Tí a bá rí ẹnikẹ́ni tó ń sọ wípé kíni àwa ìran Yorùbá máa jẹ bí a ṣe dá dúró gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀ èdè, a jẹ́ wípé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ní ojú ṣùgbọ́n kò fi ríran.
Láìpẹ́ yìí ní a rí fọ́nrán arákùnrin kan tó ń ṣe àfihàn tòmátì tó kórè nínú oko, kìí ṣe ìlú míràn bíkòse ní ilẹ̀ Yorùbá, tí tòmátì náà sì tóbi gbàǹgbà.
Ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú bí àwọn mìíràn ṣe gbàgbọ́ pé tí àwọn ará òkè ọya kò bá tíì kó oúnjẹ wá sí ilẹ̀ Yorùbá a ò ní leè jẹun.
Ohun rere gbogbo ni Olódùmarè fi ṣe ìkẹ́ wá ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), kò sí irúgbìn tí a gbìn tí kò ní mú èso jáde, aò nílò láti kò oúnjẹ wá láti ibikíbi, ọ̀dọ̀ wa gan-an ni àwọn orílẹ̀ èdè míràn ní àgbáyé yóò ti wá máa kọ́ nípa iṣẹ́ ọ̀gbìn. Nítorí iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ ilẹ̀ wa.
Ìjọba yóò ṣe ètò ìrànwọ́ fún àwọn àgbẹ̀ láti lè máa lo irin’sẹ́ ìgbàlódé kí o leè rọrùn fún wọn láti ṣe iṣẹ́ náà.
Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a rántí wípé, ìjọba orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kò ní fi àyè gba irúgbìn GMO lórí ilẹ̀ wa.