Gbọ Audio Ìròyìn Òmìnira

ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI

OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.

ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ

Bill Gates kò fi ètè àti ètò rẹ̀ láti pa àwọn ènìyàn ní àgbáyé yí, bò rárá; àwọn ọmọ èèyàn, pàápàá aláwọ̀dúdú, ni a ṣe bí ẹní dágunlá sí ọ̀rọ̀ tí Bill Gates ti ń sọ láti ọjọ́ tó tí pẹ́.

Lákọkọ́, bí Bill Gates ṣe máa nsọ̀rọ̀, àfi bíi pé ó ti ní ibi kan tí a ti jọ jóko sí tẹ́lẹ̀, tí gbogbo àgbáyé ti yàn-án kí ó ṣe olórí fún wa, tí èyí kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá; ṣùgbọ́n àwa aláwọ̀dúdú, ó ti wọ̀ wá lára kí á máa gba ohunkóhun tí òyìnbó kan tàbí òmíràn bá ti sọ, ìbáà ṣe èèrà tàbí ìdin, tí ó bá ṣáà ti jẹ́ òyìnbó, kí a máa gba ohun tí ó bá ti sọ, gẹ́gẹ́bí pé ẹlẹ́da ló sọ-ọ́.

Tí Bill Gates bá jẹ́ ènìyàn dúdú, tí ó dẹ̀ tún jẹ́ aládúgbò wa, bí ó ti wù kó lówó tó, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wa kò ní kà sí pàtàkì. Lákọ́kọ́ àá sọ pé kò kàwé gboyè. Bill Gates tí ẹ nwò yẹn kò lò tó ọdún kan-àbọ̀ ní fásitì, tí ó ti kúrò níbẹ̀. Àwọn ọmọ wa tó gboyè rẹpẹtẹ, tí ìjọba ajẹgàba arí’re-máṣe ìlú agbésùnmọ̀mí tí wọ́n máa sá kúrò lórí ilẹ̀ wa láìpẹ́ kò jẹ́ kí ògo wọn ó yọ, òmíràn nínú wọn ngun ọ̀kadà ká ṣáà rí nkan fi s’ẹnu, wọ́n kàwé ju Bill Gates lọ!

Bill Gates kò gba oyè àkọ́kọ́ ní Fásitì ni, àbí ilé ẹ̀kọ́ gbogbo nìṣe Pólì, èyí tí ó kún inú ilé wa, tí a ò rí nkan fi ṣe; ṣùgbọ́n wípé ó jẹ́ aláwọ̀ funfun yẹn, tí ó bá ṣáà ti la ẹnu rẹ̀ rírùn gbàgà, àwọn olórí orílẹ̀-èdè ní Áfríkà á bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe “yẹ sà”! Àwọ̀ funfun ṣáà ni wọ́n fi njẹ wá! Bill Gates kì ńṣe dókítà, kì ńṣe nọ́ọ̀sì, á dẹ̀ máa pàṣẹ nípa ètò ìwòsàn bí ẹni pé òun ló dá ọmọ ènìyàn! L’oótọ́, gẹ́gẹ́bí a ti mọ̀,

kì nṣe lílọ sí ilé-ìwé ni ó túmọ̀ sí ọgbọ́n tí a nílò láyé [gẹ́gẹ́bí a ti mọ̀, dáradára ní orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y, ìwé kọ́ ni a máa fi r’ayé wá ní orílẹ̀-èdè wa], ṣùgbọ́n, ní bí àwọn èèyàn wa ṣe máa nronú tẹ́lẹ̀ kí màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, tó dìde láti sọ̀rọ̀ pé ìwé ti Oyinbo amúnisìn kọ́ ni Orílẹ̀-èdè wa dúró lé lórí, irúfẹ́ Bill Gates yẹn kọ́ ni ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ máa kà sí ẹni tí ó máa kọ́ wa nípa ètò ìwòsan!

