ÀǸFÀÀNÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TÍ YORÙBÁ: ỌMỌ YORÙBÁ Ò TÚN ṢE ẸRÚ MỌ́
Nígbà gbogbo ní àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó sí’jú àánú wò wá, tó rán ìyá onínúure sí wa láti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú oko ẹrú, gẹ́gẹ́ bí màmá wa, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa wípé, ọmọ Yorùbá ò ní ti oko ẹrú kan bọ́ sí […]