Orílẹ̀-èdè Russia ti sọ pé, ní báyi, kò ní sí àǹfààní mọ́ fún àwọn àtọ̀únrìnwá tí orílẹ̀-èdè wọn fi àyè gba pàṣípààrọ̀ ìṣẹ̀dá-ọkùnrin-àti-obìnrin, láti ṣe alágbàtọ́ fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè òun.

Àwọn orílẹ̀-èdè kan wà tí ó jẹ́ pé ẹni tí a bí ní ọkùnrin, tí ó bá sọ pé ó wu òun láti jẹ́ obìnrin, wọ́n á ṣe iṣẹ́ abẹ fun láti di obìnrin; bákan náà lórí fún obìnrin t’ó bá fẹ́ yí ara rẹ̀ sí ọkùnrin.

Ohun tí Russia wá nsọ báyi ni pé àjòjì tí o ngbé ní ìlú Russia, ṣùgbọ́n tí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀ gan-an tí òún ti wá, fi àyè gba ìyípadà sí ìṣẹ̀dá kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣe iṣẹ́ tàbí wà ní ipò alágbàtọ́ fún ọmọ t’ó bá jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Russia!

Èyí túmọ̀ sí pé Russia kórira kí ènìyàn sọ pé òun fẹ́ yí ìṣẹ̀dá-òun padà. Nítorí náà, wọn ò gbà kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fi àyè gba ìyípadà sí ìṣẹ̀dá ṣe alágbàtọ́ fún ọmọ Russia mọ́!

Ṣebí tí àyè bá wà fún wọn láti ṣe alágbàtọ́ ni wọ́n lè ní àǹfààní láti kọ́ àwọn ọmọ Russia ní irú ẹ̀kọ́ burúkú yìí.

Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), àpẹrẹ ni’yí pé orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni kò gbọdọ̀ gba ohun tí kò bá wọn lára mu, ẹni ìyóòwù k’ó ṣe agbátẹrù ohun náà.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates 19/09/2024