Ọmọ-Àlè, Agbésùnmọ̀mí Jídé Sanwó-Olú, àti òfégè ìjọba ajẹgàba tó fi’pá dúró sorí ilẹ̀ wa, ní ìpínlẹ̀ Èkó, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ti túbọ̀ ntẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ibi tí àwọn amúnisìn fi rán an: ìwà-ìkà, ìwà-ìpànìyàn, ìpanisára, àìbìkítà ojúkorojú: àìláanú ọmọ ènìyàn, lórí ilẹ̀ tí kìí ṣe ilẹ̀ aríremáse Nàìjíríà tí Sanwó-Olú ń ṣiṣẹ́ fún. 

Ayétòrò, Èbúté Mẹ́ta, agbègbè Yaba, ni ó ti ṣẹlẹ̀ tí òfegè ajẹgàba ìjọba Sanwó-Olú rán àwọn ológun agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà láti ṣí àwọn ènìyàn ní’dí kúrò nínú ilé wọn, tí wọ́n dà wọ́n síta, t’ẹrù-t’ẹrù, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì f’arapa, látàrí bí àwọn ológun ṣe kó ìpalára bá wọn, tí wọ́n wá di ẹni t’ó kó gbogbo ohun ìní wọn sí ojú títì, b’ojò rọ̀, b’oòrùn ràn, orí wọn àti gbogbo ohun-ìní wọn l’ó nf’ara gbàá! Háà! Sanwó-Olú, o ṣ’èyí tán!

Gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbà (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), ẹ jẹ́ kí a wá gbọ́ o! Ní’bi tí a dé yí, kí ẹnikẹ́ni máṣe  kàánú fún Sanwó-Olú nígbàtí ìjìyà rẹ̀ bá dé. 

Sanwó-Olú, a gbọ́ pé ó ti ṣe ẹ́ bákan rí nínú ọpọlọ; a ò fi yọ̀ ẹ́, ṣùgbọ́n a fẹ́ kóo mọ̀ pé àwọn tó rán ọ ní’ṣẹ́ wèrè tí o njẹ́ yí kò ní le gbà ẹ́ sí’lẹ̀ nígbàtí ìjìyà rẹ bá bẹ̀rẹ̀; agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà t’ó fi ipá fi ẹ́ sórí oyè, agbára òun pàápàá kò ní ka, kò wá sí èyí t’ó kàn wá pẹ̀lú àìpé ọpọlọ tí o nṣe àfihàn rẹ̀ yí o! Ìyà t’ó máa jẹ ọ́, wàá ní kìl’o wá’yé fún!

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates 20/09/2024

Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ẹ̀yin tó kù, tí ẹ pe’ra yín ní gómìnà, tí ẹ fi ipá dúró lórí ilẹ̀ D.R.Y – Ṣèyí Mákindé, Adémọ́lá Adélékè, Dàpọ̀ Abíọ́dún, Abdulrahman Abdulrazaq, Ododo, Ayédatiwa, Oyèbánjí, là ń bá wí o!

Ọjọ́ ìdájọ́ yín ti dé tán; Èdùmàrè tí gbé ogun-ọ̀run dìde kọ’jú ìjà sí yín: a ké yín kúrò, ti gbòǹgbò ti gbòǹgbò ní’bi tí ẹ fi ipá dúró sí ní Orílẹ̀-Èdè D.R.Y, a ò sì níí rí yín mọ́, láíláí: ọ̀run ti kọ̀ yín; ìpòrúùruù dé bá yín; ọkàn yín dàrú; ẹ gbọ́ ìró-ogun tí ó nbọ̀ wá bá yín; ẹ̀rù bà yín, ẹ si fi ìbẹ̀rù-bojo sá kúrò báyi, ní ilé-iṣẹ́ àti ibi gbogbo tí ó jẹ́ ti ìjọba Orílẹ̀-Èdè Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y. 

Àwa ọmọ Yorùbá, àánú ṣe’ni nígbàtí a rí fọ́nrán tí ó fi ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn hàn lojú títì, pẹ̀lú gbogbo ohun ìní wọn l’ayé l’ọrun: àfi bíi ọjà, láì kìí ṣe ọjà. Ọjọ́-ìdájọ́ dé, fún ajẹgàba Nàìjíríà lórí ilẹ̀ D.R.Y.