Lára ìkìlọ̀ tí Olódùmarè kọ́kọ́ gbé fún Màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) ni láti kíyèsára fún àwọn ọ̀tá inú ilé, pàápàá àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yorùbá láti má jẹ kí ẹnikẹ́ni lò wọ́n láti jẹ́ alátakò àti ọ̀dàlẹ̀ sí ìran Yorùbá. Nitorí, nínú ìdúróṣinṣin wọn ni àìmọye àǹfààní wà.
Lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni, àwọn ọ̀tá ìta tó jẹ́ amúnisìn àti àwọn aṣojú wọn ma nwa àwọn ọ̀tá inú ilé láti lò wọ́n lòdì sí ìran àwa ọmọ aládé fún ìṣubú.
Àìmọye ni èròngbà àwọn ọ̀dájú, ìkà àti aninilára aṣojú àwọn amúnisín tí wọn kò fẹ́ kí ìran Yorùbá bọ́ lóko-ẹrú.
Onírúrú ni ọ̀nà tí àwọn ọ̀tá inúlé àti tìta pẹ̀lu àwọn ọ̀dàlẹ̀ ngbà láti da ìrìn àjò òmìnira ilẹ̀ Yorùbá rú, ṣùgbọ́n Òlódùmarè kò gbà fún wọn, Ó wá lo Màmá wa MOA láti ṣe ìkéde òmìnira wa ní Ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún, tí a sì búra wọlé fún olórí ìṣàkóso wa, bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọ́lá Ọmọ́kọrẹ́, ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún, tí a sì ti di orílẹ̀ èdè aṣàkóso-ara-ẹni.
Nitorínáà, gbogbo ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, Indigenous Yorùbá People, (I.Y.P) ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá D.R.Y, ẹ jẹ́ kí ání ìfojúnsùn kannán, kí á má darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀dàlẹ̀ ìran Yorùbá, kí gbogbo àwa ọmọ aládé lè rí ìgbédìde àti ìṣelógo orìlẹ̀-èdè Yorùbá D.R.Y.
Ọpẹ́ lóyẹ kí ọmọ Yorùbá máa da lọ́wọ Olódùmarè tí Ó lo Màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla (Olóyè Ìyá-Ààfin) láti jà fún ìran wọn, orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y).
Gbà fún Ọlọ́run, gbà fún divine blueprints ọwọ́ MOA.