Orí ni ẹja ti ń bàjẹ́, tí orí ẹja bá ti bàjẹ́, kò sí àní-àní, gbogbo ẹja náà ló ti bàjẹ́. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé, bílíọ̀nù mẹ́fà àbọ̀ náírà ni wọ́n lò láti  tún ilé ìgbàfẹ́  kan ṣe ní ìpínlẹ̀ Ìṣèjọba Ọ̀yọ́ (old Ọ̀yọ́ Empire), ọ̀kan lára àwọn Ìpínlẹ̀ wa ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) èyí tí aríremáṣe nàìjíríà ń pè ní ìpínlẹ̀ Kwara, níbi tí Abdulrahman Abdulrazaq ti ń jẹ gàba.

Ìròyìn náà tẹ̀síwájú wípé, bílíọ̀nù mẹ́jọ àbọ̀ ni ìpinnu wọn láti ná sórí àtúnṣe ilé ìgbàfẹ́ yí, ṣùgbọ́n láàárín oṣù mẹ́ta tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí rẹ̀, bílíọ̀nù mẹ́fà àbọ̀ ti bàa lọ.

Ẹ wo bí àwọn akotileta olóṣèlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà ṣe ń ná owó wa, wọn ń ná òbítíbitì owó láti tún ilé ìgbàfẹ́ kan ṣe, aò bẹ̀yín ní iṣẹ́ tí ẹ ń jẹ́ lórí ilẹ̀ wa.

Ìdí tí ọ̀rọ̀ náà fi kàn wá náà ni Abdulrahman Abdulrazaq tó ń jẹ gàba lórí ilẹ̀ Yorùbá àti pé, owó tó ń ṣe básu-bàsu yí, ti àwa ọmọ Yorùbá ni, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kò kàn wá rárá. 

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè pé ó ti gba Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) fún wa.

Ṣùgbọ́n ìwọ Abdulrahman Abdulrazaq palẹ̀ ẹrù rẹ mọ́, kí o kọjá lọ sí ìlú aríremáṣe nàìjíríà yín lọ́hùn-ún, orí ìjókòó ọmọ Yorùbá lo wà yẹn. Olódùmarè ti ṣẹ́gun yín fún wa, kò sí ohun tí ẹnikẹ́ni lè ṣe sí í bíkòṣe pé kí ẹ gbà fún ọ̀gá yín.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024