ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI
OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.
ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ
Yorùbá ló sọ pé, Àìtètè m’olè, olè mú olóko.
Ìbá ṣe pé a ti bọ́ sí’ta yanturu, ní ọjọ́ kẹ́tàlá, tàbí èyíkéyi ní ọjọ́ mẹ́ta tó tún tẹ̀le, ní oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún tí a wà nínú rẹ̀ yí, ní ìlú Ìbàdàn, láti kí Ìjọba-Adelé wa káàbọ̀ ní oríkò-ilé-iṣẹ́ ìjọba D.R.Y, à bá má ti tún rí àwọn ìwọ̀sí tí a nrí wọ̀nyí.
Ní ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, ni Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jáde kúrò l’ara Nàìjíríà! Ayé gbọ́, ọ̀run mọ̀. Nàìjíríà mọ̀.
Ní ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún tí a wà nínú rẹ̀ yí, ni a sì gbé Ìjọba-Adelé wa wọ’lé, gẹ́gẹ́bí Orílẹ̀-Èdè aṣèjọba-ara-ẹni, tuntun jùlọ, ní àgbáyé – Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y).
Ìwa-ọmọlúàbí tí wọn ò ní ní Nàìjíríà, kò jẹ́ kí wọ́n rora kúrò lórí ilẹ̀ wa, ṣùgbọ́n o, wọ́n fẹ́ wọ́n kọ̀, wọ́n máa kúrò láìpẹ́.
Wọn ò tún wá mọ ìwọ̀n ara wọn; wọ́n nṣẹ̀ sí òfin àgbáyé; ṣùgbọ́n áá tó yé wọn – wọ́n nṣe bíi pé àwọn ló ni ilẹ̀ Yorùbá – wọ́n njẹgàba, wọ́n nmú àwọn t’ó nwa kùsà ní ọ̀nà àìtọ́, a ò fún wọn ní’ṣẹ́ agbaṣẹṣe, láti bá wa mú ẹnikẹ́ni lórí ilẹ̀ wa.
Ìwọ tí o pera rẹ ní ọba, Taofeeq Ọ̀ṣúnmákindé, láti ìlú Ifẹ̀tuntun, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ìwọ lo pera rẹ lọ́ba o, àwa ò ní ọba ní D.R.Y, a gbọ́ pé o lọ njí kùsà wà ní Lege, agbègbè Òdìgbó, ní Ìpínlẹ̀ Ondo, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y); àbọ̀ábá ni tìẹ, àti àwọn tó kù – Sheu Mustapha, Sabiru Hashim, Danbaba Ibrahim àti Ade Olap Global Resources Limited, àti ẹni t’ó kù yín.
Ẹ̀ ẹ́ f’ojú dán’rin òfin Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y). Ìwọ ilé-iṣẹ́ tó-o pera ẹ ní Olap Global Resources Limited, wàáwá ṣe àlàyé ibi tí o ti gba àṣẹ orúkọ tó njẹ́ yẹn, àti lábẹ́ òfin wo lo ṣe nwa kùsà orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni D.R.Y. Ṣùgbọ́n, wọ́n ní, kí a kọ́kọ́ lé ẹlẹ́yọ́rọ́ lọ ná ká tó wá fàbọ̀ fún adìyẹ.
Nàìjíríà, wá gbọ́ o! Èkíní, agbègbè Òdìgbó, àti gbogbo ilẹ̀ Yorùbá, kò sí l’ara Nàìjíríà mọ́, láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, nítorí náa ẹ ò ní àṣẹ kankan níbẹ̀, àgàgà, Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, èyí tí agbègbè náà wà, ti di orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni láti ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún; nítorí náà, ìkọjá-àyè ni fún yín, pé ẹ ṣì wà l’orí ilẹ̀ Yorùbá, tí ẹ tún wá nsọ pé ẹ nmú àwọn tó nwa kùsà ní ọ̀nà àìtọ́! Ilẹ̀ Yorùbá kì nṣe ara Nàìjíríà aríre má ṣe; a ò dẹ̀ bẹ̀ yín kí ẹ bá wa mú ẹnikẹ́ni. Ẹ kúrò lórí ilẹ̀ Yorùbá, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y)