Nígbà tí a bá sọ pé kò sí nǹkan tó ń jẹ́ ọba ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), òótọ́ àti òdodo ni; kí ẹnikẹ́ni má sì ṣe lòdì sí ọ̀rọ̀ yí, kò sí ọba ní D.R.Y. Kí á sì rántí pé ìjọba D.R.Y ti bẹ̀rẹ̀. Nítorí èyí, ó jẹ́ ọ̀ràn-dídá fún ẹnikẹ́ni láti pe ara rẹ̀ ní ọba ní Ilẹ̀ Yorùbá.
Kò sí ọba mọ́ ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y). Nítorí náà, gbogbo àwọn tí wọ́n bá ṣì npe’ra wọn ní ọba, tàbí tí àwọn èèyàn kan ń pè ní ọba, wọ́n ń ṣe lòdì sí ìjọba Democratic Republic of the Yoruba, lẹ́yìn ọjọ́ kéjìlá, oṣù Igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún tí ìjọba D.R.Y ti wà ní ìkàlẹ̀, irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ ń ṣẹ̀ sí òfin orílẹ̀-èdè aṣèjọba ara-ẹni D.R.Y.
Nítorí èyí, kí gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ó ṣọ́ ìsọ̀rọ̀-sí wa.
A rí fọ́nrán kan láìpẹ́ yí, ní ibi tí wèrè kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Ẹniìtàn Ògúnwùsì Adéyẹyè ti ns’ọ̀rọ̀ bíi pé ó ní àṣẹ láti sọ ohun tó ń sọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ ìsọkúsọ ọ̀rọ̀ wípé àwọn ìran Ìgbò ló ní ajé kìí ṣe Yorùbá, tí aláìní’tìjú rẹ̀ ń sọ òyìnbó wèrè tí ó ṣì máa tún sọ nígbàtí ọjọ́ ìdájọ́ rẹ̀ bá dé.
Ọ̀rọ̀ yí kò rú’jú rárá,
Èkíní, kò sí ipò kankan t’ó ń jẹ́ “ọba” ní Democratic Republic of the Yoruba.
Èkejì, Ẹniìtàn Ògúnwùsì Adéyẹyè kò ní ipò àṣẹ kankan ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).
Ẹ̀kẹ́ta, ìṣèjọba D.R.Y ti bẹ̀rẹ̀, kí oníkálùkù wa ó ṣọ́ ara wa, ṣọ́ ẹnu wa, àti ìhùwà-sí wa, kí a má ṣe lòdì sí ìṣèjọba ara-ẹni D.R.Y, ìjọba tí ó jẹ́ aṣojú fún gbogbo ojúlówó ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) lábẹ́ àkóso Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún àwa Ìran Yorùbá títí ayé nípasẹ̀ Màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla.