ÌRAN YORÙBÁ ÀTI LÀÁKÀYÈ
Bàbá kan ní Ìlú Ọfà, láyé ijọ́un, nígbà tí ó fẹ́ re’bi àgbà ń rè, ó fi ìṣúra sílẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, kí wọ́n pin ní ọgbọọ-gba. Àgbà ọ̀mọ̀wé kan ló sọ ìtàn yí nínú fídíò kan tí a rí, ó sì ṣe àlàyé bí àwọn àgbà’gbà ayé-ijọ́un ṣe ṣe ètò pínpín náà, […]