Bóyá Fúlàní ni; bóyá inkan-kí’nkan tí ìbáà wù kó jẹ́, èyí tí ó pe’ra rẹ̀ ní Alhaji Abubakar Alhaji, tí ó jẹ́ mínisítà ètò ìṣúná ní agbésùnmọ̀mí nàìjíríà ní àkókò ìṣejọba shagari ní ìlú aríremáṣe nàìjíríà náà, sọ pé nṣe ni òun nsun ẹkún fún Nàìjíríà, l’oní, torí pé, ní ẹgbàá ọdún ó dín mẹ́rin-dín-l’ọgbọ̀n, Àjọ Ìyánilówó Àgbáyé (IMF) fún’ra rẹ̀, èyí tí ó sọ ara rẹ̀ di ẹ̀rù-jẹ̀jẹ̀ sí ọrùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè l’oní, IMF yí fún’ra rẹ̀ wá yá owó lọ́wọ́ aríremáṣe Nàìjíríà!
Eléyi kò yà wá l’ẹnu rárá-à, ṣe bí nígbà kan rí pàápàá, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí bẹ Nàìjíríà fún owó. Irú nkan bẹ́ẹ̀ kò ṣe àjòjì: ṣe bí aríre-máṣe l’a pè wọ́n: wọ́n gbúdọ̀ máa jẹ́ orúkọ wọn: àpà abara-pàì-pàì.
Tiwa ni pé, kí wọ́n kó oríburúkú wọn kúrò lórí ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).
Ibẹ̀ ni àwọn kan á ti máa béèrè pé kí ni orílẹ̀-èdè wa fẹ́ jẹ́! Aàà!
Owó tí wèrè Nàìjíríà yá IMF nìgbànáà l’ọhún, níbo ni wọ́n ti ri? Ẹ jẹ́ kí á fi omi sílẹ̀ fún ẹja inú odò; omi ni’lé ẹja!