Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀jù-Lẹ̀kkí tí Dangotè, ọmọ Fúlàní ṣe ilé-iṣẹ́ ìfọ’po sí, ní ìlẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), tí ó sì sọ pé òun san ọgọ́run mílíọ̀nù dọ́là fún ẹgbẹ̀rún-méje ékà ilẹ̀ náà, kò tíì kúrò nílẹ̀. 

A gbọ́ ìròyìn tí ó sọ pé àwọn kan tí wọ́n pe’ra wọn ní “Ibeju-Lekki People’s Forum” ti pe àwọn ajẹgàba tó dúró sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba wa ní ìpínlẹ̀ Èkó l’ẹ́jọ́, pé kí wọ́n wá ṣe àlàyé lórí owó tí Dangote sọ pé òun san ọ̀hún.

Ìròyìn yí sọ pé ọ̀rọ̀ náà tako ohun tí àwọn ènìyàn gbàgbọ́, wípé ọ̀fẹ́ ni Dangote gba ilẹ̀ náà!

Dangotè, ìjọba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà tó ń jẹgàba lórí ilẹ̀ D.R.Y, ní pàtàkì ìpínlẹ̀ Èkó, àti ẹyin tí ẹ pe’ra yín ní “Ibeju-Lekki People’s Forum”, gbogbo yín, ọ̀daràn!

Dangotè, o mọ̀ pé ilẹ̀ Yorùbá ti jáde kúrò nínú aríremáse Nàìjríà láti ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún; o sì mọ̀ pé a ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba tiwa láti ọjọ́ kéjìlá, oṣù Igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún, nítorínáà, oò ní ẹ̀tọ́ mọ́ láti j’ábọ̀ fún ẹnikẹ́ni lórí ọ̀rọ̀ yí yàtọ̀ sí ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y); ìjọba D.R.Y ni ó  máa sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ìjọba gbésùnmọ̀mí  Nàìjíríà tó ń fi’pá jẹ gàba lórí ilẹ̀ D.R.Y, pàápàá ní Ìpínlẹ̀ Èkó, d’ẹkun ìwà ìkọjá-àyè àti ìdúnkòokò tí o ń ṣe, ẹ̀ṣẹ̀ ni o ń dá níwájú àgbáyé, wàá kábamọ̀ láìpẹ́. 

Ẹ̀yin tí ẹ pe’ra yín ní Ibeju-Lekki People’s Forum; kò sí “mi ò mọ̀ ni” lábẹ́ òfin o! Ìjọba D.R.Y ti fagilé gbogbo ẹgbẹ́ ní ọjọ́ náà tí ìṣèjọba-ara-ẹni D.R.Y bẹ̀rẹ̀!

Ọ̀ran-dídá ni láti pe ara yín ní ẹgbẹ́; kí gbogbo àwa ọmọ Yorùbá, gbárùkù ti ìjọba-Adelé wá kí orílẹ̀ èdè wa leè gòkè àgbà.