Ọ̀dọ́bìnrin kan ẹni ọdún méjìlélógún tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Fáṣítì ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, D.R.Y, èyí tí ìlú agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà ń fi ipá jẹ gàba lé lórí, ni a gbọ́ wípé ó ní àìsàn jẹjẹrẹ tí ó sì nílò mílíọ̀nù márùndínlógún náírà fún ìtọ́jú. Eléyi gba omijé lójú ẹni.
Ó wá di dandan báyi, pé, àwa ìran Yorùbá níláti padà sí mímọ rírì àwọn ohun àdáyébá tí Olódùmarè fún wa ní ilẹ̀ Yorùbá, kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́mọbìnrin ọmọ ológo yí, máṣe máa wáyé.
Àìmọ rírì rẹ̀ á máa jẹ́ kí ìyà tí kò tọ́ sìwa ó dé bá ọmọ ológo nígbà tí gbogbo ohun tí a nílò fún ìtọ́jú ara wa wà ní àr’ọ́wọ́tó ṣùgbọ́n a ò mọ ìwúlò rẹ̀.
Àpẹẹrẹ ni Ọ̀dọ́bìnrin olórí-ire yí, lẹ́yìn tí àwọn ẹbí rẹ̀ bá san owó iyebíye ní ilé ìwòsàn, wọ́n yóò ṣe iṣẹ́ abẹ fún un láti gé ibi tí jẹjẹrẹ náà wà kúrò lára rẹ̀, ojú àpá kò sí leè jọ ojú ara láéláé.
Kí a dúpẹ́ lọ́wọ́ màmá wa Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tí Olódùmarè lò láti gba ìran Yorùbá lọ́wọ́ àwọn òyìnbó amúnisìn àti kúrò lábẹ́ apanilẹ́kún jayé Nàìjíríà ṣùgbọ́n tí wọ́n sì ń fi agídí jẹ gàba lórí ilé wa.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ fún wa wípé, a óò máa gba ìtọ́jú ní ìlànà ti ìbílẹ̀ Yorùbá ní àwọn ilé ìwòsàn wa.
Èyí túmọ̀ sí pé, a ò ní rọ̀gbọ̀kú lé ètò ìwòsàn ní ìlànà tí ìgbàlódé nìkan, ìwádìí tó lóòrìn yóò wà nípa àwọn ewé àti egbò tí Olódùmarè fi jíǹkí wa ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), èyí pàápàá yóò mú kí orílẹ̀ èdè D.R.Y t’ayọ orílẹ̀ èdè tó kù ní àgbáyé.
Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P), ẹ jẹ́ kí a ṣe àwárí ara wa.
Ẹ má lọ sí ilé ìwòsàn àwọn apanilẹ́kún jayé yí mọ́, àwọn ni wọ́n ń da oríṣiríṣi àìsàn síta nípasẹ̀ àṣẹ tí ọ̀gá wọ́n Bill Gates bá ti pa fún wọn, ẹ máa ṣe ìtọ́jú ara yín ní ìlànà tí a jogún lọ́wọ́ àwọn babańlá wa.