Àwọn alárùn-ọpọlọ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti ṣe adìyẹ-GMO, èyí tí kò ní ìyẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé àwọn ò ní tàá ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Ilẹ̀ tí kò sí òtútù ni wọ́n ń gbèrò láti tàá sí; wọ́n tilẹ̀ dárúkọ ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ní pàtó!

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe máa ń sọ, ṣé kò kúkú kàn wá tí aríremáṣe nàìjíríà bá fẹ́ po sódà mu, ṣùgbọ́n jíjẹgàba tí wọ́n ń jẹgàba lórí ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) jẹ́ kí wàhálà wọn máa ṣe àkóbá fún àwọn èèyàn wa, nítorí púpọ̀ àwọn èèyàn wa ni kò tíì gbọ́ nípa ayédèrú oúnjẹ yí: wọ́n ní kí ilẹ̀ ó tó pa òṣìkà,ohun rere á ti bàjẹ́!

A ò fẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó jẹ́ pé àwọn èèyàn wa á máa rò pé àgbéjáde ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ni, bẹ́ẹ̀ sì ní ewu pọ̀ níbẹ̀.

Adìyẹ tí kò ní ìyẹ́ kìí ṣe ojúlówó adìyẹ tó yẹ fún ọmọ ènìyàn láti jẹ, Adìyẹ GMO ayédèrú nìyẹn.

Ó ní iṣẹ́ ibi tí wọ́n ti ṣe sí ẹ̀dá rẹ̀ kó tó di pé kò ní ìyẹ́! Àwa ọmọ Yorùbá, ẹ jẹ́ k’á máa fura.

Gẹ́gẹ́bí ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá, tí a bá rí adìyẹ lát’òkè-dé’lẹ̀ tí ó jáde nínú ẹyin tí kò ní ìyẹ́ kankan, tí ó sì dàgbà bẹ́ẹ̀, a óò ti mọ̀ wípé ayédèrú adìyẹ ni, ó ní ń kan tí àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ òyìnbó máa ń pè ní RNA àti m-RNA nínú ara, bẹ́ẹ̀ náà ni ó ní nkan t’ó ń jẹ́ nano-particles.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates 19/09/2024

Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n máa ń lò láti dènà bí ó ṣe yẹ kí ara ènìyàn, ẹranko tàbí ohun-ọ̀gbìn ó ṣiṣẹ́, tí wọ́n a wá yi sí ayédèrú àti èyí tí ó leè pa ènìyàn lára: nítorí náà kìí ṣe pé a kàn nkígbe lásán, sáyẹ́nsì yé àwa ọmọ Yorùbá náà dáadáa, nítórí náà ni ó fi ká wa lára tí a fi ń pariwo sí’ta pé kí àwọn ènìyàn wa ní ilẹ̀ Yorùbá máṣe gba ìgbàkugbà kankan láti ọwọ́ apanilẹ́kún jayé Nàìjíríà.

Ìgbà díẹ̀ báyi ló kù, Olódùmarè á ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àṣepé rír’ẹyìn àwọn agbésùnmọ̀mí wọ̀nyí kúrò lórí ilẹ̀ wa. Wọ́n fẹ́, wọ́n kọ̀.

Ìwọ Ṣèyí Mákindé, Sanwó-Olú; Oyèbanjí, Ayédatiwa, Abdulrahman Abdulrazaq, Ododo, Adémọ́lá Adélékè; àti Dàpọ̀ Abíọ́dún, ẹ̀yin ọmọ-Àlè Yorùbá wọ̀nyí, a tún nsọ fún yín: ẹ kó’ra yín kúrò nínú ilé-iṣẹ́ Ìjọba wa ní ilẹ̀ Yorùbá! Ìkìlọ̀ ni o, ẹ máa tó tẹ́: ìbá sàn fún un yín kí ẹ tètè kúrò ní ilé-iṣẹ́ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) báyi: àmọ́ ṣá, ọjọ́ ìtìjú yín kù sí dẹ̀dẹ̀.