Bàbá kan ní Ìlú Ọfà, láyé ijọ́un, nígbà tí ó fẹ́ re’bi àgbà ń rè, ó fi ìṣúra sílẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, kí wọ́n pin ní ọgbọọ-gba.
Àgbà ọ̀mọ̀wé kan ló sọ ìtàn yí nínú fídíò kan tí a rí, ó sì ṣe àlàyé bí àwọn àgbà’gbà ayé-ijọ́un ṣe ṣe ètò pínpín náà, èyí tí kò ṣe-é ṣe ní ònkà ìwọ-gba-tìẹ ẹnikọ̀ọ̀kan.
Ohun tí Bàbá fi sílẹ̀ dàbí kí á mú ẹgbàá nǹkan fún ènìyàn mẹ́ta láti pín ní ọgbọọ-gba.
Wọ́n ní kí ẹnikọ̀ọ̀kan ó mú ẹgbẹ̀ta nínú ohun tí bàbá wọn fi sílẹ̀, ṣùgbọ́n wọn ri pé ó ṣì ku igba, èyí tí kò sì ṣe é pín sí ọ̀nà mẹ́ta ọgbọọ-gba. Ni wọ́n bá ní kí ẹnikọ̀ọ̀kan ó tún mú ọgọ́ta, ló bá ku ogún sílẹ̀!
Ogún kò sì ṣe é pín sí ọ̀nà-mẹ́ta ọgbọọgba! Ni wọ́n bá tún ní kí wọ́n tún mú ogún yí ní mẹ́fà-mẹ́fà ẹnikọ̀ọ̀kan! Ló bá ku méjì sílẹ̀! Báwo ni a ṣe fẹ́ pín nǹkan méjì láarín ènìyàn mẹ́ta ní ọgbọọgba?
Àwọn àgbà ìlú Ọ̀fà wá ní kí wọ́n mú méjì náà lọ sí ọjà, kí wọ́n fi ra ataare! Ni wọ́n bá ra ataare, ó sì ní awẹ́ mẹ́ta, Lọ̀rọ̀ bá bùṣe.
Ọ̀jọ̀gbọ́n yí wá sọ pé ohun tí ẹ̀rọ kọ̀mpútà ń ṣe láyé òde òni nìyẹn, tí àwọn babańlá wa fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ, tí ayé sì tùbà tó tùṣẹ !
YORÙBÁ, ayé ndúró de làákàyè rẹ!
Ìyá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá sọ pé ìmọ̀, ọgbọ́n àti òye àwọn babanlá wa ni a máa gbé lárugẹ; ògo ti èyí á sì tún wá tayọ ti àtẹ̀yìnwá.