A ri lórí fọ́nrán kan irú ipa tí àwọn Amẹ́ríkà pẹ̀lú òyìnbó amúnisìn nkó nínú gbígbé àwọn ìkànnì tí ó jẹ́ tí aláwọ̀ dúdú wálẹ̀. Ìròyìn tí a gbọ́ nínú fọ́nrán náà jẹ́ ká mọ̀ pé ìkànnì aláwọ̀ dúdú kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ African Stream ti YouTube gbé wálẹ̀, jẹ́ iṣẹ ọwọ́ àwọn amúnisìn wọ̀nyí.
Wọ́n ní ìròyìn tó njáde lórí ìkànnì yí jẹ́ ìròyìn tí ìjọba Russia gbé jáde fún wọn lati máa tẹ̀ jáde àti pé ìjọba Russia ló nfi owó ṣe àtìlẹ́yìn fún wọn. Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ ràrá.
Òtítọ́ inú ọ̀rọ̀ yí ni pé ìkànnì African Stream ńgbé ìròyìn nípa àṣà àti ohun tó jẹ́ ti aláwọ̀ dúdú lápapọ̀ jáde.
Àwọn agbóhùn-sáfẹ́fẹ́ wọn ní ìlú àwọn amúnisìn aláwọ̀ funfun yí, pàápàá jùlọ ní Améríkà, ní oore ọ̀fẹ́ láti gbé ìròyìn tí wọ́n bá fẹ́ jáde, bíótilẹ̀ jẹ́ irọ́, wọn kìí gbé wọ́n wálẹ̀, bí ìròyìn náà bá ṣáà tí gbè lẹ́yìn Améríkà tàbí àwọn òyìnbó amùnisìn t’ókù.
A gbọ nínú fọ́nrán náà pé, bí ó tí hàn gbangba tó, pẹ̀lú ẹ̀rí pé àwọn ìkànnì bíi BBC, CNN, Sky News ma ngbé ìròyìn èké jáde, síbẹ àwọn amúnisìn yí kò gbé wọn wálẹ̀, ṣùgbọ́n ìkànnì African Stream tí wọn kò ní ẹ̀rí fún ẹ̀sùn kankan ni àwọ́n òyìnbó yí gbé wàlẹ̀.
Ohun tó wá burú jù ni bí gbogbo agbóhùn-sáfẹ́fẹ̀ ní ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú kò ṣe dìde láti fọhùn lòdì sí ìwà àìṣedéédé àwọn amúnisìn yí, tí gbogbo olórí ìjọba ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú náà sí pa ẹnu mọ́.
Àwọn aláwọ̀ funfun yìí, pàápàá jùlọ Améríkà, tí fi gbogbo orílẹ̀-èdè aláwọ̀-dúdú sí ipò tí wọn kò lẹ́nu lórí ètò òṣèlú, ọrọ̀ ajé àti ààbò wọn. Báyìí wọ́n tí bọ́ sórí ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ lati sọ Áfríkà di aláìlèronú fúnra rẹ̀, bí wọn tí ṣe fún àwọn aláwọ̀ dúdú Améríkà.
Ète amúnisìn ní láti lo ẹ̀rọ ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ lati darí èrò inú àwa Áfríkà pẹ̀lú irọ́ àti ẹ̀tànjẹ, kí a lè wà lábẹ́ ìsìnrú wọn, kí wọ́n lè máa darí ìjọba wa àti làti máa kó àwọn ohun àlùmọ́nì wa. Ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ jẹ́ irinṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì tí ó sì ní agbára.
Áfríkà kò ní àwọn ìkànnì báyìí lọ́pọ̀lọpọ̀, àwọn amúnisìn yí dẹ̀ máa ńfi ẹ̀rọ tọ ipasẹ̀ gbogbo ìkànnì Áfríkà nítorí wọn ò fẹ́ kí aṣírí ìwà kíkó àlùmọ̀nì wa àti ṣíse’kú pa àwọn olórí ìjọba tí ó dára ní Áfríkà hàn síta. Ìkànnì aláwọ̀ dúdú tí ó bá sọ̀rọ̀ nípa ìwà búburú wọn, ṣe ní wọ́n á gbe wálẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀sùn tí kò ní ẹ̀rí kankan láti bo àṣírí ara wọn.
Àwọn òyìnbó yí ti sọ ara wọn di ọ̀gá ní àgbáyé, bíi pé ọmọ ìkókó tí kò mọ ọwọ́ ọ̀tún yàtọ̀ sí ti òsì ni àwa aláwọ̀ dúdú jẹ́ àti pé àwọn nikan ló ni gbogbo ọgbọ́n àti àròjinlẹ̀.
Àkókò ti tó fún Áfríkà láti gbà ara wa kúrò lọ́wọ́ àwọn òyìnbó amúnisìn wọ̀nyí, lati jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pẹ́ àwa náà gbọ́n, a kìí ṣe ẹrú wọn rárá.
Òtítọ́ tí wọ́n nfi pamọ́ tí hàn síta pé láì sí aláwọ̀ dúdú, àwọn aláwọ̀ funfun kò le dá dúró. Àlùmọ́nì wa ni Amẹ́ríkà àti àwọn amùnisìn ẹgbẹ́ wọn fí nṣe ọrọ̀ àti agbára orílẹ̀-èdè wọn.
Lára àwọn ohun tí màmá wa, Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla máa nsọ fún wa rèé nípa àwọn aláwọ̀ funfun. Wọn ò nífẹ àwa aláwọ̀ dúdú rárá.
Nítorínáà, kí gbogbo àwa Áfríkà dìde, kí a má gbẹ́kẹ̀lé wọn, gbogbo ìgbìyànjú wọn ni láti gba ilẹ̀ wa, kí wọ́n sì tún wá kó wa lẹ́rú.
Àwa aláwọ̀ dúdú, pàápàá àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí a má gbàgbọ́ nínú ọ̀pọ̀ ìròyìn tí àwọn amúnisìn òyìnbó yí ńfi síta mọ́, kí a sì má fi ọkàn tán àwọn ohun tí aláwọ̀ funfun nkó wá sọ́dọ̀ wa.
Ojú ni alákàn fi nṣọ́rí.Àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) níláti dúró ṣinṣin tí òmìnira tí Olódùmarè lò màmá wa, Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti gba fún wa yìí, kí a sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Adelé wa.
A sì tún níláti ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà nínú àlàkalẹ̀ ètò ìṣèjobà tí Olódùmarè gbé fún màmá wa, fún ògo Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), láti tètè búyọ, nítorí àwa ní ìmọ́lẹ̀ ògo adúláwọ̀ tí gbogbo ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú ńretí.