Ṣe a kìí gbọ́n tó ẹnití ń ṣọ́ ni, fún ìdí èyí a nílò láti máa kíyèsára nígbà gbogbo, ọkùnrin kan ló tú àṣírí ọ̀nà tuntun tí àwọn amóòkùn ṣèkà tún fi nlu jìbìtì báyìí nínú fọ́nrán kan lórí ayélujára láti sìn àwọn ènìyàn ní gbẹ́rẹ́ ìpàkọ́.
Nínú àlàyé rẹ́, ó ní ṣàdédé ní àpò ìwé yíò dé láti ọ̀dọ̀ àwọn oníjìbìtì yí bíi pé ẹnìkan fí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ranṣẹ́ sí ẹnití wọ́n fẹ́ lù ní jìbìtì, orúkọ àti àdírẹ́sì rẹ̀ yíò wà lára àpò ìwé àti ẹbùn náà.
Bí onítọ̀hún bá ti rí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀, wọn á wá sọ fún kí ó fí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ ya àwòrán kóòdù àdírẹ́sì orí ayélujára (QR code) ará ẹbùn náà ránṣẹ́ sí àwọn, bí ẹni náà bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn nọ́mbà ilé ìfowópamọ́, àwòrán, àwọn àkọsílẹ̀ ìdánimọ̀ àti gbogbo nkan tó fipamọ́ sínú ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ ni yíó hàn lọ́dọ̀ àwọn oníjìbìtì yíi, gbogbo owó inú ilé ìfowópamọ́ ẹni ọ̀hún ní wọ́n á kò pátápátá, wọ́n sì tún lè máa lu àwọn tó ni nọ́mbà tó wà lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ ní jìbìtì.
Ọmọ Aládé ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ k’á ṣọ́ra gidigidi, agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó ń fipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa kò ní ààbò rárá fún ẹ̀mí tàbí ohun ìní ará ìlú, kò tún sí òfin tó lè gbèjà ẹnití ó bá kàgbákò oníjìbìtì, nítorí àwọn olóṣèlú, ọba àti agbófinró wọn pàápàá, olè àti ọ̀dájú oníjìbìtì pọ́nbélé ní wọ́n.
Ṣé a kò gbàgbé pé Ogunwusi, tó sì máa já’jà láì pẹ́ yìí náà nlu jìbìtì lójú méjèèjì? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ọba ní ilẹ̀ Yorùbá.
Olódùmarè ti yọ wá nínú àjàgà Nàìjíríà nípa lílo ìránṣẹ́ Rẹ̀, màmá wa, Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla láti gba òmìnira wa kúrò nínú oko ẹ́rú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun tí ìjọba Adelé wa sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọjọ́ kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún nígbàtí a búra wọlé fún bàbá wa, Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ gẹ́gẹ́bí olórí ìjọba Adelé wa, màmá wa sí ti sọ fún wa pé ẹnikẹ́ni tí ó bá lu ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ní jìbìtì, ìjọba wa yíó ṣe ìrànlọ́wọ́ láti ṣe ìwádìí àti láti fi òfin gbé irú ẹni bẹ́ẹ̀, ọmọ Aládé tó bá lu jìbìtì á fimú dánrin.
Gbogbo ètò yí ni ìjọba Adelé wa ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, D.R.Y tí ṣetán láti dáwọ́lé pẹ̀lú àwọn ohun amáyédẹrùn tó wà nínú àlàkalẹ ètò ìṣèjobà tí Olódùmarè gbé lé màmá wa lọ́wọ́ fún àwa ọmọ Yorùbá ní kété tí àwọn ìjọba Adelé wá bá ti gbà àkóso oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba wa kúrò lọ́wọ́ àwọn jẹgúdú jẹrá ajẹgàba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ní àìpẹ́ mọ́ rárá yìí.