyé – Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), tàbí wọ́n gbọ́ ṣùgbọ́n wọ́n kọ etí ikún síi ni? Èyí á wá túmọ̀ sí pé apanilẹ́kún jayé nàìjíríà ló tẹ́ àwọn bàbá yí lọ́rùn.
Ṣèbí ohun tí wọ́n fẹ́ ni; oníkálùkù ló ní ẹ̀tọ́ láti fẹ́ ohun tí ó wùú; ṣùgbọ́n, ẹ̀yin bàbá wọ̀nyí, ọ̀ràn ni ẹ ń dá. Ilẹ̀ Yorùbá ti kúrò ní èyí tí a máa ṣe gọ̀ṣú-gọ̀ṣú tẹ̀lé bàbá kankan. Tí ẹ ò bá mọ̀, ẹ̀yin bàbá wọ̀nyí, ìkọlu-orílẹ̀-èdè-aṣèjọba-ara-ẹni ni ọ̀ràn tí ẹ ndá o, nípa pípe ilẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá mọ́ ara agbésùnmọ̀mí nàìjíríà. Ẹ máṣe sọ pé ẹ ò mọ̀, ààbọ̀ ọ̀rọ̀ ni a nsọ fún ọmọlúàbí; wọ́n ní ìgbà tó bá dé inú rẹ̀ ni ó máa di odindi.
Ẹ máṣe sọ pé ẹ ò gbọ́, ìlẹ̀ tí ẹ̀yín npè ní “South-West” yẹn, pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ Yorùbá míràn, pàápàá, ti jáde kúrò nínú apaná ògo nàìjíríà ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, a sì ti ní ìṣèjọba tiwa láti ọjọ́ kéjìlá oṣù Igbe ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún; nítorí náà gbogbo èyí tí ẹ ń sọ yí, ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀ràn dídá gbáà ni.