Tiktok @ hon. _steve_mbogo – (a lo fọ́nrán yí fún ẹ̀kọ́ nìkan, a sì ṣe ìdánimọ̀ fún àwọn tí ó ní ẹ̀tọ́ lórí rẹ̀.)

Bí Bill Gates àti àwọn alágbàáyé ṣe ń gbé ìgbésẹ̀ lorísìírísìí ọ̀nà láti dín iye àwọn ènìyàn tí ó wà ní àgbáyé kù pàápàá àwa aláwọ̀ dúdú, ọ̀rọ̀ náà tí wá dé ìkòríta tí a kò gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ lẹ́rán mọ́ nítorí pé wọn ò dákẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò simi.

Fọ́nrán arákùnrin kan ni a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára, tó sì ṣe àlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iṣẹ́ tí àwọn alágbàáyé wọ̀nyí ń ṣe lọ́wọ́ – lọ́wọ́ báyìí ní orílẹ̀ èdè Kenya.

Ó wípé, wọn yóò ríi dájú pé àwọn ni wọ́n ń darí àwọn ènìyàn, wọ́n wípé, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ dín iye wọn kù, báwo ni a óò ṣe wá ṣe eléyìí? Bí a ṣe leè ṣe ní láti jẹ́ alákòóso oúnjẹ, nítorí pé tí ẹ bá ti lè jẹ́ alákòóso oúnjẹ, ẹ ti jẹ́ olùdarí ènìyàn nìyẹn. 

Ìdí nìyí tó fi jẹ́ wí pé, láti ọdún bíi mẹ́wàá sẹ́yìn, àwọn òfin tí ìjọba orílẹ̀ èdè Kenya ńṣe ní àwọn òfin tí ẹnikẹ́ni kò ní leè ṣe iṣẹ́ ọ̀gbìn, nítorí pé wọ́n ti gbà àkóso ètò ọ̀gbìn pátápátá, kúrò ní  ọ̀dọ̀ ẹnìkọ́ọ̀kan lọ sí ọ̀dọ́ àwọn àjọ alágbàáyé wọ̀nyí.

ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI

OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.

ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ

Ẹ jẹ kí a làá yé wa dáadáa, Èròǹgbà wọn ni láti jẹ́ alákòóso oúnjẹ àti  Olùpèsè oúnjẹ, nípa jíjẹ́ alákòóso ní wọ́n sì fi leè ṣe eléyìí, wọ́n wá wò ó wípé ọ̀nà tí àwọn leè gbà ní láti má ṣe múu ní dandan fún àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa àwọn ìlànà kan. 

Kí ni kí a wá ṣe ó? A ní láti ṣe àwọn ìlànà kan ni àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí, láti leè rí dájú pé àwa ni alákòóso oúnjẹ, bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí pẹ̀lú pípèsè oúnjẹ, ní orílẹ̀ èdè Kenya lónìí, púpọ̀ oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ GMO ni. Àwọn alágbàáyé yí sì ni olùdarí GMO, àwọn ni ilé iṣẹ́ tó tóbi jù lọ ní àgbáyé, bí àpẹẹrẹ Monsanto, Cargil, Dupont, àwọn wọ̀nyí lóni irúgbìn náà. 

Ìjọba orílẹ̀ èdè Kenya nígbà kan tí ṣe òfin nígbà náà lọ́hùn-ún, tó sì ti jẹ́ kí wọ́n rí àyè láti ta irúgbìn GMO, lónìí ó ti di ọ̀ràn dídá lábẹ́ òfin orílẹ̀ èdè Kenya láti fún ẹnikẹ́ni ní irúgbìn àdáyébá, kò sì bí ó ti wù kí ẹni náà sún mọ́ọyín tó. Irúgbìn àwọn alágbàáyé tí wa gbilẹ̀ dáadáa, wọ́n ṣe eléyìí nítorí pé ẹni tí ó bá wù wọ́n ni wọn lee tá fún ní iye tó wù wọ́n. 

Irúgbìn GMO kò sì ṣeé tún gbìn nígbà méjì, èyí yóò mú kí ẹ tún lọ báwọn láti ra irúgbìn lọ́wọ́ wọn nígbà míràn. Ìwọ̀n kan tòmátì ní orílẹ̀ èdè Kenya báyìí ti di mílíọ̀nù mẹ́wàá owó wọn, tí àbáláyé rẹ̀ ní àádọ́rin mílíọ̀nù owó Kenya. 

Wọ́n ti ń mú àwọn ènìyàn lọ sí ibi tó jẹ́ wípé ní nǹkan bí ọdún márùn-ún sí mẹ́wàá sì àkókò yí kò ní sí àgbẹ̀ tí yóò leè dá oko mọ, wọ́n ti kó ajílẹ̀ ayédèrú síta, nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àgbẹ̀ tó bá gbin irúgbìn ní ọdún yìí, mélòó nínú wọn ni yóò leè gbìn ní ọdún tó ń bọ̀? 

