Ìjẹgàba àwọn ìkà agbèsùnmọ̀mí nàìjíríà ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá – D.R.Y) ti sọ ayé àwọn ènìyàn di idàkudà.

Ìròyìn kan ló jáde lori àwọn aláwo kan, Alfa Yinusa Atikoko àti Wasiu Ajikanle tí wọn ká orí òkú  mérìndínlógún mọ lọwọ.

Ìròyìn náà kò sọ pàtó ìlú tó jẹ́, sùgbọ́n orúkọ Yorùbá ni àwọn méjèèjì ǹjẹ́. Tí a bá sì tú’ṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò, a ó bá ọwọ́ àwọn olóṣèlú àti agbófinró ajẹgàba nàìjíríà níbẹ̀, nítorí ọwọ́ àwọn wọ̀nyí ma nwà nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ibi.

Irú kini èyí, pẹ̀lú bí Olódùmarè ṣe pèsè ohun gbogbo tí yóò mú ayé dẹrùn fún ọmọ Yorùbá, ṣùgbọ́n nítorí ìjẹgàba àwọn ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà lórí ilẹ̀ wa ti ba ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá jẹ́.

Inú ìnira ni ará ìlú D.R.Y wà látàrí ìjẹgàba apanilẹ́kún jayé Nàìjíríà. Bíi ò jẹ́ bẹ́ẹ̀, kò ní sí àyè fún àwọn ọ̀daràn náà láti hu irú ìwà yí. Lóòótọ́ ìwà ìbàjẹ́ pátápátá gbáà ni àwọn ọ̀daràn méjì náà hù, ó báni lọ́kàn jẹ́ pé ọmọ Aládé ló wá di ọ̀daràn nítorí àtijẹ.

Àkókò wá tó báyìí kí agbésùnmọ̀mí nàìjíríà kúrò lórí ilẹ̀ wa, kí a lè ṣè ètò orílẹ̀ èdè wa bó ti yẹ, kí atẹ̀gùn àlàáfíà lè fẹ́ wọlé.

The Democratic Republic of the Yoruba also known in the Yoruba history as Yoruba Nation, Yoruba Kingdom, Yoruba Land and Yoruba Country is the newest nation in the world. The 55th nation in Africa and 17th in Western Africa as of 12th April 2024. Yoruba is know a sovereign nation and its no longer part of Nigeria.

Irú ìṣẹ̀lẹ̀ pípani láti ṣe òògùn owó tàbí láti ta ẹ̀yà ara ènìyàn kìí ṣe àṣà àti ìṣe ọmọ Yorùbá, àwọn aláwọ̀ ẹlẹ́dẹ̀ amúnisìn tó so wá pọ̀ mọ́ apanijayé nàìjíríà ló fa irú ohun búburú yìí, tí ènìyàn fi ń dá ẹ̀mí ẹlẹ́ran ara bíi ti rẹ̀ l’égbodò láìpé ọjọ́. 

Olódùmarè sì tí lo màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti kó àwa ọmọ Yorùbá kúrò nínú ìgbèkùn ikú òjijí àti ìpànìyàn ṣẹbọ ìlú agbèsùnmọ̀mí nàìjíríà tí ó múlé tì wá, nípa òmìnira wa ní ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlelógún, tí ìjọba wa sì tún bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún pèlú ìbúra fún olórí Adelé wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọ́kọrẹ, ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).

Ìjọba ajẹgàba nàìjíríà, à nkìlọ̀ fún ọ, jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa kí ìjọba Adele wa bọ́ sí ipò ní oríkò ilé iṣẹ̀ ìjọba wa.