Ìròyìn tí a gbọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára X, ìkànnì @dammiedammie35, nípa àwọn ọlọ́pa ajẹgàba Nàìjíríà tí wọ́n fi àìlẹ́tọ́ dúró sí Surulere, ní ìpínlẹ̀ Èkó, Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y, sọ pé wọ́n fi ipá mú àwọn ọ̀dọ́ mẹ́ta kan láti fún wọn ní mílíọ̀nù kan owó náírà torí pé wọn ò mú ìwé ẹ̀rí-ọkọ̀-wíwà wọn dání.
Wọ́n d’ẹ́rù bà wọ́n, wọ́n sì mú wọn lọ sí “Kafaru Oluwọlé Tinubú House Area C Police Command” ní ilẹ̀ D.R.Y wa bákan-náà.
Ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ yí, ẹ̀yin ọlọ́pa àti ológun agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí àwọn ìjọ̀ba Ajẹgàba yín ntì rìbá-rìbo, tí ó bá délẹ̀ tán, ẹ̀yin ati ìdílé yín lẹ máa jẹ púpọ̀ nínú iyà náà.
Ẹ ṣáà gbọ́ nínú fọ́nrán kan ní’bi tí Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ìyá Ìran Yorùbá, ti ń sọ̀rọ̀ lórúkọ àwa ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), pé ẹni tóo bá jẹ́ ọmọ ẹ̀yà míràn, tó wá takò ìran ọmọ aládé ní orí ilẹ̀ wa, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti sọ ìran rẹ̀ di ọ̀tá àwa ọmọ aládé.
Ẹni tó bá sì jẹ́ ọmọ I.Y.P tì D.R.Y, tó fi àyè gba ìjọba agbésùnmọ̀mí Naijiria láti lò òun takò ìran rẹ, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti sọ Ìjẹ́-ọmọ-Yorùbá rẹ̀ nù. Ààbọ̀ ọ̀rọ̀ là ń sọ fún ọmọlúwàbí, tí ó bá dé’nú rẹ̀ á di odindi.
Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) ti bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba ara ẹni láti ọjọ́ Kejìlá oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé-mẹ́rinlélógún yí; orúkọ Olórí Ìjọba-Adelé wa, Bàbá wa, Mobọ́laji Ọlawale Akinọla Ọmọ́kọrẹ́ ni ó sì ti jẹ́ mímọ̀ ní Àjọ Àgbáyé.
Títí láé ni àwa á máa yin Ọlọ́run nínú ayé Màmá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, fún lílò tí ẹ gbà kí Olúwa lò yín fún ògo Rẹ̀ fún ìtúsílẹ̀ àwa ọmọ Yorùbá kúrò nínú oko ẹrú àwọn amúnisìn.