The Democratic Republic of the Yoruba also known in the Yoruba history as Yoruba Nation, Yoruba Kingdom, Yoruba Land and Yoruba Country is the newest nation in the world. The 55th nation in Africa and 17th in Western Africa as of 12th April 2024. Yoruba is know a sovereign nation and its no longer part of Nigeria.

Láìpẹ́ yìí ní wọ́n tún ṣe òfin pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gboyè kíní ní ilé ìwé gíga, kíni èyí wá túmọ̀ sí? Ẹ ò ní leè ṣe iṣẹ́ ọ̀gbìn láìní ìwé ẹ̀rí ilé ìwé gíga. 

Òfin tuntun tí wọ́n tún ṣe báyìí ni wọ́n pè ní òfin ẹran ọ̀sìn ti ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún, wọ́n wí pé àwọn fẹ́ ṣe ìlànà nípa ẹran ọ̀sìn, nítorí pé wọn kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa sin ẹran ọ̀sìn láìgba ìwé ẹ̀rí lọ́wọ́ wọn, ẹni tí ó bá sì takò ìgbésẹ̀ náà yóò san mílíọ̀nù kan àbọ̀ owó Kenya, gbogbo ohun tí ẹ bá ń fún àwọn ẹran ọ̀sìn yín gbọ́dọ̀ jẹ́ lábẹ́ ìdarí wọn títí kan oògùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì tako òfin ọ̀hún yóò san mílíọ̀nù kan owó wọn tàbí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì. 

Oríṣiríṣi ẹgbẹ́ àti àjọ ni wọ́n  sì ti ṣètò tí yóò máa bójú tó àwọn ẹran ọ̀sìn, àwọn tí yóò máa tàá, àwọn tí yóò máa fún wọn ní abẹ́rẹ́ àjẹsára àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ti dá ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò ti lọ máa kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ẹran ọ̀sìn, tí wọ́n yóò sì ní ìwé ẹri, wọ́n ṣe ìwọ̀nyí kí ẹ̀ka tí ẹran ọ̀sìn leè wà ní abẹ́ àkóso wọn láti leè ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn. 

Wọ́n tún ti bá a dé ibi ilẹ̀ báyìí, ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ilẹ̀ ni yóò máa san owó àti pé Mínísítà fún ètò ilẹ̀ ní yóò máa sọ iye owó tí ẹnìkọ́ọ̀kan yóò máa san. Gbogbo ìgbésẹ̀ wọ̀nyí ní láti múṣẹ ní ẹgbàáọdún àti ọgbọ̀n.

Ọkùnrin náà tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ wípé, ó dàbí wípé àwọn ìjọba wọ̀nyí kò mọ ibi tí wọ́n ń  lọ, nítorí pé gbogbo òfin tí wọ́n ń ṣe yí, kìí ṣe láti ọ̀dọ̀ ìjọba Kenya, àwọn àjọ alágbàáyé yí ló ń ṣe wọ́n láti leè ṣe àkóso oúnjẹ àti ilẹ̀ wọn.

Wọ́n tún sọ wípé kí ó tó di ẹgbàáọdún ó le ọgbọ́n ẹnìkọ́ọ̀kan kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ju ìwọ̀n mẹ́rìndinlógún ẹran lọ láàárín ọdún kan, àwọn ọkọ̀ gbọ́dọ̀ dínkù débi pé ẹgbẹ̀rún kan ènìyàn ni yóò máa pín ọkọ̀ igba wọ̀, ìgbésẹ̀ ńlá gidi ni wọn sì ń bá a lọ láti parí rẹ̀ ní ẹgbàá ọdún àti ọgbọ́n. 

O ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yéwa dáadáa gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ìyà wa máa ń bá wa sọ báyìí ni wípé, déédéé ìgbà yí gan-an ni a gbọ́dọ̀ dìde nítorí, aò ní leè dúró wo ohun tí ó ń bọ̀. 

Ṣèbí díẹ̀ tí a gbọ́ ni ìwọ̀nyí, mélòómélòó ni àwọn tí a kò gbọ́ tí wọ́n sì ń gbé ìgbésẹ̀ ní gidi. 

Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a dìde láti gbárùkù ti àwọn adelé wa, Olódùmarè ti gbà wá, ẹ má tún jẹ́ kí a fi ìyà jẹ ara wa mọ́. 

Fún ìdí èyí, màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, gbogbo àwa ọmọ Yorùbá dúpẹ́ lọpọlọpọ fún iṣẹ́ takuntakun tí ẹ ṣe fún wa, Kí Ọlọ́run Olódùmarè kò wà pẹ̀lú yín, ìran Yorùbá mọ̀ọ́ lóore.