Fónrán kan ni a fìhàn wá láìpé yíì, ní ibi tí àwọn kan ti n gbìyànjú láti fi agídí gbé obìnrin kan pẹ̀lú ọmọ rẹ méjì tàbí kí á sọ pé àwọn ìbejì rẹ̀ sínú ọkọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ònà bí obìnrin náà ti nrìn lọ tí ó sì ń bá wọn ṣe agídí.

Obìnrin yi ni àrùn ọpọlọ gẹ́gẹ́bí a ti ri nínú fónrán náà, àwọn ọkùnrin tí ó wà gbé yí pàápàá f’ìwà jọ alárùn ọpọlọ bí wọ́n ti npariwo mọ pé, àwọn fẹ́ lọ ṣe ìtọ́jú ẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ ni.

Bí fọ́nrán yìí kò tilẹ̀ sọ pàtó ìpínlẹ̀ tí ìṣẹ̀lẹ̀ yí ti ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n èdè Yorùbá tí a gbọ́ tí wọ́n ń sọ lẹ́nu fi hàn dájú pé ìpínlẹ̀ kan ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ní ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀ àti pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìlú agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà tó nfi ipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, ló ń ṣiṣẹ́ ìtìjú náà.

Gbogbo ìgbésẹ̀ àwọn ìjọba ìlú agbèsùnmọ̀mí Naijiria lórílẹ̀ èdè wa yìí lòdì sí òfin àgbáyé, iwa ìjẹ gàba àti ọ̀daràn ni, ilẹ̀ Yorùbá kìí ṣe ará aríremáṣe Nàìjíríà mọ́ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbẹ̀wá ọdún ó lé méjìlélógún tí a ti gba òmìnira wa kúrò nínú ìlú àwọn ìkà yii,a sì ti di Orílẹ̀-ẹ̀dè aṣèjọba-ara-ẹni láti ọjọ́ kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún nígbàtí a ti búra wọlé fún olórí ìjọba Adelé wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọ́kọrẹ́. Naijiria kò ní ẹ̀tọ́ láti dá sí ètò ìlera Orílẹ̀-èdè wa, a kò pè wọ́n si.

Democratic Republic of the Yorùbá daily news

Olódùmarè tí Ó lo màmá wa, Olóyè Ìyá Àfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá ti fún wọn ní àlàkalẹ̀ ètò ìṣèjọba tí ó dára, a sì ti gbọ lẹ́nu ìyá wa pé ètò ìwòsàn ọ̀fẹ́ yóò wá fún gbogbo àwa I.Y.P., ọ̀wọ̀ yóò wà fún ẹ̀tọ́ ará ìlú nítorínáà, ko sí àyè láti fi agídí wọ́ ènìyàn fún ìdí kan tàbí òmíràn láì bìkítà fún un, gẹ́gẹ́bí àwọn oṣìṣẹ̀ afagídí jẹgàba Nàìjíría ṣe n hùwà àìnítìjú nínú fọ́nrán ọ̀hún.

Ọ̀pọ̀ ló kàgbákò àárùn ọpọlọ nípasẹ̀ ìrònú àìnì àti ìnira ọrọ̀ ajé tí ìjọba ìlú agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà ń dá sílẹ̀ lórí ilẹ̀ wa, D.R.Y. nítorí ìfi agídí jẹgàba wọn.

Màmá wa tún sọ nípa ètò ọrọ̀ ajé tí yóò fún wa ní ìfọkànbalẹ̀, tí àwọn ọ̀dọ́ yóò rí ògo wọn lò, àwa ará ìlú náà yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí í ìgbádùn lọ́gán tí àwọn ìjọba Adelé wá bá ti wọlé sí oríkò ilè iṣẹ́ ìjọba wa.