Ìròyìn kan tí a rí lórí Ayélujára, ní ìkànnì Sahara Reporters, sọ pé, Ilé-Aṣòfin Àgbà ní ìlú tó fẹ̀gbẹ́ tì wá agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, tó ń jẹgàba lórí ilẹ̀ wa Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ti gba àbá kan wọlé, tí ó fi òntẹ̀ lùú láti gbé ‘àjọ fún ìdàgbàsókè gúúsù ìwọ̀-oòrùn kalẹ̀.

Èyí túmọ̀ sí pé àwọn aláìmọ̀yí tó kàn asòfin ìlú ajẹgàba Nàìjíríà sì ń ka ilẹ̀ D.R.Y mọ́ ara wọn.

Màmá wá Oloye Ìyá-Ààfin Modupeọla Onitiri-Abiọla, ni Ọlọ́run lò fún àṣeyọrí òmìnira Yorùbá, tó sì hàn sí gbogbo àgbáyé.

Gbogbo àwọn gómìnà agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí ó wà káàkiri Orílẹ̀-Èdè Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) àti àwọn Ilé-Ìgbìmọ̀ Aṣòfin wọn,

pẹ̀lú Ààrẹ aríremáse Nàìjíríà, ló ti gba ìwé Ìgbàpadà (Reclamation) nígbà náà ní  oṣù Ọpẹ́, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, títí di oṣù Ṣẹ́rẹ́, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́talélógún, tí wọ́n sì búwọ́ lù’wé pé àwọn ti ri gbà, èyíinì lẹ́yìn tí a ti ṣe ìkéde òmìnira wa ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàá ọdun ó lé méjìlélógún. 

A sì ti bẹ̀rẹ̀ ìsèjọba ara ẹni láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún tí a ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ

 Wá gbọ ó! Agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó ń jẹgaba lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y,  jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates 30/09/2024