Ìbùkún ní fún orílẹ̀ èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).

Àwọn ọ̀rọ̀ rere báyìí ni àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People I.Y.P) níláti máa sọ sí orílẹ̀ ẹ̀dè wa láti pè wá jáde sínú ògo wa.

Àbí báwo ní a ó ti ṣe àlàyé ti ọmọ Yorùbá tí ko ju ọdún mẹ́rìndínlógún ní ọjọ́ orí tí ó di apànìyàn nítorí owó? Èyí kìí ṣe àṣà àti ìṣe wa rárá. Àsopọ̀ amúnisìn ló kó bá ìran ọmọ Aládé.

A rí ìròhìn kan láì pẹ́ yìí bí Azeez Tajudeen ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ṣe tan Ibrahim ọmọ ọdún mẹ́rin tí ó jẹ́ alaádúgbò rẹ̀ lọ sí ilè ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kan tí ó lọ pá nítorí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta naira.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yí wáyé ní agbègbè Ìjànikin, ìpínlẹ̀ Èkó ni Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ( Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) tí ìlú arufin Nàìjíríà nfi ipá jẹ gàba lé lórí báyìí.

Ìròhìn náà tẹ̀síwájú pé lẹ́hìn tí Azeez pa Ibrahim tán, ó kó ìfun àti kídìrín rẹ̀ jáde, ó sì gé nkan ọmọkùnrin rẹ̀.

Ó ní ọkùnrin kàn tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Ọ̀ṣọ́ ní ó ran òun pẹ̀lú ìlérí láti fún òun ní àádọta ẹgbẹ̀rún náírà.

Democratic Republic of the Yorùbá daily news

Ó ní Ọ̀ṣọ́ yẹn ló nílò ẹ̀yà ara ènìyàn.Ọ̀rọ̀ p’èsì jẹ. Ohun tí ìjẹgàba àwọn agbésùnmọ̀mí, apaniṣayọ̀ Nàìjíríà dá sílẹ̀ sínú ayé àwọn ọmọ kékèké àti ọ̀dọ́ wa rèé.

Búburú yìí níláti d’áwọ́ dúró, ìjẹgàba yìí níláti wá s’ópin ní kíákíá Omìnira wa kúrò lára ìlú agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun àti ìbúra wọlé fún olórí ìjọba Adelé wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọ́kọrẹ́ ní ọjọ́ kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún tí sọ wá di orílẹ̀ èdè aṣèjọba ara ẹni, tí ó sì fún wa ní ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnṣe àti àtúntò ìgbé ayé wa nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò ìṣèjobà tí Olódùmarè gbé lé màmá wa tí ó jẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ fún òmìnira àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla lọ́wọ́.

Nípa àlàkalẹ̀ ọwọ́ màmá wa, àwọn ọ̀dọ̀ wa máa rí ògo wọn lò, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ màmá wa, ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ wà nínú àlàkalẹ̀ ìṣèjọba yìí láti ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé ìkẹ́kọ́ gboyè àkọ́kọ́ ní fásitì, iṣẹ́ yíò sì wa ní yanturu fún wọn láti rí ògo wọn lò fún ìṣerere àti ọjọ́ ọ̀la tí ó dájú.

Kò ní sí ìdí láti wá owó òjijì tàbí owó ẹ̀jẹ̀. Àwọn ìjọba mùjẹ̀mùjẹ̀ agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó ńjẹgàba lórí ilẹ̀ wa yíò kúrò pẹ̀lú ẹ̀tẹ́ àti ìtìjú àgbáyé láì pẹ́ yìí lágbára Olódùmarè, a ó wa bọ́ sínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbádùn.