Nínú fọ́nrán kan lati ri gbọ́ wípé, ọkọ̀ tó ń lo iná mọ̀nàmọ́ná ti wà láti ayégbọ́ngan ṣùgbọ́n, nítorípé àwọn amúnisìn yí fẹ́ ma jẹ èrè gọbọi lórí epo rọ̀bì àti epo bẹtiróòlù pẹ̀lú ìwà ìjẹgàba wọn lórí àwọn orílẹ̀-èdè míràn ni àwọn aláwọ̀-ẹlẹ́dẹ̀ ṣe fi irú nǹkan bayi pamọ́ fún àgbáyé.
Bí àwọn apanijayé yìí ṣe ní ìfẹ́ owó ju ẹ̀mí ènìyàn lọ tó, ní èjì dín lẹ́gbẹ̀wá ọdún ní wọ́n ṣe ikú pa ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Stanley Meyer tó ṣe ọkọ̀ tó ń lo omi lásán láti ṣiṣẹ́ ní okòó dín lẹ́gbẹ̀wa ọdún,ṣùgbọ́n àwọn apanilẹ́kún jayé yí ṣekú pa ọkùnrin náà kó má baà lè tẹ̀síwájú.
Àwọn òyìnbó amúnisìn yìí mọ ọgbọ́n bí aṣé ń fẹran s’ẹ́nu k’á wa tì. Ṣé ọgbọ́n àti má kojú bọ ìlú onílùú káàkiri ni wọn ṣe gbà láti lo ọkọ̀ tó ń lo mọ̀nàmọ́ná làgbáyé báyìí.
Àìmọye ìlú ní àwọn aláwọ̀-ẹlẹ́dẹ̀ yìí ti parun látàri ìwà ìjẹgàba wọn. Ìdí ni pé aṣálẹ̀ ní ìlú tí Olódùmarè jogún fún àwọn alápò-ìkà yìí, tí ilẹ̀ adúláwọ̀ sí kún fún wàrà àti oyin, èyí ló fàá tí wọ́n fi ń lo onírúurú ète láti gbà gbogbo àlùmọ́ọ́nì ilẹ̀ adúláwọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí Màmá wa Olóyè, Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (MOA) ti gbé ìpìlẹ̀ rere kalẹ̀ fún àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P), wọ́n ṣèlérí pé ọmọ Yorùbá kò ní ti oko ẹrú kan bọ́ sí òmíràn. Orílẹ̀ èdè kankan lágbàáyé kò ní jẹgàba lórí ẹ̀bùn tàbí ìmọ̀ I.Y.P rárá.
Ògo àti ẹ̀bùn àwa ọmọ Yorùbá a búyọ nígbàtí àwọn ìjọba Adélé wa bá tí wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba láti tẹ̀síwájú iṣẹ́ ní pẹrẹu.
Ní àkótán, ohun tí yóò jẹ́ kókó ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú orílẹ̀-èdè tí ìbáà-wù kó jẹ́ ni pé, lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá Ni Àkọ́kọ́!
Gẹ́gẹ́ bí ìyá wa ti sọ fún wa, ìlẹ̀ Yorùbá kò ní ta ohunkóhun ní rọ̀bì fún orílẹ̀-èdè kankan. Ohun tí a ó tà jáde yóò jẹ́ èyí tí a ti sọ di ohun lílò, bẹ́ẹ̀ na ni a ò ní fi Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá sílẹ̀ láti máa tẹ́ orílẹ̀-èdè míràn lọ́rùn.
Àwọn ìpìlẹ̀ rere yìí, kò ní f’àyè gba orílẹ̀-èdè kankan láti fi ìwọ̀sí lọ Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y.