Bí a ṣe ń gé wọn lọ́wọ́ ni wọ́n tún ń bọ òrùka, ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ń pà’ṣẹ àfíkún owó ilé gbígbé fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y.), bẹẹni wọ́n sì mọ̀ pé D.R.Y kìí ṣe ara apaná ògo Nàìjíríà mọ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun.

Ṣà dédé ni a rí lórí ayélujára pé Sanwo-Olu tó ńfagídí jẹ gàba lórí ìpínlẹ̀ Èkó, ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ wa ni Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), tí agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà nfi ipá jẹ gàba lórí rẹ̀, gbé ìròyìn kan jáde pé wọn fi owó kún owó ilé-ìgbé fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé ìjọba ìpínlẹ̀ náà, ó ní kí akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan máa san ẹgbẹ̀rún lọ́ná ọgọ́run naira, ti o jẹ́ owó ìlú wọn, dípò ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì tí wọ́n ń san tẹ́lẹ̀.

Democratic Republic of the Yorùbá daily newspaper

Ẹgbọ́ ná, irú àìfinipeni àìfì ènìyàn p’ènìyàn wo ni èyí? Lẹ́yìn tí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti di orílẹ̀ èdè aṣèjọba ara ẹni ní ọjọ́ kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún tí a ṣe ìbúra wọlé fún olórí Adelé wa, lọ́jọ́ yìí náà ni Olórí Adelè wa, Bàbá wa Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọ́rẹ́ ti pàṣẹ pé kí gbogbo ilẹ́-ẹ̀kọ́ wà ní títì pa ní gbogbo ìpínlẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y).

Tani ó wa bẹ arúfin Sanwo-Olu tó njẹ gàba lórí ìpínlẹ̀ Èkó láti máa bá wa ṣètò ẹ̀kọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ tí ìjọba wa ti tì pa? Sanwo-Olu o ṣì máa f’ojú ba ilé ẹjọ́ àgbáyé fún àwọn ìwà ọ̀daràn rẹ ní ìpínlẹ̀ Èkó.

K’ádúpẹ́ lọwọ́ Elédùmarè tí ó gbé Màmá wa, Ìyá Àfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá dìde latí gbà wá kúrò lọ́wọ́ apànìyàn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, bí ò jẹ́ bẹ́ẹ̀, à bá má nì ìrètí ìdánilójú ẹ̀kọ́ tó yè kooro fún ọmọ Aládé, nítorí búburú ni èrò àwọn ìkà yí sí wa.

Màmá wa ti fi dá wa lójú pé gẹ́gẹ́bí àlàkalẹ̀ ètò ìṣèjobà tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́ fún ìgbáyé gbádùn àwa ọmọ Yorùbá, ní kété tí àwọ́n Adelé wa bá wọ oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba wa, ẹ̀kọ́ ọ́fẹ́ tó yanrantí láti ilé ìwé alákọ̀ọ́ bẹ̀rẹ̀ títí dé ìkẹ́kọ́ gboyé ìpele àkọ́kọ́ ní Fásitì pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun amáyédẹrùn ni a o ó jẹ ìgbádún rẹ̀ ní Orílẹ̀-èdè wa.

Èwo laò ní yọ́ sí, nígbàtí Olódúmárè ti ṣe àánú fún wa. Nítorínáà, gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People I.Y.P) níláti dídé, kí a f’ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹlú ìjọba Adelé wá nítorí a ní ìdánilójú pé láì pẹ́ láì jìnnà yí ọ̀rọ̀ àwọn agbésúmọ̀mí àti ajẹgàba yóò di àfìsẹ́yìn tí eégún ń fi aṣọ, ní àsẹ Èdùmàrè.