Bẹ́ẹ̀ ni o! ní ilẹ̀ Áfríkà, ṣe ni àwọn ẹrú tún ń gbè sí ẹ̀yìn àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú. Ọ̀rọ̀ kan tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára ló tọ́’ka sí gbólóhùn yí, tí ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, nípa ọ̀rọ̀ tí òyìnbó amúnisìn kan ti sọ sẹ́yìn, ní ẹgbàá ọdún ó dín ọgọ́jọ ó lé márun, ní ọjọ́ kéjì, oṣù Èrèlé ọdún náà ni.
Ọkùnrin òyìnbó tí ó sọ ọ̀rọ̀ yí ni wọ́n ń pè ní Lord Macaulay, tí ó sì ń bá àwọn ilé ìgbìmọ̀ ìjọba ìlú Gẹ̀ẹ́sì, ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nígbà náà.
Gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí Macaulay sọ, fihàn gbangba pé, ìjíròrò lórí bí àwọn ṣe lè borí àwọn ọmọ Áfríkà, ni wọ́n nṣe lọ́wọ́ nígbàtí Macaulay sọ àfojúsùn tirẹ̀ fún wọn, lórí bí ìlú Gẹ̀ẹ́sì ṣe lè borí Áfríkà.
Ó sọ fún wọn pé òun ti rin ìrìn-àjò káàkiri gbogbo ilẹ̀ Áfríkà, òun ò sì rí ẹyọ ẹnikan tí ó jẹ́ alágbé (atọrọ-jẹ), tàbí tí ó jẹ́ olè! Ó ní ọ̀rọ̀ tí òun kò rí rí, ni òun rí káàkiri ilẹ̀ aláwọ̀dúdú. Bẹ́ẹ̀ ni ó tún sọ fún wọn pé, àwọn ọmọ Áfríkà jẹ́ olóotọ,ọmọlúwàbí àti oní’wà-rere tí òun kò rí irú ìwà-rere bẹ́ẹ̀ rí!
Èyí túmọ̀ sí pé ọ̀dọ̀ àwa aláwọ̀ dúdú ni àwọn òyìnbó ti kọ́kọ́ ri orílẹ̀-èdè tí kò sí alágbe tàbí olè ọ̀dọ̀ wa ni wọ́n ti ri pé èèyàn oní ìwà rere. Ó túmọ̀ sí pé, kí òyìnbó ó tó wá sí Áfríkà, wọn ò kìí ṣe ọlọ́rọ̀; bẹ́ẹ̀ náà ni kò sí ìwà-rere, ìwà olóotọ́, tàbí ìwà ọmọlúwàbí ní ìlú wọn. Ṣùgbọ́n tí ìlú àwọn òyìnbó jẹ́ ìlú òtòṣì, ìlú tí alágbe pọ̀ sí, tí olè sì wà gidi. Ọrọ̀ tí Macaulay rí ní ilẹ̀ wa ní Áfríkà yàá lẹ́nu tí ó sì jẹ́ ọrọ̀ tí ó f’ara hàn ní gbogbo ìlú ni, kì ṣe pé àwọn kan péré ni ó ní ọrọ̀.
Macaulay wá tún sọ pé àwọn aláwọ̀dúdú, èèyàn jàǹkàn ni wọ́n, wọn ò kìí ṣe ẹni yẹpẹrẹ rárá! Ó ní kò sí bí àwọn ṣe lè bórí tàbí ṣẹ́gun wọn, àyàfi tí àwọn bá gba oun tí Áfríkà fi jẹ́ alágbara, ọlọ́rọ̀, ológo, ẹni iyì, oníwà-rere, olóotọ́ àti ọmọlúàbí tí wọ́n jẹ́, tí àwọn bá ṣẹ́ Áfríkà ní eegun-ẹ̀yìn. Kí wá ni eegun-ẹ̀yìn Áfríkà ó? Ó sọ pé ohun-àjogúnbá inú-ẹ̀mí wọn gẹ́gẹ́bí aláwọ̀dúdú, àti ohun-àjogúnbá àṣà wọn ni eégún ẹ̀yìn wọn.
