ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI
OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.
ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ
Ẹni tó máa tẹ́ ni ìlú Agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà: kò níí ṣàì máa kọjá àyè rẹ̀ ní ìgbà dé ìgbà. Tó bá jẹ́ pé wọn ò mẹ́nu ba Yorùbá tí wọn ò sì fi tipá dúró sórí ilẹ̀ wa ni, kò sí èyí tí ó kàn wá níbẹ̀.
Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ sọ pé ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà fẹ́ gbé oríkò ẹ̀jẹ̀-gbígbà-sílẹ̀, kalẹ̀, káàkiri ohun tí wọ́n pè ní ọ̀rìn-lé-lẹ́ẹdẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́fà ìjọba ìbílẹ̀ wọn; a sì mọ̀ pé iye tí àwọn ìjọba ìbílẹ̀ wọn jẹ́, kí àwa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ó tó kúrò lára wọn nìyẹn, a ò sì gbọ́ pé wọ́n tún ti ní ìjọba-ìbílẹ̀ síi lẹ́yìn ti àwa D.R.Y ti kúrò ní Nàìjíría – èyí túmọ̀ sí pé ẹ ṣì ń ka ilẹ̀ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwatiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) mọ́ ara yín,apanilẹ́kún jayé Nàìjíríà, lọ ṣọ́ ara rẹ̀ gidi gan-an, àbí kíni gbogbo rádaràda wọ̀nyí?
Ìlú ajẹgàba Nàìjíríà, gbọ́, kí o tùn tún-un gbọ́: ibi tí ẹ̀ ń pè ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Ọ̀yọ́, Èkìtì, Ọ̀ṣun, Oǹdó, Ògùn, Kwara àti apá Kogí tí ó wà ní Ìwọ̀-Oòrùn Odò Ọya, kì í ṣe ara ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà mọ́ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbàá Ọdún ó lé méjìlélógún; bẹ́ẹ̀ sì ni gbogbo ibi tí a dárúkọ wọ̀nyí lóni àti títí ayé, jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), a sì ti di Orílẹ̀-Èdè aṣèjọba-ara-ẹni láti ọjọ́ kéjìlá, oṣù Igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún, nígbàtí a ṣe Ìpolongo Ìṣèjọba-Ara-Ẹni, tí a sì tún ṣe Ìbúra-Wọlé fún olórí ìjọba-Adelé wa, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, ẹni tí àgbáyé ti mọ̀ gẹ́gẹ́bí Olórí Ìjọba-Adelé Democratic Republic of the Yoruba(D.R.Y), ti aríremáse Nàìjíríà náà sì mọ̀, ṣùgbọ́n tí ó ń ṣe orí kunkun tí ó sì ń fi agídí jẹ gàba lórí ilẹ̀ D.R.Y.
Agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà afipá jẹgàba jádé kúrò lórí ilẹ̀ D.R.Y, má sì ka D.R.Y mọ́ ara rẹ mọ́! Ṣọ́ ara rẹ gidi.
Àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti D.R.Y, ẹ jẹ́ kí a rántí pé a ò sí lára Nàìjíríà mọ́; ẹ má ṣe lọ bá wọn kó’pa nínú ètò ẹ̀jẹ̀-gbígbà-sílẹ̀ kankan, lábẹ́ apaná ògo Nàìjírà, ní orí-ilẹ̀ D.R.Y, nítorí pé D.R.Y kì í ṣe ara ìlú ajẹgàba Nàìjíríà mọ́, kò ò sì ní àṣẹ kankan ní ilẹ̀ D.R.Y. Agbésùnmọ̀mí ni Nàìjíríà jẹ́ ní D.R.Y, yóò sì fi ìtìjú jádé kúrò ní orí ilẹ̀ D.R.Y.