PROVERB: Tinú ọ̀lẹ lọ̀lẹ ńjẹ; aṣiwèrè èèyàn ni ò mọ èrú tí yó gbà
Àì fẹ́ẹ́ kúrò lórí ìjẹgàba, èyí tí nàìjíríà njẹgàba ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, òun ni okùn’fà oríṣiríṣi ìgbésẹ̀ tí Nàìjíríà àti àwọn gómìnà ajẹgàba wọn ní ilẹ̀ Yorùbá ngbé, látàrí kí ọmọ Yorùbá le rò wípé inkan ti bẹ̀rẹ̀ síí dára si.
❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP). (ÌKÉDE… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò mọ̀ pé ipele tí a wà ní ilẹ̀ Yorùbá kìí ṣe ipele kí a máa rò pé nàìjíríà ṣì ni ìlú wa. Nítorí èyí, ó ṣe pàràkì fún àwa tí a ti mọ̀, kí á jẹ́ kí àwọn ará-ilé wa kí ó mọ̀; kí ẹbí wa kí ó mọ̀; kí ọ̀rẹ́ wa kí ó mọ̀; kí ojúlùmọ̀ kí ó mọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ló ti gbọ́ nípa orílẹ̀-èdè Yorùbá nígbà kan tàbí òmíràn, ṣùgbọ́n tí wọn ò tún gbọ́ nkankan mọ́, nítorí rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n lábẹ́ Nàìjíríà kò sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe nlọ gan-an gan.
Nítorí èyí, wọn ò tilẹ̀ mọ̀ pé ìjọba Yorùbá ti wà lórí àléfà láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí – nípa èyí, wọ́n ṣì rò pé abẹ́ nàìjíríà àti àwọn ajẹgàba gómìnà wọn ní ilẹ̀ Yorùbá ni àwọn ṣì wà!
Ìdí ni èyí, tí ó fi jẹ́ pé nígbàtí àwọn agbésùnmọ̀mí ajẹgàba gómìnà wọ̀nyí bá ti pè wọ́n kí wọ́n wá gba ohunkóhun, inú wọn á dùn, wọ́n á ní ìlú ti ndára síi.
Àìmọ̀kan yí ni ìṣòro tí ó pọ̀ jù nísiìyí, tí a ní láti borí rẹ̀ láarín àwọn ènìyàn wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn ò dí iṣẹ́ tí Màmá wa, MOA, nṣe lọ́wọ́; bẹ́ẹ̀ ni kò dí gbogbo ìgbésẹ̀ tí wọ́n ngbé, èyí tí ó máa já sí pé àwọn ajẹgàba wọ̀nyí máa sá, láìpẹ́, kúrò lórí ilẹ̀ wa, kò díi lọ́wọ́ rárá.
Ṣùgbọ́n ohun tí ó wà níbẹ̀ ni pé, àìmọ̀kan yí ni ó máa jẹ́ kí àwọn ènìyàn wa ó máa sá tẹ̀lé àwọn gómìnà ajẹgàba wọ̀nyí!
Fún àpẹrẹ, wèrè tó wà ní ìlú Ìbàdàn – Ṣèyí Mákindé – ti gbé ètò kan síta, ó ní kí àwọn ọ̀dọ́ wá máa gba àádọ́ta ẹgbẹ̀run náírà, ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́bí owó ìrànlọ́wọ́ látàrí ohun tí ó pè ni “líle tí ìlú le koko.”
Ẹ jọ̀wọ́, gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ máṣe yà síbẹ̀ o!
Ẹ rántí pé, àdéhùn-k’adéhùn kankan tí ẹ bá ti ní pẹ̀lú nàìjíríà, l’ẹhìn tí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti di orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-rẹ̀ ní ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún, tí a wà nínú rẹ̀ yí, gbogbo àdéhùn tàbí ìbáṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú nàijíríà, ti di Ọ̀RÀN dídá gbáà labẹ́ òfin Orílẹ̀-Èdè Yorùbá.
Ẹ máṣe gbàgbé pé kò sí “mi ò mọ̀ niì” lábẹ́ òfin o!