Ní ìgbà ìwáṣẹ̀, kí àwọn amúnisìn tó wá so irun iwájú pọ̀ mọ́ ti ìpàkọ́, ọwọ́ àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá ni agbára, àṣẹ àti ìdarí ohun gbogbo wà.

Ohun tí wọ́n bá sọ fún àwọn ará ìlú nígbà náà ni wọ́n ń ṣe, èyí ló mú kí wọ́n wá rí ara wọn bí i igbákejì Olódùmarè.

Oríṣiríṣi gbólóhùn Yorùbá ló sì ṣe àfihàn bí àwọn ọba ọ̀dàlẹ̀ yí ṣe ka ara wọn sí pàtàkì ni ilẹ̀ Yorùbá ju àwọn ará ìlú lọ. Wọn a máa wípé, t’ọba làsẹ, ar’ọ́bafín lọba ń pa, ẹnìkan kì í k’ọ́ba ní ìnàró, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ní ìgbà náà lọ́hùn tí kò tíì sí ilé ẹjọ́ ti ìwòyí, tí aáwọ̀ bá ṣẹlẹ̀ yálà láàárín ọkọ àti aya, nípa ààlà ilẹ̀ tàbí nípa ogún pínpín, ọ̀dọ̀ ọba ni wọn yóò kò ẹjọ́ lọ láti báwọn yanjú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú wípé ní ìgbà mìíràn tí ọkọ àti aya bá ní aáwọ̀, àwọn ọba olójú kòkòrò yí nínú ìdájọ́ ibi wọn, wọ́n a wípé àwọn ti gbé ẹsẹ̀ lé ìyàwó rẹ̀,

ṣé kó kúkú sí agbára tí ọkọ ìyàwó lè sà àbí ilé ẹjọ́ tó lè gbé wọn lọ, ọkọ ìyàwó yóò wá fi ìbànújẹ́ padà sí ilé rẹ̀. Ṣé ìwà ìkà àti àìláàánú ọmọlàkejì kọ́ ni eléyìí jẹ́? 

Ẹní tó fi ìṣẹ́ àti ìyà ṣe iṣẹ́ oko, ọba a ní kó mú ìṣákọ́lẹ̀ wá, àbí ẹ̀ mawo ìwà ìrẹ̀jẹ, ìfọwọ́ ọlá gbá ni lójú àti ìṣi agbára lò. Ayé ìjẹkújẹ àti fàmílétèntutọ́ tí gbogbo wọ́n ń jẹ nìyí. 

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla sọ láìpẹ́ yí wípé, àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá kò ṣe oore fún ẹnikẹ́ni rí, àfi kí wọ́n ṣáá ti máa gba àbọ̀dè fún ọmọ Yorùbá, alábọ̀dè ni gbogbo wọn. 

Gbogbo ilẹ̀ ìlú ni wọ́n ti tà fún àjòjì tán, nítorí wọ́n gbàgbọ̀ wípé, ọba ló ni’lẹ̀. Kò sí àyè ìjẹkújẹ bí eléyìí mọ́, Olódùmarè ti jà fún wa, ìran Yorùbá ti kúrò nínú oko ẹrú, a ti di òmìnira!

Ominira yoruba daily news | the newest nation in the world 2024