Ìjọba orílẹ̀ èdè Burkina Faso ṣe’lérí iná mọ̀nàmọ́ná tó dúró déédéé fún àwọn ọmọ ìlú rẹ̀, wọ́n sì sọ pé ó ṣe-é-ṣe kí eléyi wáyé nípasẹ̀ àgbékalẹ̀ irinṣẹ́ alágbára tí wọn ń gbèrò láti s’ àgbékalẹ̀ rẹ̀. Ààrẹ Traore sọ pé èyí ṣe pàtàkì nítorí pé àwọn wà ní ààringbùngbùn ìwọ̀-oòrùn Afrika

Láti ìgbà tí Ibrahim Traore ti di olórí orílẹ̀ èdè Burkina Faso, ni àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè náà  ti nrí ìdàgbàsókè lọ́kan-ò-jọ̀kan. Irú olórí báyìí dára fún Áfrika, ẹni tó n’ifẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ dénúdénú, tó sì fẹ́ ìtẹsíwájú fún ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú. 

Adúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè fún àtìlẹyìn Rẹ̀ fún Màmá wa, Olóyè ìyá ààfin Modúpẹ́ọlà Onítìrí-Abíọ́lá, fún àṣeyọrí iṣẹ́ Orilẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), tí wọ́n sì jẹ́ àwòkọ́ṣe ìpìnlẹ̀ rere fún orílẹ̀-èdè Yorùbá àti fún ilẹ̀ Afrika lápapọ̀. 

Gẹ́gẹ́ bí Màmá wa ṣe máa ń sọ àwọn ọ̀dọ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) kún’jú-ìwọ̀n láti ṣe ètò ìṣèjọba tí ó dára.

Èyí sì ti bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún tí a ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ.

Ní kété tí Olódùmarè bá ti mú wa ṣe àṣeyọrí nípa lílé àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà kúrò lórí ilẹ̀ wa, tí àwọn adelé sì wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba ní àwọn ìpínlẹ̀ wá, iṣẹ́ náà yóò leè tẹ̀síwájú. 

Nítorí náà, gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), ẹ jẹ́ kí a fi ọkàn wa bálẹ̀, Olódùmarè ti ṣẹ́gun fún wa.

Ominira yoruba daily news | the newest nation in the world 2024