Ẹ wo Seyi Makinde nínú àwòrán tí ẹ̀rọ ayélujára gbée níbi tí ó ti ń tàn ara rẹ̀ jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ ìgbéraga wípé, àwọn wà fún ara ìlú láti sún mọ́ ìjọba, ìyẹn ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, nítorí ó yẹ kí o rántí pé, ìwọ àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ tó kù, ẹ kìí ṣe gómìnà Orílè-èdè Olómìnira Tiwantiwa tí Yorùbá, kí àwọn ará ìlú máa wá bèèrè ohun tí wọ́n bá fẹ́ kí àwọn ṣe fún wọn.

Hee! Heee!!, ṣe ẹ wá ríi wípé, àyè ló gbá Tápà tí ó fi ń kọ́’lé Ìgunnu, ẹni tí a ò bá tà kí a fi ra àtùpà, tí ó wípé, òun di àjítannà wò ńkọ́, kínni?, lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá, àbí, ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ní ó lérò pé o wà?, Ṣeyi Makinde kúrò lórí ilẹ̀ wa kí o kọjá lọ sí ìlú aríremáṣe nàìjíríà yín lọ́ ùn

Kí ó tó di ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a kúrò nínú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà, kínní àwọn àṣeyọrí tí ìwọ Ṣeyi Makinde ṣe ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Gbogbo ìwà ọ̀daràn tí ìwọ àti àwọn tó kú ẹ ń hù ní orí ilẹ̀ wa ni ìjìyà wà fún. kò sí wàhálà, akèrèngbè ló máa júwe ibití a máa f’okùn sí lọ́run rẹ̀, tí ẹ bá mọ ọ̀ràn tí ẹ ń dá sí ara yín lọ́run ni, ńṣe ni ó yẹ kí gbogbo ẹ̀yin afipá jẹ gàba, rọra fi ìtìjú kó ẹrù yín kí ẹ sì ṣá kúrò lórí ilẹ̀ D.R.Y, nítorí pé, a ò mọ ohun tí ó ń yá àpọ́n yín lórí, tó fi’ṣu sí’ná, tó wá ń yá’ fe làù.

Ṣeyi Makinde, aò bẹ̀ ọ́ kí o ṣe ohunkóhun fún ará ìlú tó wà ní ìpínlè Ọ̀yọ́, ohunkóhun tí o bá fẹ́ ṣe lọ ṣé fún àwọn ará ìlú rẹ ní ìlú apanilẹ́kún jayé nàìjíríà tí o ń ṣe ìjọba lé lórí. Láìpẹ láìjìnà, ó máa ti’ka àbámọ̀ bọ’nu.

Yoruba has always been a country; now we've restored our Nationhood by the help of Olódùmarè