Ọmọkùnrin kan ẹni ọdún mẹ́tàlélógún tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adelẹyẹ Ayọmide ṣe’kúpa akẹ́kọ̀ọ́ fásítì iṣẹ́ ọ̀gbìn ti ìlú Abẹ́òkúta ní ìpínlẹ̀ Ògùn, Idowu Christiana tí ó wà ní ipele kẹta ni ilé ẹ̀kọ́ náà.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́ nínú ìròyìn náà, àwọn ajínigbé ló jí akẹ́kọ̀ọ́ ‘bìnrin Idowu Christiana gbé, ní òpópónà Ìkòròdú sí Yábà ní ìpínlẹ̀ Èkó ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù Ògún ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí àwọn ajínigbé ọ̀hún sì béèrè fún mílíọ̀nù mẹ́ta náírà fún ìtúsílẹ̀ rẹ̀, àwọn ẹbí rẹ̀ bẹ̀bẹ̀, wọ́n sì gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ó lé àádọ́ta, ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti tú akẹ́kọ̀ọ́ ‘bìnrin náà sílẹ̀, wọ́n sì ṣe ikú paá lẹ́hin tí wọ́n gba owó náà.
Ìròyìn yí báni nínújẹ́ púpọ̀, ohun tí ó mú ìṣẹ̀lẹ̀ yí kàn wá ní pé ìpínlẹ̀ Ògùn àti Èkó tí ọ̀rọ̀ náà báwí jẹ̀ méjì lára àwọn ìpínlẹ̀ wa ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) tí agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà nfi ipá jẹ gàba lé lórí títí di àkókò yí. Àtúnbọ̀tán ìjẹgàba ìlú búburú agbésùmọ̀mí Nàìjíríà yìí ló fa ìwàkiwà àti orúkọ ẹ̀tẹ́ sínú ayé ọmọ Yorùbá.
Wọ́n ti sọ ọmọ Yorùbá di ajínigbé àti apànìyàn, kí ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún ti di agbenipa, ó burú jáì! Ṣùgbọ́n, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí ó bá wa tún orí àwa ọmọ Yorùbá ṣe, a ti kúrò lára ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún, a sì ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí ìjọba adelé wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún, a sì tí di orílẹ̀ Èdè aṣèjọba ara ẹni. Olè àti akótilétà agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa.
Màmá wa, Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla tí Olódùmarè lò fún àṣeyọrí òmìnira wá yìí tí sọ fún wa pé ọ̀rọ̀ ìjínigbé àti ìpànìyàn ní àwọn ìjọba Adelé wa yíò rí sí nípa ètò ààbò tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ dáradára, ètò ọrọ̀ ajé wa yíò lágbára tó fún ìṣe rere ará ìlú, àwọn ọ̀dọ́ wa máa rí ògo wọn lò dáradára.
Ní àfikún ọ̀rọ̀ màmá wa, àlàkalẹ̀ ìṣèjọba D.R.Y fún àwọn ọ̀dọ́ Yorùbá ní ayé ìṣerere àti ọjọ́ ọ̀la tó dájú, nítorínáà, àyè ìwà ọ̀daràn kò ní ṣí sílẹ̀ fún ọ̀dọ́ tàbí àgbà kankan.
Àwọn ògo wa yìí á bẹ̀rẹ̀ síí tàn ní kété tí a bá ti lé àwọn àjẹgaba agbésùnmọ̀mí Naijiria kúrò lórí ilẹ̀ wa ní kò pẹ́, kò pẹ́ yii.