Oríṣiríṣi nkan ni a jogún bá ní ọwọ́ àwọn bàbá nlá wa, tí Olódùmarè fi kẹ́ ìran Yorùbà láti lè máa gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn àti èyí tí ó ní ògo. 

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan tí ọwọ́ nṣe, gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, ògiri tí ó jẹ́ ọgọ́run ibùsọ̀ máìlì (èyí tí ó ju ọgọ́run ibùsọ̀ kìlómítà lọ), tí ó sì jẹ́ nkan àmúyangàn ní àgbáyé.

Gẹ́gẹ́bí Màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin), ṣe sọ wípé a máa padà sí orírun wa láti ṣe àmúlò ohun àjogúnbá wa. 

Àwọn ilé tí àwọn baba wa nkọ́ ní ayé àtijọ́, jẹ́ ilé tí ó ní ọnà púpọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ère àjogún-bá wa, gẹ́gẹ́bí Orí-Olókún jẹ́ iṣẹ́ ọnà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ṣì nwòye, títí di òní yí, pé irú ọgbọ́n wo ni àwọn baba wá lò, tí wọ́n le dá oríṣiríṣi nkan wọ̀nyí ṣe!

Títí dí òní, àwọn iṣẹ́ kan wà tí ó jẹ́ pé ọ̀nà àrà tí Ẹlẹ́da ngbà láti tipasẹ̀ ọmọ Yorùbá ṣe nkan wọ̀nyí, jẹ́ ìyàlẹ́nu lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣé ti iyùn ni kí á sọ ni, tàbí oríṣiríṣi ọnà-àrà tí ọmọ Yorùbá ndá sí aṣọ-òkè.

Tàbí ọnà ti irun-dídì ni ká sọ; bó ti lẹ̀ jẹ́ bí a ṣe ngbálẹ̀ pàápàá. Obìnrin Yorùbá á gbá àyíká àti agbègbè rẹ̀, lórí ilẹ̀ eruku, á sì ya ọnà si!

Ṣé bí a ṣe nwọ àwọn aṣọ wa ni, àtọkùnrin àtobìrin wa ni a ní oríṣiríṣi ọnà tí a nṣe pẹ̀lú aṣọ tí a bá wọ̀.

Ànfààní iṣẹ́ ọnà-ṣíṣe wà lára ànfààní tí a máa máa rí ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).

Nísiìyí tí a ti padà sí Orísun wa, Èdè wa àti àṣà wa, oríṣiríṣi ìmísí láti inú wá ni Ọmọ Yorùbá yíò máa ní, èyí tí iṣẹ́-ọnà àti ìṣe-ọnà yíò fi gbòòrò si ní àwùjọ orílẹ̀-èdè Yorùbá.

Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá D.R.Y.

Àìmọṣẹ́ kọ̀ ọmọ ajá, lọdẹ fi ńrán an níṣẹ́ ikú