Ní kété tí Èdùmàrè bá ti ṣe àfihàn lílé àwọn ìjọba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà kúrò lórí ilẹ̀ wa, tí Ìjọba-Adelé wa ti wọlé sí’nú gbogbo oríkò ilé-iṣẹ́ Ìjọba káàkiri ìpínlẹ̀ méjèèje, ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ tààrà, lọ́gán ni àṣírí máa tú nípa oríṣiríṣi irọ́ tí òyìnbó-amúnisìn tí Ọlọ́run ti gbà wá kúrò lọ́wọ́ wọn máa ń pa.
Ẹ jẹ́ mọ̀ pé àjọ kan wà ní ìlú Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n ń pèé ní DFID, ìyẹn ní ẹ̀ka ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó nrí sí ìdàgbàsókè káàkiri àgbáyé!
Ẹ jọ̀ọ́, níbo ni Gẹ̀ẹ́sì ti rí nkan tí wọn fi nrí sí “ìdàgbàsókè” káàkiri àgbáyé? Àlùmọ́nì wo l’ó wà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì? A ò fi yọ̀ wọ́n, àànú l’a rí gbà, ṣùgbọ́n a nsọ òótọ́ ọ̀rọ̀ ni.
Nkan tí wọ́n bá ti jí ní Áfríkà, náà ni wọ́n á mú kékeré lára ẹ̀ padà, tí wọ́n á wá sọ pé àwọn ṣe ìrànlọ́wọ́ fún Áfríkà!
Èyí tí a wá tún rí gbọ́ báyìí ni ìròyìn kan t’ó fi aṣekú-pa’ni, Ìránṣẹ́-Àṣìtáánì Bill Gates hàn ní’bi tó ti nsọ pé, òun ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú DFID ní oríṣiríṣi ọ̀nà.
Lára rẹ̀ ni iṣẹ́ tí àwọn ńṣe nípa ẹran-ọ̀sìn. Àwọn nṣe ìrànlọ́wọ́ fún ẹran-ọ̀sìn láti yè, yálà nípa abẹ́rẹ́-àjẹsára (àfi abẹ́rẹ́-àjẹsára yíi ṣá!!), tàbí yíyí ìṣẹ̀dá wọn sí èyí tí ó dára! HÀÀ!! Bill Gates, lẹ́nu ẹ! Èyí túmọ̀ sí pé, bí Ọlọ́run ṣe dá wọn kò dára tó, àbí?
Ìwọ lo fẹ́ tún wọn dá?! Ó mà ṣe o! Àánú ẹ kò ṣe wá, àánú àwọn Orílẹ̀-èdè Áfríkà tó ń tẹ̀lé ẹ, gọ̀ṣú gọ̀ṣú, ló nṣe wá! Kò sì tún ṣe wá náà ṣùgbọ́n, ní ti àwa ọmọ-Aladé, Ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ojú wa ti là!
Olódùmarè ti rán Olùgbàlà sí wa, Ìyá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, wọ́n sì ti jẹ́ kí á mọ̀ pé, ní orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y, ohun gbogbo tí a máa lò, tí a máa jẹ, tí a máa ṣe, máa jẹ́ ohun àbáláyé, kì í ṣe àtúndá-ọmọ-ènìyàn!
Bill Gates ní Iṣẹ́ òun àti DFID, á jẹ́ kí àwọn ẹran-ọ̀sìn náà ó tún lè bí’mọ síi ! Ó ní iṣẹ́ náà sì nmú àyípadà tó pọ̀ wá.Ó wá sọ pé òun ti lọ sí Orílẹ̀-èdè Ethiopia, òun ti rí bí àwọn adìyẹ ti ńyé ẹyin tó pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, tí oúnjẹ tí wọ́n njẹ dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, tí àwọn t’ó ni adìyẹ sì tún nrí owó díẹ̀ díẹ̀ l’orí wọn.
Ó ní ìlú Edinburgh ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni ibi tí èyí tí ó pọ̀ nínú iṣẹ́ ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ irúfẹ́-èyí, l’agbáyé, ti nwá’yé.
Ó wá sọ pé nítorí bẹ́ẹ̀ ni ilé-iṣẹ́ òun, Gates Foundation, pẹ̀lú DFID ṣe nṣe ìrànlọ́wọ́ owó fún àwọn “onímọ̀-ìjìnlẹ̀” ní’bẹ̀!
Àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, tí a bá ti gbọ́ tí wọ́n npe àwọn kan ní “onímọ̀-ìjìnlẹ̀” ní ìlú-òyìnbó, kí á funra!
Àwọn tí Bill Gates nṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú, látí yí ẹ̀dá ọmọ ènìyàn padà, àbí ṣe’kú pa èèyàn lagbáyé, pàápàá aláwọ̀dúdú, àti àwọn bíi ti Edinburg yí, tí Bill Gates sọ pé òun àti DFID nfún lówó, kí wọ́n le yí ìṣẹ̀dá àwọn ẹranko padà, àwọn ni “onímọ̀-ìjìnlẹ̀” t’ó nsọ o! Kí a má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ó fi gbólóhùn “imọ̀-ìjìnlẹ̀” kó wa l’omi ọbẹ̀ jẹ!
Tani ó mọ̀ pé irú iṣẹ́ ibi báyi ni DFID nṣe, tí wọ́n sì sọ pé àwọn wà fún ìdàgbà-s’okè káákiri àgbáyé!
Ìgbàkúgbà tí àwọn òyìnbó bá ti sọ pé àwọn nṣe ìrànwọ́ fún Afríkà, kí a funra ! Ìfẹ́ tí a ní fún òròmọdìyẹ ni òyìnbó ní fún aláwọ̀dúdú. Ìyá wa, Ìránṣẹ́ Olódùmarè, sì ti sọ fún wa pé a ò ní ṣe ẹrú amúnisìn mọ́!