Ọ̀kan lára àwọn àǹfààní tí a ní, ní Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ni pé ibi tó bá wu oníkálukú ló le gbé ní ilẹ̀ Yorùbá.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla (Olóyè Ìyá-Ààfin) bá àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá sọ láìpẹ́ yí wípé, ọ̀kan ni I.Y.P ti D.R.Y.
Ẹnìkan lè jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ìbàdàn, ó ní àǹfààní láti gbé ibikíbi tí ó bá ní ìfẹ́ sí ní Orílẹ̀ èdè D.R.Y. Kò sí ohun tó burú níbẹ̀, nítorí pé ọ̀kan náà ni gbogbo wa. Kò sí ohun tó ń jẹ́ ọmọ Èkó tàbí ọmọ Ìjẹ̀bú, níwọ̀n ìgbà tí a bá ti jẹ́ ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P), ọ̀kan ni wá.
Níwọ̀n ìgbà tí a ti jẹ́ Orílẹ̀ èdè, tí a ní èdè kan, àṣà kan, ìtàn kan àti ilẹ̀ àjogúnbá kan, gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí ti so wá papọ̀ a sì ti di ìkan ṣoṣo.
Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó rán màmá wa MOA ìyá ìrọ̀rùn lóbádé láti gbà wá kúrò nínú oko ẹrú, tí wọ́n sì jẹ́ kí á mọ̀ wípé àwa ọmọ Yorùbá la ni ilẹ̀ Yorùbá.
Àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí yóò mú ìgbé ayé rọrùn fún wa ní Olódùmarè gbé fún Màmá wa MOA. A kú oríire, gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, I.Y.P ti D.R.Y.
Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, D.R.Y.
Àtẹ́lẹwọ́ ẹni kì í tan ni’jẹ