Àgàgà, kò tilẹ̀ wá ní iṣẹ́ ètò-ìwòsàn tó nṣe ju kó máa ṣe agbóde-gbà fún àwọn ẹlẹ́tẹ alágbayé tí wọ́n fẹ́ dín ọmọ ènìyàn kù, àwọn tí wọn ò fẹ́ rí aláwọ̀dúdú lórí ilẹ̀ ayé, látàrí pé wọ́n ṣáà kórira wa, wọ́n sì fẹ́ gba ilẹ̀ wa, tí ti ọmọ Yorùbá ò dẹ̀ ṣe é gbà, bẹ́ẹ̀ ni Olórí ìjọba wa, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, kò sí lára ẹni tó máa gbà’gbà-kúgbà lọ́wọ́ ẹni asán kankan, tí ó lòdì sí ògo tí Olódùmarè ṣe fún ọmọ Yorùbá!

Ní ti ìránṣẹ́ àṣìtáánì, Bill Gates yí, kò fi ìgbà kankan fi ète rẹ̀ láti pa aráyé bò rárá. Oríṣiríṣi fọ́nrán níbi tí òun fúnra rẹ̀ ti nsọ̀rọ̀, ló wà káàkiri ayélujára, tí ó ti fi ẹnu ara rẹ̀ sọ pé àwọn fẹ́ dín iye ènìyàn tí ó wà láyé kù, àti pé àwọn fẹ́ lo abẹ́rẹ́-àjẹsára láti ṣe iṣẹ́ ibi yí, bẹ́ẹ̀ ni àwọn máa da àìsàn síta títí tí àwọn á fi riṣe! Ṣùgbọ́n ti àwa ọmọ Yorùbá yàtọ̀ o! Ìdí nìyẹn tí a nílati ri dájú pé a ò yẹ’sẹ̀ kúrò nínú Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), nípasẹ̀ Màmá wa, MOA.

Latest news on Bill gates - bill gates is out to destroy humans. He's far from saving lives.
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Bill Gates, ẹni ibi yí, sọ nínú fọ́nrán kan tí a rí, ó ní àwọn nmú àwọn ohun ayédèrú (GMO), àwọn nfi sí’nú abẹ́rẹ́-àjẹsára, tí àwọn dẹ̀ nfi abẹ́rẹ́-àjẹsára ọ̀ún gún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́! Èdùmàrè gbà wá! Tí ẹ bá rí aṣiwèrè yí níbi tí ó ti nsọ ọ̀rọ̀ náà, nṣe l’ó tún nrẹ́rin pé “a máa nkì-í sí wèrè wọn lára kí wọ́n kú sọnù,” irúfẹ́ yẹ̀yẹ́ tí ó nṣe nìyẹn níbi tí ó ti nsọ ọ̀rọ̀ yí.

Ó tún sọ̀rọ̀ níbi míràn, ó ní, láarín bí ọdún márun sí àkókò tí òun ún sọ̀rọ̀ nígbà-náà, pé àwọn kàn máa nílò láti ṣe aṣemáṣe kàákiri, láti mọ ìwà ìkà èyí tí ó máa ṣiṣẹ́ dáradára, nítorí oríṣiríṣi àwọn ohun olóró tí wọ́n npè ní “nanoparticles” ló wà, tí àwọn le lò, àti pé lára wọn tún lè ṣe iṣẹ́ oró ju àwọn kan lọ. Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n á kàn máa máa fi ọmọ-aráyé ta ayò ikú, títí wọ́n á fi rí èyí tí ó máa jẹ́ ní gidi.

Ó ní àwọn máa ní abẹ́rẹ́-àjẹsára fún oríṣiríṣi nkan – títí kan aìsàn ibà, àrùn HIV, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ – gbogbo ọ̀nà tí àwọn ṣáà lè wọ àwọn èèyàn l’ara l’ati lè ṣe’kú pa wọ́n!

Ó tún sọ pé l’oótọ́ ni pé òun ti ná bílíọ̀nù mẹ́wa dọ́là ní àárín ogún ọdún, àti pé kì nṣe owó kékeré lórí abẹ́rẹ́-àjẹsára, bẹ́ẹ̀ ni, òun ní ìrètí àti jèrè, torí owó okòòwò ni! Ẹ wá bá wa béèrè o, okòòwò kíni? Okòòwò ìpànìyàn, tórí pé ẹ fẹ́ẹ́ gba ilẹ̀ aláwọ̀dúdú! Bẹ́ẹ̀ ní ẹ fẹ́ ní àgbáyé ní ìkáwọ́ ẹ̀yin ẹlẹ́tẹ alágbayé, ẹ fẹ́ rọ́pò ẹlẹ́da, àbí?

