Nígbà gbogbo ní àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó rán ìyá aláàánú sí wa, màmá wa Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti gbà wá kúrò nínú ìyà àti òṣì. Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń fi dá’wa lójú wípé, ọmọ Yorùbá kankan kò tún j’ìyà mọ́, nítorí pé àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè gbé lé màmá lọ́wọ́, kún fún ìgbá’yé gbá’dùn lorísìírísìí,lára wọn náà ni ọjà ìgbàlódé.

Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), gbogbo àwọn ọjà wa ni a óò sọ di ti ìgbàlódé, iná mọ̀nàmọ́ná tí kò ní sẹ́’jú, omi ẹ̀rọ tí kò ní lọ,ààbò tó péyé fún àwọn olùra’jà àti olùta’jà, bẹ́ẹ̀ ni àyíká tó mọ́ tó sì dùn- ún wò.

Ìjọba D.R.Y yóò ríi dájú pé, gbogbo àwọn ohun tí ẹnu ń jẹ ní wọ́n ń pèsè ní àyíká tó mọ́ láti dènà àìsàn tó leè sẹ́yọ nípasẹ̀ ìdọ̀tí, nítorí pé, ìjọba tó fẹ́ràn ará ìlú tó sì fi tiwọn ṣe àkọ́kọ́ ni ìjọba D.R.Y 

Nítorí náà, a kí gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) pé a kú oríire, bẹ́ẹ̀ ni a kí màmá wa Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ẹ seun lọ́pọ̀lọpọ̀,ìran Yorùbá mọ̀ọ́ lóore.