Ó ní láti leè gba àwọn nkan wọ̀nyí, òun dáa l’abá kí àwọn ó yí Áfríkà lọ́kàn padà, láti má tẹ̀lé ẹ̀kọ́ ti àwọn babanlá wọn, kí àwọn gbé ẹ̀kọ́ ti òyìnbó lé wọn lọ́wọ́, kí Áfríkà sì ma rò pé ti òyìnbó ló dára ju! Ó ní tí àwọn bá ti lè ṣe eléyi, ó tán nìyẹn, wọ́n ò ní leè tako ìmúnisì.
Aláwọ̀dúdú kan tí ó sọ̀rọ̀ lórí ń kan tí Macaulay sọ yí, lórí ẹ̀rọ ayélujára láìpẹ́ yí, sọ pé ó hàn nínú ọ̀rọ̀ Macaulay pé, ìwà-ìbàjẹ́ tí ó gbilẹ̀ ní Áfríkà loní, jẹ́ àbájáde ìwà-ìkà tí àwọn òyìnbó yí ṣe, èyí tí wọ́n mọ̀ọ́-mọ̀ pa àṣà àti ìṣe àdáyébá wa run! Ó ní àwọn tí ó sì ṣe iṣẹ́ yí ni àwọn òyìnbó amúnisìn tí wọ́n yàn wá sí ilẹ̀ wá láti jẹ́ alákóso nígbà náà: àwọn gómìnà-àgbà, ajẹ́lẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọkùnrin aláwọ̀dúdú yí sọ pé gbogbo òtítọ́ wọ̀nyí ni a mọ̀, ṣùgbọ́n kò sí ìpinnu àtinúwá láàárín àwọn tí ó pe’ra wọn ní olórí ní Áfríkà loní láti ṣe àtúnṣe sí ń kan wọ̀nyí. Ó ní ìdí ni pé àwọn tí ó pe’ra wọn ní “olórí” ọ̀ún gan-an-gan ní wọ́n njẹrà nínú ìwà-ìbàjẹ́ ọ̀ún, tí wọn ò sì fẹ́ kó tán nílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àá máa sọ pé “ó wà lọ́wọ́ Ọlọ́run”! Bẹ́ẹ̀ ni àwọn òyìnbó ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, ó mà ṣe o!
Àmọ́ ṣá o! k’á sọ̀rọ̀ sí’bi tí ọ̀rọ̀ wà, ti àwa Yorùbá yàtọ̀ o! Ọjọ́ ológo ni ọjọ́ náà lọ́hùn-ún, ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún, tí Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá Ìran Yorùbá, b’ojú wò wá ṣel’oore, nípasẹ̀ Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, nígbà tí gbogbo àgbáyé gbọ́ ìkéde ÒMÌNIRA àwa Yorùbá kúrò lara agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà! Kìí ṣe èyí nìkan ìsèjọba ara ẹni wa tún ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún.
Olódùmarè ti gbà wá là; ó wá ku kí a máa fi ojú méjèèjì rìn nínú ìgbàlà náà: a ò gbọ́dọ̀ ṣàì mọ rírì ẹni tí Ọlọ́run wa lò gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà fún wa: Màmá wa, MOA; ìkẹ́ àti Ìgẹ̀ Olódùmarè kí ó wà pẹ̀lú wọn títí lái! A ò sì gbọ́dọ̀ yí ẹsẹ̀ wa kúrò nínú Àlàkalẹ̀ tí Èdùmarè ti ọwọ́ Ìyá wa gbé fún Ìran Yorùbá. Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), kí a máṣe yà sí ọ̀tún tàbí òsì; kí á sì fi Àlàkalẹ̀ náà kọ́ àrọ́mọdọ́mọ wa títí ayé.