Nínú fọ́nrán tí a rí, bákan-náà, wọ́n béèrè lọ́wọ́ wèrè apànìyàn yí nígbà-náà, pé, ìgbà wo ló rò pé nkan máa padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀? Ó ní, ní àkókò tí wọ́n bi òun ní ìbéèrè yẹn, pé, láìpẹ́ sí ìgbà náà, àkókò bí oṣù mẹ́san ṣì máà wà tí kòì tíì ní sí àyè fún àwọn èèyàn láti wà papọ̀ ní yanturu.

Ó ní, kí ohun gbogbo ó tó le wà bí “ó ṣe yẹ kó wà,” àwọn á kọ́kọ́ níláti fún gbogbo àgbáyé ní abẹ́rẹ́ àjẹsára ná! Olúwa o! Abẹ́rẹ́ àjẹsára tó ti fi ẹnu ara ẹ̀ sọ pé àwọn fẹ́ fi dín ènìyàn kù lágbayé ni! Èyí túmọ̀ sí pé “bí ó ṣe yẹ kí nkan wà” tí Bill Gates nsọ, ní pé, kí ọmọ-ènìyàn ó dínkù! Ṣé òun ni Ẹlẹ́da ní?!

Ó tún wá sọ, nígbà náà l’ọhún, ó ní àìsàn “kónílé-ó-gbélé” tí ó wà ní àsìkò náà l’ọhún kì nṣe àṣemọ irúfẹ́ rẹ̀! Ẹ jọ̀wọ́ báwo ló ṣe mọ̀? Èyí fi yé wa pé àwọn ẹni ibi wọ̀nyí ni wọ́n nmọ̀ọ́-mọ̀ da àìsàn wọ̀nyí sínú ayé: àtàìsàn àtabẹ́rẹ́ àjẹsára àìsàn, àwọn méjèèjì, kí ọmọ ènìyàn ṣáà ti kú! Iṣẹ́ tí Bill Gates wá’yé wá ṣe nìyẹn, kò dẹ̀ fi bò rárá!

Ó wá la ẹnu ẹ̀ gbàgà, ó ní, nṣe ni a níláti máa gbáradì fún èyí tó tún nbọ̀! Èyí túmọ̀ sí pé, wọ́n ti to àwọn àìsàn yẹn lẹ́sẹẹsẹ! Tí eléyi kò bá pawọ́n run tán, àá tún gbé òmíràn jáde! IṢẸ́ BILL GATES ÀTI ÀWỌN ALÁGBAYÉ TÓ RAN NÍṢẸ́ NÌYẸN.

Wèrè yí wá la’nu, ó ní èyí t’ó nbọ̀ yẹn, àwọn èèyàn á gbà! Èyí túmọ̀ sí pé èyí tó mbọ̀ máa ká ọwọ́ gbogbo ènìyàn kò, ẹni tí kò báì tíì kú á wá jọ̀wọ́ ara rẹ̀, fún àwọn wèrè alágbayé yí, kí wọ́n máa ṣe àkóso ìgbé-ayé wọn! Ṣùgbọ́n o! Rárá! Kò sí ọmọ Yorùbá lára àwọn tí alágbaye irọ́ kan máa tẹ orí rẹ̀ ba! Ẹ wá jẹ́ kí á mọ̀ o! Ojúlówó ọmọ Yorùbá ni a nsọ o!

Ọmọ Yorùbá tó ní ìdánilójú pé Olódùmarè nìkan ni Ìgbàlà wa kúrò lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ àṣítáánì tí wọ́n pe’ra wọn ní kò sí báwọn ò ṣe jẹ́ wọ̀nyí, tí aráyé npè ní alágbayé; ọmọ Yorùbá tí ó mọ̀ pé Èdùmàrè ni Ìgbàlà wa kúrò lọ́wọ́ wọn, tí ó dẹ̀ mọ̀ pé Ìyá-Wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ni Olódùmarè rán sí wa láti ṣe iṣẹ́ Olùgbàlà náà, tí a dẹ̀ ntẹ̀lé Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún wa ní Orilẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), nípasẹ̀ Màmá wa yí, àwa ni a ní Ìgbàlà o! Ẹ má ṣe jẹ́ kí á fi ṣeré rárá!